Kí ni Autopsy? Báwo la ti ń ṣe é, ọjọ́ mélòó ni èsì rẹ̀ máa ń jáde?

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina
Bí àwọn ènìyàn ṣe ń retí èsì àyẹ̀wò òkú gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé Ilerioluwa Aloba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad, onírúurú ìbéèrè ló gba ẹnu àwọn ènìyàn.
Èyí rí bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí agbenusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko, Benjamin Hundeyin kéde pé àwọn ti parí àyẹ̀wò tí wọ́n fẹ́ ṣe lára òkú Mohbad.
Ìwádìí òkú Mohbad ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Nàìjíríà dìde pé ó yẹ kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò òkú náà láti fìdí ohun tó ṣekúpa olórin náà múlẹ̀.
Lára àwọn ìbéèrè tó gba ẹnu àwọn ènìyàn láti ìgbà náà ni pé kí ló ń jẹ́ "autopsy" tí wọ́n máa ń ṣe fún òkú.
Kí ló ń jẹ Autopsy? Ó máa ń tó ìgbà wo kí èsì rẹ̀ tó jáde?

Oríṣun àwòrán, MOHBAD/INSTAGRAM
Àwọn onímọ̀ nípa ṣíṣe àyẹ̀wò fún òkú tó ń jẹ́ Autopsy sọ fún BBC pé ó túmọ̀ sí pé lílo ìmọ̀ ìgbàlódé láti fi mọ̀ ohun tó bá ṣekúpa òkú tí wọ́n bá ṣe é fún.
Bákan náà ló jẹ́ ọ̀nà láti mọ̀ bóyá òkú náà ní àìsàn kan tàbí òmíràn kí ẹ̀mí tó bọ́ lára rẹ̀.
Wọ́n ní oríṣiríṣi autopsy ló wà tó sì jẹ́ pé iṣẹ́ abẹ ni wọ́n máa fi ń ṣe gbogbo rẹ̀.
Àyẹ̀wò òkú wà tó jẹ́ pé àwọn nǹkan tó wà nínú ènìyàn ni wọ́n le ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ tí òmíràn sì wà tó wà fún ẹ̀yà ara tó wà níta.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ṣe sọ ṣíṣe àyẹ̀wò autopsy kìí pẹ́ rárá - kìí ju láàárín wákàtí méjì sí mẹ́rin lọ àmọ́ ó máa ń tó ọ̀sẹ̀ mẹ́rin kí èsì rẹ̀ tó jáde.
Bákan náà ni irú àyẹ̀wò tí wọ́n bá ń ṣe lára òkú máa ń sọ iye ìgbà tó ṣeéṣe kí èsì rẹ̀ tó jáde.
Àwọn mìíràn máa ń tó oṣù kan tí òmíràn sì máa ń jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Lára àwọn nǹkan tó máa ń fa ìyàtọ̀ láàárín ìgbà tí èsì àyẹ̀wò autopsy máa ń jáde ní:
Èsì àyẹ̀wò òkú ènìyàn tó bá sanra máa pẹ́ jáde sí ti ènìyàn tí kò sanra.
Ìgbà tí ènìyàn bá kú sí àsìkò tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò òkú rẹ̀ náà máa ń ṣokùnfà bí èsì rẹ̀ yóò ṣe tètè jáde sí.
Kí ni àwọn nǹkan tó yẹ láti ṣe ṣáájú autopsy?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ó ní àwọn ìgbésẹ̀ tí ènìyàn gbọ́dọ̀ gbé tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àyẹ̀wò òkú.
Ẹ gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí.
Ẹ gbọ́dọ̀ ní ilé ìwòsàn tàbí ẹ̀ka kan tó ń tì yín lẹ́yìn láti ṣe àyẹ̀wò náà.
Tí ẹ bá wà ní ìpínlẹ̀ Eko, ilé ìwòsàn LUTH àti LASUTH nìkan ló máa ń gbà láti ṣe àyẹ̀wò yìí.
Bákan náà ni àwọn ilé tí wọ́n máa ń gbé òkú pamọ́ sí kan náà ní àṣẹ láti ṣe àyẹ̀wò yìí.
Gẹ́gẹ́ bí òfin ìpínlẹ̀ Eko, àwọn onímọ̀ "Pathology" tí wọ́n máa ń pè ní "Pathologist" nìkan ló ní àṣẹ láti ṣe àyẹ̀wò yìí fún òkú.














