Ọkọ, ìyàwó ọ̀sìngín àti èèyàn 113 míì jóná di eérú, 150 farapa níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó

Ibudo to jona

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O le lọgọrun un eeyan to ti jade laye, nigba ti ọgọrun un ati aadọta eeyan mii farapa lẹyin ina to ṣẹyọ nibi ayẹyẹ igbeyawo kan ni ariwa orilẹ-ede Iraq.

Alẹ ọjọ Iṣẹgun ni ina ọhun bẹrẹ ni gbagede igbeyawo naa to wa ni ariwa Nineveh.

Ko si ẹni to tii le sọ ohun to ṣokunfa ina naa amọ iroyin ni ina ọhun bẹrẹ lẹyin ti awọn eeyan ṣana si awọn ‘fireworks’ kan lati ṣajọyọ.

Iraq fire

Oríṣun àwòrán, getty images

Ọ̀pọ̀ àwòràn ló jáde lórí bí wọn ṣe ń kó òkú àwọn èèyàn jáde nínú gbọngàn ayẹyẹ

Bi ina naa ṣe bẹrẹ lo mu orule gbọgan ayẹyẹ igbeyawo ọhun ti ọrọ si di boolọ o yago fun mi.

Ileeṣẹ eto abo Iraq sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin pe ohun elo ikọle ti wọn fi kọ gbọgan naa kii ṣe ojulowo lo jẹ ko tete dawo laarin iṣeju perete ti ina ọhun bẹrẹ si n jo.

Agbẹnusọ ileeṣẹ eto ilera kan sọ pe tọkọ-taya to n ṣe igbewo naa ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

Oniruru aworan lori ayelujara ṣafihan bi ina naa ṣe lagbara to, ati bi wọn ṣe n ko oku awọn eeyan jade ninu gbọgan naa.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ọgọrọ eeyan lo peju sibi ayẹyẹ igbeyawo ọhun ki ina to sọ ni nnkan bii aago mọkanla alẹ ku iṣẹju marundinogun.

Ọkan lara awọn oṣojumikoro naa, Imad Yohan ni “A ri ina to n jade lati inu gbọgan naa wa, awọn kan ṣe aṣeyọri lati jade, nigba ti ọpọ awọn mii ha sinu gbọgan naa.”

Ẹlomiran to jẹ okan lara awọn ero inu gbọgan ọhun, Rania Waad, ṣalaye pe “A ko ri nnkankan, eefin bo gbogbo inu gbọgan naa, o ṣoro fun wa lati mi, bẹe ni a ko le jade.”

Ina jo Rania to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun lọwọ rẹ.

Igbakeji gomina Nineveh, Hassan al-Allaq, ti sọ fun ileeṣe iroyin Reuters pe apapọ eeyan mẹtalelaadọfa (113) lo ba iṣẹlẹ ọhun lọ.