Wo ibùdó ìgbafẹ́ pàtàkí nílẹ̀ Yorùbá to le pa owo gọbọi wọle fáwọn ìpínlẹ̀ tí wọn wà

Awọn ibudo igbafẹ

Oríṣun àwòrán, Collage

    • Author, Adedayo Okedare
    • Role, Broadcast Journalist
    • Author, Adedayo Owolabi
    • Role, SBJ

Oni ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Kẹsan ọdun 2023 ni ayajọ irinajo afẹ jakejado agbaye eyi to maa n waye ni ọdọọdun.

Lọdun 1980 ni ajọ isọkan orilẹede agbaye kede ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Kẹsan ọdọọdun gẹgẹ bii ayajọ ọjọ irinajo afẹ lagbaye.

Akori ayajọ irinajo afẹ fun tọdun yii ni “Eto igbafẹ ati idokowo ninu itọju ayika ko le rẹ wa si, ti wọn si n tẹnumọ idi to fi yẹ ki a gbajumọ idokowo to pegede fawọn eeyan, awujọ agbaye ati ọjọ ọla to dara.

Lọna ati sami ayajọ ọjọ irinajo afẹ l'agbaye yii, lo mu ki BBC Yoruba ṣe akojọpọ ọkanojọkan ibudo afẹ ti o lagbara lati pa owo gọbọi wọle fun ijọba.

Paapaa awọn ibudo igbafẹ ti yoo tun mu idagbasoke ba awọn agbegbe ibi ti Eledua fi idi wọn sọlẹ si nilẹ kaarọ-oojiire.

Ni awọn ipinlẹ mẹfẹẹfa to wa nilẹ Yoruba, a wo awọn ibudo igbafẹ to se pataki ni ipinlẹ kọọkan ati bi wọn se pegede si lati pa owo gọbọi wọle fun ipinlẹ koowa wọn.

Ipinlẹ Ekiti:

Gbọngan igbalejo adayeba ọlọpọ̀ ijoko

Gbọngan igbalejo adayeba ọlọpọ̀ ijoko (Amphitheater):

Apata Abanijorin to n bẹ niluu Iyin Ekiti jẹ ọkan pataki lara awọn nnkan adayeba to jẹ nnkan iyalẹnu nilẹ Yoruba.

Inu apata naa da bii gbọngan nla igbalejo ti o le gba to eeyan bii ẹẹdẹgbẹta lẹẹkan ṣoṣo.

Awọn afọku apata wẹwẹ to ṣee fi joko tun wa ninu gbọngan adayeba naa.

Gbọngan naa duro gẹgẹ bii ile ti a mọ, ti o si ni ẹnu ọna abawọle, ibi ti afẹfẹ ti n fẹ wọle, ati ori oke ibi ti eeyan le duro si.

Se ni eeyan yoo si maa wo gbogbo ilu Ado-Ekiti kedere lati inu gbọngan yii.

Ojubọ Ogun Onire

Ibudo ti Ogun Onire wọlẹ si ni Ire Ekiti:

Lara awọn ibudo afẹ mii to n bẹ n'ipinlẹ Ekiti ni oju ibi ti Ogun Lakaaye Ọṣinmọnlẹ wọle si nilu Ire-Ekiti.

Itan fi idi rẹ mulẹ wi pe wahala bẹ silẹ laarin Ogun ati awọn ọmọlẹyin rẹ ti o hu iwa arifin sii.

Ogun pa gbogbo wọn, o si binu wọlẹ si ilu naa.

Awọn eeyan ilu mọ odi yi oju ibi ti Ogun wọlẹ si ka, o si ti di nnkan apewo titi di asiko yii eyi to le pa owo gidi wọle fun ipinlẹ Ekiti.

Ibudo ti baalu akọkọ ti ja ni Naijiria

Ibudo ti baalu akọkọ ti ja ni Naijiria:

Lọjọ kejila ọṣu kẹrin ọdun 1942 ni baalu akọkọ ja lorilẹede Naijiria, ni ori oke Igbo Ilapa to n bẹ niluu Ikọgosi n'ipinlẹ Ekiti.

Ijalulẹ baalu naa waye lasiko ogun agbaye keji.

Ọkọ ofurufu to n ko nnkan ijagun lọ, lo dede ja lulẹ.

Fun ọpọlọpọ wakati lẹyin ijalulẹ baalu naa si ni awọn ado oloro ti ọkọ naa ko fi n dun kikan kikan.

Titi di asiko yii, awọn afọku ara ọkọ ofurufu naa ṣi wa nilu Ikọgosi eyi ti awọn eeyan maa n lọ pe wo.

Ipinlẹ Eko:

Ile pẹ̀tẹ́sìí alájà, akọkọ ni Naijiria:

Ẹniọwọ Henry Townsend to jẹ aṣoju ijọ 'Church Missionary Society (CMS)' lo kọ ile pẹtẹsi alaja, akọkọ lorilẹede Naijiria lọdun 1845.

Agbegbe Badagry nipinlẹ Eko si ni o kọ ile naa si.

Wọn fi ipilẹ ile naa lelẹ ni ọdun 1842, wọn si kọ ọ pari lọdun 1845.

Fidio ti BBC Yoruba se nipa pẹtẹsi akọkọ naa ree nisalẹ yii.

Àkọlé fídíò, Badagry ni pẹtẹsi akọkọ ni Naijiria wa

Ikorita Aremabọ fawọn ẹru ni Badagry:

Lasiko ti owo ẹru ṣi gbilẹ gan an kaakiri agbaye, ikorita Aremabọ yii ni awọn ẹru ti wọn n ra lati Naijiria, ti n wọ inu ọkọ oju omi ti yoo gbe wọn lọ oko ẹru loke okun.

Lati nnkan bii ọọdunrun ọdun sẹyin, awọn ọmọ ilẹ Afrika to le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta, ni wọn ta si oko ẹru lati ibudo ikorita aremabọ yii, bẹrẹ lati ọdun 1886 titi di ọdun ti wọn fi ofin de owo ẹru ni ṣiṣe.

Ẹru to ba di de ikorita Aremabọ yii, ipade dọhun fun niyẹ, oke okun ni yoo ti lọ ba ara rẹ nitori ibudo naa lẹba okun.

Ọpọ awọn ẹru yii ti wọn ko lati orilẹede Naijiria si ni ko pada silẹ baba wọn mọ, titi ti wọn fi dagbere faye.

Fidio ree nipa ibudo ajo aremabọ naa ti BBC Yoruba se.

Àkọlé fídíò, Badagry: Ojú ọ̀nà àrèmabọ̀ fáwọn ẹrú tó ń lọ sókè òkun

Ipinlẹ Oyo:

Iyara Sango lori oke Iyamapo ni Igbeti:

Lasiko ti awọn Ọyọmesi (tii se awọn afọbajẹ ilu Ọyọ) kọ jalẹ lati fi Sango jẹ Alaafin Ọyọ lẹyin ipapoda Ọranmiyan ti o jẹ baba rẹ, inu bii o si kuro nilu Ọyọ.

Ninu irinajo to n rin lọ si ilu Ile-Ifẹ, o pade arabinrin giga kan lẹba apata nla, ti obinrin naa si sọ fun un wi pe oun ni Ayaba to ni oke ti wọn n pe ni 'Iya Mapo'.

Iya Mapo wa gba Ṣango nimọran lati fi ori pamọ si ọdọ oun niluu Igbẹti n'ipinlẹ Ọyọ.

O si fun un ni iyara nla kan lori apata Iya Mapo naa, nibi ti Iya Mapo ati awọn ẹbọra mii ti ro Ṣango ni agbara.

Iyara naa ninu oke Iyamapo si wa nilu Igbeti n titi di oni eyi to wa lara awọn ibudo igbafẹ pataki tipinlẹ Oyo n tọkasi.

Oke Iyamapo

Adagun odo ori apata nilu Ado-Awaye:

Meji pere ni adagun omi to le tente s'ori apata nla, to wa ni gbogbo agbaye.

Ọkan n bẹ ni ipinlẹ Colorado lorilẹede Amẹrika, ikeji n bẹ ni ilu Ado Awaye n'ipinlẹ Ọyọ.

Itan sọ pe obinrin agan kan to wa lati ilu Ọta n'ipinlẹ Ogun, lo wa si Ọyọ atijọ.

Ọpọlọpọ eeyan lo fẹran rẹ, ṣugbọn awọn kan gan an nitori aibi'mọ rẹ.

Ibanujẹ ọkan lo mu ki o gba ẹmi ara rẹ nipa bibẹ sinu odo naa.

Ohun ti awọn ọmọ ilu sọ nipa adagun odo naa ni pe o jin pupọ si isalẹ, ti ko si ni ipẹkun, bẹẹ si ni ko si ẹni to wọ inu rẹ ti yoo jadepada saye ni aaye.

Itan mii tun ni ààyè kan n bẹ labẹ odo naa eleyii ti Yemọja to n fun ni l'ọmọ n ṣe akoso le lori.

Ori Oke naa, ti wọn n pe ni 'Iya-n-ke' tumọ si iya n ke, o si iwa nilu Ado Awaye di oni eyi to jẹ ibudo igbafẹ pataki fun ijọba ipinlẹ Oyo lati pawo wọle

Fidio ree nisalẹ yii ti BBC se nipa adagun omi Ado Awaye naa.

Àkọlé fídíò, Colorado ni Amẹrika àti odò Awaye ní Naijiria nikeji àdágún órí àpáta ní gbogbo àgbáyé!

Odo Sogidi ti ẹnikẹni ko gbọdọ pa ẹja inu rẹ:

Odo Sogidi to n bẹ nilu Awẹ n'ipinlẹ Ọyọ jẹ odo kan ti ẹni ti ko ba fẹ wahala ko gbudọ pa ẹja inu rẹ jẹ.

Itan ni odo naa ni agbara lati wo alaisan san, eyii lo si mu ki o di eewọ lati pa ẹja inu rẹ jẹ.

Lati ọdun 1750 ti wọn ti fi ilu naa lọlẹ, ni odo Sogidi naa ti wa ni bẹ.

Ohun ti itan fi idi rẹ mulẹ ni pe, ọba kan ni ilu naa, Ilemolu ati awọn eeyan rẹ ni oungbẹ n gbẹ, ti wọn si wa omi lọ.

Ninu ilepa wọn lati se awari omi, ni awọn ti o jẹ ọdẹ laarin wọn ti ri awọn ọbọ kan lori igi, ti wọn si n lepa wọn.

Ọbọ wọnyii ni wọn le de ibi ti odo yii wa titi di asiko yii.

Awari agbara ti odo naa ni lo mu ki o di eewọ lati pa ẹja inu rẹ jẹ.

Pupọ awọn eeyan to dẹjaa si eewọ naa, ti wọn si ṣe aigbọran, lo kabamọ.

Odo Sogidi si wa nilu Awe, eyi ti awọn eeyan n rinrin ajo afẹ lọ.

Fidio nipa odo Sogidi ree nisalẹ yii ti BBC Yoruba se nilu Awe.

Àkọlé fídíò, Sogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele

Ipinlẹ Ondo:

Ihò Eléérú (Cave of Ashes):

Iho abẹ apata nla kan n bẹ niluu Iṣarun n'ipinlẹ Ondo to kun fun kiki eeru.

Awọn akọṣẹmọṣẹ to n ṣe iwadii nipa nnkan iṣẹmbaye fi idi rẹ mulẹ wi pe awọn eeyan kan ti gbe ibẹ ri ni nnkan bii ẹgbẹrun mẹtala ọdun sẹyin.

Iho Eleeru naa to n bẹ ni ijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, ni ọmọ ilu kan Isarun kan, ti wọn pe orukọ rẹ ni Obele, ṣe awari rẹ lọdun 1922 nibi ti o ṣiṣẹ ọdẹ lọ.

Obele si lọ ke si awọn eeyan ilu lati wa wo ọpọlọpọ eeru ti oun ri ninu iho nla naa.

Ibudo ọhun si ti di ibudo igbafẹ nipinlẹ Ondo eyi to yẹ ko maa mu owo gidi wa.

Ori Oke Idanre:

Ori oke idanre jẹ ọkan pataki lara awọn ibudo afẹ to n bẹ n'ipinlẹ Ondo.

Ọkanojọkan oke to yi ilu naa ka, jẹ nnkan to ṣe anfani fun wọn pupọ lasiko ogun laye atijọ.

Itan fi idi rẹ mulẹ wi pe awọn eeyan 'Ufe Oke' ti o tẹ ilu naa do, lo to ẹgbẹrin ọdun lori oke ki o to di pe wọn tẹdo si ipẹtẹlẹ lọdun 1923.

Oke naa ga pupọ, amọ aaye to tẹju wa loke lati naju ti eeyan ba le gun oke naa tan.

Oke Idanre yii si ni ọpọ awọn arinrin ajo afẹ maa n lọ eyi to n mu owo wọle fun ijọba ipinlẹ Ondo.

Fidio isalẹ yii ti BBC Yoruba se lo se afihan bi Oke Idanre se ri.

Àkọlé fídíò, Òkè Ìdànrè: Òkè tó kéré jùlọ jẹ́ ẹsẹ̀ bàtà 3000

Oju orórì Ayaba Sheba:

Ibudo ti wọn gbagbọ pe wọn sin Ayaba Sheba si, ti itan rẹ wa ninu Bibeli laye Ọba Solomoni, lo wa ni Ijebu Ode, Ipinlẹ Ogun.

Abule Oke-Eiri, to wa lagbegbe Ijebu Ode, nipinle Ogun lo gbalejo ibi ti won sin Ayaba naa si.

Bẹẹ lo tun jẹ ibi ti awọn arinrinajo afẹ maa n wa ni ọdọọdun lati bu ọla fun oju orori oku ọrun naa ti wọn tun n pe ni ayaba Bilikisu.

Bibeli Onigbagbọ ṣapejuwe ayaba Shẹba gẹgẹ bii obinrin ti o ni agbara ati ọgbọn, ti o wa lati ṣabẹwo si Ọba Solomoni nigbati o gbọ nipa ọgbọn ti o tayọ ti oba Solomoni ni.

Oju orórì Ayaba Sheba

Oke Olumo:

Oke Olumọ jẹ ọkan gboogi ninu awọn ibudo afẹ to n bẹ n'ipinlẹ Ogun.

Titobi oke naa jẹ nnkan pataki ti o nii ṣe pẹlu idasilẹ ilu Abẹokuta, ti itumọ rẹ jẹ ilu ti o wa labẹ okuta) gẹgẹ bi iwadii ṣe fi idi rẹ mulẹ.

Lasiko ogun atijo, oke yii jẹ ibi isadi ti o daabo bo awọn eeyan ilu lọwọ ogun.

L'ọdun 1976 ni Oke Olumọ di ibudo afẹ, ki aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ to fi idi rẹ mulẹ gan an ni san an l'ọjọ kẹta oṣu keji ọdun 2006.

Fidio nipa Oke Olumo ti BBC Yoruba se ree nisalẹ yii.

Àkọlé fídíò, Olumo Rock: Òrìṣà Igùn lọba ọ̀pọ̀ òrìṣà tó wà lábẹ́ Olúmọ tó ń dáhùn àdúrà

Ipinlẹ Osun:

Odo Osun Osogbo:

Alaye nipa ibudo afẹ n'ipinlẹ Ọṣun ko ni kun to lai mẹnuba odo Ọṣun Oṣogbo.

Odo Osun yii bẹrẹ si ni n ṣan lati Igede-Ekiti, wọ ipinlẹ Ọṣun ni ẹkun guusu Naijiria lọ si ilu Eko titi ti o fi de inu okun lorilẹede Guinea.

Itan ti o rọ mọ odo naa ni pe obinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ọṣun lo binu di odo naa.

O gbe igbesẹ ọhun lẹyin ede aiyede to waye laarin oun ati orogun rẹ, 'Ọbà' ti wọn jọ jẹ aya Sango.

Ọdọọdun si ni wọn n bọ odo Osun nibi ti ọpọ awn arinrinajo afẹ labẹle ati nilẹ okeere maa n peju si.

Inu osu kẹjọ ọdọọdun si ni wọn maa n bọ Odo Osun ti wọn n pe ni Arẹmọ nitori igbagbọ awọn eeyan ni pe o maa n fun awọn agn ni ọmọ.

Ajọ agbaye to n se agbelarugẹ asa, UNESCO si ti fi ontẹ lu Ojubọ Osun Osogbo lọdun 2005 gẹgẹ bi ọkan lara awọn ibudo iṣẹmbaye ti wọn n mojuto.

Lara awọn eewọ odo naa ni ẹja pipa, ọdẹ ṣiṣẹ ati gige igi ni ayika naa.

Fidio bi n se n bọ Osun Osogbo ree nisalẹ yii ti BBC se.

Àkọlé fídíò, Osun Osogbo: Ọdọọdún ni Àtáója ń gbàlejò gbogbo arugbá lásìkò ọdún Ọ̀ṣun Òṣogbo

Ọ̀pá Oranmiyan:

Ọpa Ọranmiyan kalẹ si ilu Ile-Ifẹ n'ipinlẹ Ọṣun.

Ọranmiyan, ti o jẹ ọmọ Oduduwa lo fi ọpa kan lọlẹ ni ẹgbẹlẹgbẹ ọdun sẹyin.

Lati igba naa si ni o ti wa gẹgẹ bi wọn ṣe fi lọlẹ.

Ayika ibi ti ọpa Oranyan wa ni agbegbe Arubidi ni ilu Ile-Ifẹ, ti di ohun ti awọn arinrinajo afẹ n lọ pe wo.

Amọ eewọ to wa nibẹ ni pe o ni ibi ti ajeji lasan, ti kii ṣe ọmọ ile to n bọ ọpa naa le de ni ayika ibi ti ọpa ọhun wọlẹ si.

Ojubọ ọpa Oranyan