Màálù kan akẹ́kọ̀ọ́jáde pa lọ́jọ́ ayẹyẹ àṣekágbá ẹ̀kọ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, EBIRA4REAL/FACEBOOK
Akẹkọọjade fasiti ipinlẹ Kogi, KSU kan, Joel Felix Akowe, ti ọpọ awọn ọrẹ rẹ mọ si Joe Black, ti dagbere faye.
Joe Black, to ṣẹṣẹ ṣetan nile ẹkọ naa jade laye lọjọ kan naa to n ṣe aṣekagba ẹkọ ‘project defence’ rẹ.
Ọjọ kejila, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 lo kọ idanwo rẹ to kẹyin, ti aworan bo ṣe dọbalẹ fun baba rẹ si ti gba gbogbo ori ayejara kan.
Bi iku Joe Black sẹ waye
Logunjọ, oṣu Kẹsan an to pari idanwo rẹ kan naa ni Joe Black ati ọrẹ rẹ n rinrinjo lọ si ijọba ibilẹ Dekina, nipinlẹ Kogi to ti kawe ti wọn si pade awọn darandaran kan, ti ọkan lara awọn maalu darandaran naa si ṣakọlu si wọn.
Ọkan lara awọn ọrẹ rẹ ti ko fẹ ki a darukọ oun ṣalaye fun BBC pe abule Ologba ni ikọlu naa ti waye ti awọn si gbe e lọ sile iwosan lẹsẹ kan naa amọ o jade laye lẹyin ọjọ mẹta.
O ni “Oun funra rẹ lo wa alupupu ti wọn gbe lọ si abule naa ki wọn to pade awọn maalun ọhun ni Ologba, eyii ti wọn yoo kan ki wọn to de abule wa.”
Ọrẹ oloogbe naa ṣalaye siwaju si pe o farapa yanayana lẹyin ikọlu ọhun ti ọkan lara awọn maalu naa ṣe si.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, Joe Black jẹ ẹni ti kii ṣe imẹlẹ, ati pe o tilẹ ti n pinnu oun ko ni ṣe agunbanirọ lẹyin ẹkọ rẹ lọna ati bẹrẹ owo cashew.
O ni “Joe Black jẹ onirẹlẹ eeyan to maa n bọwọ fun gbogbo eeyan, bẹẹni kii n bu eeyan.”
Lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi, William Aya sọ fun BBC pe oun ko tii gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun rara.
Ọpọ awọn ọrẹ ati ololufẹ oloogbe naa lo ti bẹrẹ si n daro rẹ bayii lori ayelujara.
Ẹni ọdun mẹrinlelogun ni Joe Black ki ọlọjọ to de.















