Kàyééfì! ọmọ ọdún mẹ́wàá bínú gbé ọkọ̀ àwọn òbí rẹ̀ sálọ nítorí pé wọn gba 'tablet' lọ́wọ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, ALACHUA COUNTY SHERIFF/FACEBOOK
Iroyin eleyi kọja arosọ.
Ọwọ palaba ọmọ ọdun mẹwaa kan ti ṣegi lẹyin tawọn ọlọpaa gba a mu pe o n da ọkọ wa loju ọna marosẹ.
Iyalẹnu lo jẹ fawọn ọlọpaa Florida lorileede Amẹrika nigba ti wọn da awakọ kan duro loju ọna marosẹ.
Kaka ki agbalagba sọ kalẹ ninu ọkọ ti wọn da duro, ọmọdekunrin ọdun mẹwaa kan ni wọn ba nidi ọkọ.
Ọmọdekunrin yi ati ẹgbọn rẹ obinrin ọmọ ọdun mọkanla ni wọn jijọ wa ninu ọkọ naa nibi ti wọn ti da wọn duro iyẹn Alachua.
Ibi ti ọwọ ti tẹ wọn jina ni aimọye mẹẹli si ibi tawọn obi wọn ti kọkọ ke gbajare pe awọn mejeeji di awati ni ibẹrẹ ọsẹ.
Awọn ọlọpaa lawọn mejeeji pete pero lati gbe ọkọ salọ lẹyin tawọn obi wọn gba awọn ẹrọ ibaraẹnisọrọ lọwọ wọ.
O jẹ iyalẹnu fawọn oṣiuṣẹ wa lati ri pe awakọ ọmọdekunrin ọdunmẹwaa bọlẹ ninu ọkọ pẹlu ọmọ iya rẹ obinrin''
Bẹẹ ni alaye ti ileeṣẹ ọlọpaa Alachua ṣapejuwe idauro tawọn ọlọpaa da awọn awakọ duro ni nkan bi ago mẹrin ku iṣẹju mẹwaa loru Ọjọbọ.
Iya awọn ọmọ naa ti ṣaaju fi to awọn agbofiunro leti pe awọn n wa ọkọ Sedan funfun tawọn ọmọ naa wa.
North Port Florida lo ti fẹjọ sun.Iwọn mẹẹli igba(320km)ni o fi jina si Alachua ti wọn ti pada ri awọn ọmọ rẹ ati ọkọ to dawati.
Iwadii ọlọpaa fi han pe awọn ọmọ naa ko dunnu si iya wọn nitori pe o gba awọn ẹrọ ibaraẹnisọrọ taabu ati foonu lọwọ wọn nitori pe wọn ko ṣamulo rẹ daada.
Awọn ọlọpaa fi kun ọrọ wọn pe awọn ko riapẹrẹ kankan wi pe wọn n fiya jẹ awọn ọmọde yi.
Wakati mẹ́ta gbako ni iya wọn fi wa kọ wa si Alachua to ti wa gba awọn ọmọ ati ọkọ pada.
Ni ipinlẹ Florida lorileede Amẹrika,ọdun mẹẹdogun leeyan le jẹ ko to le gba iwe aṣẹ kikọ ọkọ wa taa mọ si learners permit.
Bi eeyan o ba si wa ọkọ, o gbọdọ pe ọdun mejidinlogun ko to le kọwe pe oun fẹ gba iwe aṣẹ ọkọ wiwal.
Awọn ọlọpaa ṣalaye pe awọn ba iya awọn ọmọ yi sọrọ lori na to le gba tọ awọn ọmọ naa.
Wọn ni iya awọn ọmọ naa tẹti gbọ gbogbo imọran ati aba ti wọn gbaa lọna ati ri iranwọ gba ki o baa fi le tọ awọn ọmọ yi daada.
Nitori ọjọ ori awọn ọmọ yi, wọn ko kede orukọ wọn bẹẹ si ni wọn ko ba wọn ṣe ẹjọ lori aṣiṣe yi.















