Man allegedly sleeps with wife's cousin: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ arákùnrin ẹni ọdún 35 tó fi ipá bá ọmọ ọdún 11 ìbátan ìyàwó rẹ lò pọ̀

Aworan afurasi to ba ọmọde lo pọ

Ọwọ palaba arakunrin ẹni ọdun marundinlogoji kan ti wọn fẹsun kan pe o fipa ba ọmọ ọdun mọkanla kan lo pọ ti segi ni ipinlẹ Ogun.

Ọmọdebinrin naa to fipa ba lo pọ la gbọ pe o jẹ ibatan iyawo rẹ to n gbe lọdọ oun ati iyawo rẹ.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun Abimbola Oyeyemi lo fi ọrọ yii sita ninu atẹjade kan pe Idowu Shittu ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayi.

Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf

Gẹgẹ bi Oyeyemi ṣe sọ, afurasi naa to n gbe ladugbo Halleluyah ni Ifo lọwọ tẹ lẹyin ti iyawo rẹ wa fẹjọ sun lagọ ọlọpaa to wa ni Ifo.

O sọ pe arabinrin naa ni ọmọde yi ti n fara da ibalopọ tipa yi to nkan bi ọdun mẹta ki o to pada sọ fun ''auntiẹ'' rẹ to jẹ iyawo arakunrin yi.

Ọmọ ọhun s pe nitori pe afurasi naa maa n halẹ mọ ohun lo jẹ oun dakẹati pe ko si ibi ti oun le lọ nitori awọn obi rẹ ti ku.

Igba ti iroyin aduru nkan ti arakunrin yi ṣe de etigbọ awọn ọlọpaa ni wọn lọ si ile rẹ lati lọ mu.

Alukoro ọlọpaa sọ pe lyin ifọrọwanilẹnuwo, afurasi naa sọ pe lootọ loun hu iwa yi ṣugbọn o bẹrẹ si ni tọrọ aforijin lọdọ ọmọ naa.

Kọmisana ọlọpaa ipinl Ogun ti ni ki wọn gbe arakunrin naa lọ si ẹka to n risi ifiyajẹọmọde fẹkunrẹrẹ iwadii.

Ọmọdebinrin ọhun ti wa ni ile iwosan to ti n gba itọju.