Domestic Violence in Benue: Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún dáná ṣun ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ lẹ́yìn eré ìfẹ́

Omah ko to ku ati lẹyin iku rẹ

E wo ni ki ololufẹ sun lalẹ, ki wọn fi ẹnu ko ẹnu, ki o si ji pẹlu irora ina ni ara rẹ, eyi to si jasi iku ọrẹkunrin rẹ.

Bayii ni ọrọ ifẹ laarin Elvis Chinma Omah, to n ta oogun ati ọrẹbinrin rẹ ri ni ilu Markurdi, to jẹ olu ilu Benue.

Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni ọrẹbinrin Omah ti awọn mejeeji si jẹ ọrẹ kori kosun, ti wọn si ti jẹ ololufẹ fun ọdun mẹta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ifẹ wọn gbona to bẹẹ ti wọn ṣe ibura fun ara wọn wi pe, awọn ko ni dalẹ ara awọn, ati wi pe igbeyawo ni yoo kẹyin irinajo ifẹ wọn.

Ile Omah ti Esther dana sun

Amọ ọjọ ko tọjọ, osu ko to osu, ti olobo ta ọrẹbinrin pe Omah, to gbẹmi le bi ọkọ afẹsọna ti n nifẹ ikọkọ pẹlu obinrin miran.

Esther bẹrẹ si ni binu nigbati awọn ọrẹ rẹ sọ fun wi pe Omah ti ni ẹlọmiran o, to si ti fẹ ṣe igbeyawo pẹlu rẹ ni abule wọn.

Bi o tilẹ jẹ pe Omah sọ wi pe ko si otitọ ninu ọrọ naa fun Esther, amọ ko gbagbọ, ti o si pinu lati dana sun arakunrin naa, ki ifẹ wọn kuku pari.

Esther lasiko to n wi tẹnu rẹ fun awọn ọlọpaa sọ pe, Omah lo gba ibale oun, to si ṣe ileri fun oun wi pe oun ko ni dalẹ.

Ile Omah ti Esther dana sun

Amọ, o ni Omah ko ṣe olotitọ pẹlu oun, n ṣe lo n ko obinrin kaakiri, ti yoo si sọ fun oun pe ki oun sun si ori ilẹ, nigba ti awọn ọrẹbinrin rẹ ba n wa si inu ile.

Lẹyin ọpọlọpọ ija ni o kọ Omah silẹ, amọ o ni Omah wa bẹ oun pada wi pe ki awọn pari ija, ki ifẹ wọn si pada si bi o ṣe wa tẹlẹ.

Esther gba ẹbẹ Omah, amọ o gbe garawa bẹntirol dani, to si tọju rẹ si ita ki o to wọle tọ Omah lo ninu ile rẹ.

Esther dana sun Omah lẹyin ibalopọ ati ifẹnukonu:

Omah ṣẹṣẹ de lati Enugu ni nigbati Esther wọle tọ ọ wa, lẹyin ti wọn pari ija laarin ara wọn.

Esther se ounjẹ alẹ fun, wọn jẹun, ti wọn si gbadun ara wọn, ki o to di wi pe wọn gba ibusun lọ.

Lẹyin ti wọn jọ sun, ni Esther dide to si lọ gbe bẹntirol, to si da a yika yara Omah, ko o to sọ ina si.

Àkọlé fídíò, Itaniji: Oluwo sọ ìtàn bí Orunmila ṣe jìyà nílùú Iwo àti ayọ̀ tó gbẹ̀yìn rẹ̀ torí sùúrù

Esther salọ si ile ijọsin to wa nibẹ lẹyin ti ina sọ ninu yara Omah.

Awọn ara adugbo lo gbọ igbe Omah, ki wọn to sare lati doola ẹmi rẹ, amọ o ti jona kọja keremi, ti o si jasi iku rẹ.

Agbẹnusọ fun olu ileeṣẹ ọlọpaa ni Benue ni, otitọ ni iṣẹlẹ naa waye ati wipe awọn yoo gbe Esther lọ si ileẹjọ lẹyin ti iwadii ba pari lori iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa naa fikun wi pe, iru iṣẹlẹ bẹẹ mẹta lo ti waye ni ipinlẹ naa, nibi ti awọn ololufẹ ti dana sun ara wọn.