Paul Okoye fàbínú yọ lórí ọ̀rọ̀ìkíni tí ìyàwó ìbejì rẹ̀ Lola Omotayọ kọ, ẹ wo ohun tó sọ

Aworan Paul Okoye ati Lola Okoye

Oríṣun àwòrán, Instagram

Tẹbi tọrẹ a maa fi ayajọ ọjọ ibi kini ku orire,gbogbo wa la mọ bẹ.

Sugbọn ti ọjọ yi ba wa di ọjọ ti eeyan tako ọrọ si ara ẹni, ki lo le fa iru nkan bayi?

Ibeere to gbẹnu awọn ọmọ Naijria re lẹyin ti ilumọọka olorin takasufe nii Paul Okoye, P Square, bẹrẹ si ni tako ọrọ si iyawo ibeji rẹ, Peter Okoye ti ọrọ naa si gbori ayelujara kan.

Lola Omotayo to jẹ iyawo Peter Okoye lo ki ọkọ rẹ ku orire ọjọ ibi loju opo ayelujara.

Lẹyin to ki olowo ori rẹ tan, lo ba ki ibeji rẹ Paul Okoye sugbọn kiki yi tun mu ọrọ arọwa lọwọ.

Ọrọ ti Paul Okoye fifesi fun Lola Okoye

Oríṣun àwòrán, Instagram iamKingRudy

Ninu ọrọ rẹ o sọ pe

"Hmmm…. ẹyin ibeji @peterpsquare @iamkingrudy bi ẹ fẹ bi ẹ kọ, ọmọ iya ni yin. E kii se ọmọ iya nikan, ibeji ni yin.

Mo ki yin ku ayajọ ọjọ ibi! Bintin laye,ẹ ma fi asiko sofo.Ibọwọfunraẹni ati ifẹ se pataki.Bi a se n dagab si, o yẹ

ki a mọ pe aye yi ko se fi falẹ asiko ko si duro de ẹni kan.

Mo wi temi naa!''

Ọrọ yi ko ba Paul nibi to ti gbe da ti ko si jẹ ko pẹ to fi fesi pada fun Lola.

O sọ kobakungbe ọrọ si Lola to si ni oju aye lasan lo n se nitori lati bi ọdun meloo sẹyin awọn ko ki ara wọn.

O ni nitori ki awọn eeyan baa le foju eeyan daada wo lo fi maa n bọ si oju opo ayelujara lọdọdun lati ki oun.

Ẹ wo ẹkunrẹrẹ ọrọ naa bo ti se sọ soju opo Instaagram

Ọrọ ti Paul Okoye fifesi fun Lola Okoye

Oríṣun àwòrán, Instagram/iamkingrudy

Agbemaja ko si ni Yoruba a maa wi, a ja ma pari ohun lo buru.

Ija laarin awọn Ibeji olorin takasufe yi jẹ eleyi tawọn ololufẹ wọn ti n sọ pe ko wa si opin.

Sugbọn pẹlu itakoọrọsiraẹni to n waye yi, ko daju pe ọrọ naa yoo niyanju.

Titi di igba ta fi n sakojọ iroyin yi , Peter Okoye ko ti fesi si ọrọ ti ibeji rẹ sọ.

Bẹẹ ni Lọla iyawo rẹ naa ko fesi pada.