Ooni Crown Prince: Èyí ni bí wọ́n ṣe bí Àrẹ̀mọ tuntun Ọọ̀ni Adeyeye ti Ile Ife àti orúkọ tí ó kọ́kọ́ jẹ́

Ooni Ife Olori Silekunola

Oríṣun àwòrán, Olori Moronke Shilekunola Ogunwusi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iroyin tuntun nipa Arẹmọ kabiyesi Ọọni ile ifẹ to n jade fihan pe ni ileewosan nla ti ijọba apapọ, FMC to wa ni ilu Ọwọ ni wọn bi i si.

Ni owurọ Ọjọru ni okiki kan pe kabiyesi Ọọni Adeyeye Ogunwusi ti ni Arẹmọ lẹyin ti wọn gbẹbi olori rẹ, Yeyeluwa Naomi Silekunola Ogunwusi; lati igba naa si ni wẹjẹwẹmu ti n lọ kaakiri.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, agbẹnusọ fun aafin Oodua, Kọmureedi Ọlafare ṣalaye pe ileewosan nla naa ni wọn bi Arẹmọ Ọọni si.

Iroyin fi idi rẹ mulẹ pe, ni kete ti iroyin ibi arẹmọ wọle ni Kabiyesi Ọlọwọ ti ilu Ọwọ, Ọba Ajibade Ogunoye ati Olori rẹ, Adenikẹ ti n dawọ idunnu. Wọn wa lara awọn to kọkọ ṣe abẹwo si Arẹmọ tuntun ati Iya rẹ, Olori Naomi Silẹkunọla ni ileewosan nla naa.

Koda iroyin ti a tun n gbọ ni pe Kabiyesi Ọlọwọ ti ilu ọwọ ti fun Arẹmọ tuntun yii lorukọ.

Orukọ ti kabiyesi fun arẹmọ ni 'Aderiye".

Kabiyesi Ọba Ajibade ṣalaye pe ibi Arẹmọ naa tun tubọ fi idi ajọṣepọ lati iṣọkan ati ipilẹ to wa laarin Ifẹ ati Ọwọ mulẹ ni.

Àkọlé fídíò, Grandma Maruwa: Ó yẹ kí obìnrin sisẹ́ láì wojú ọkọ kó tó jẹun

Olori Ọlọwọ ti ilu Ọwọ, Adenikẹ Ogunoye la gbọ pe o lewaju ikọ awọn agba oloye ilu Ọwọ gẹgẹ bi awọn to kọkọ ṣe abẹwo si Arẹmọ tuntun ati Iya rẹ, Olori Naomi Silẹkunọla ni ileewosan nla naa.

Awọn oloye to wa pẹlu Olori Adenikẹ ni Agbaoye Tunde Elerewe, Akọwe fun Ọlọwọ, Oloye Amos Aladeṣẹyẹ, Oloye Mudongho pẹlu Iyalode Ẹhin Ogbe, Oloye Ọbademi.

Bakan naa ni agbẹnusọ fun aafin Ooodua ni ile Ifẹ, Kọmureedi Ọlafare pẹlu fi idi rẹ mulẹ pe awọn oloye lati Ile Ifẹ pẹlu ti kan si Arẹmọ ni kete ti iroyin naa kan Kabiyesi Ọọni lara.

Bi o tilẹ jẹ wi pe agbẹnusọ fun aafin Oodua ko ṣalaye awọn oloye to lọ ni pato, iroyin ti a gbọ fi idi rẹ mulẹ pe alamojuto abo ibilẹ fun Ọọni, Saarun Oodua, Oloye Oriowo Oriyọmi lo lewaju awọn agba oloye Ile Ifẹ bii Akọgun Waasin, Lowaatẹ ati Ẹrẹbẹsẹ lọ ki Arẹmọ tuntun kaabọ sile aye.

Wo ìròyìn tuntun tó tún jáde laááàfin Oòduà nípa Àrẹ̀mọ tuntun Ọọ̀ni Ile Ifẹ̀

Ooni Ife Olori Silekunola

Oríṣun àwòrán, Olori Moronke Shilekunola Ogunwusi

Iroyin lati aafin oodu ni ile Ifẹ ni yewa pe rẹpẹtẹ ni wẹjẹwẹmu n lọ laafin Kabiyesi Ọọni niluu ile Ifẹ lẹyin ibi Arẹmọ ile Oodua lowurọ Ọjọru.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni kete ti awọn araalu ti gbọ iroyin naa ti bọ sita lawọn eeyan ti ya wọ aafin ti wọn si ti bẹrẹ gbogbo ijo ati ilu; bẹẹ ni orin n lọ lakọlakọ.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe iroyin bọ̀ sita lowurọ Ọjọru ni kabiyesi, Ọọni ti Ife, Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi kede pe iyawo oun, olori Naomi ti bimọ.

Ọọni fi si oju opo opo Instagram rẹ pe "gbogbo ọpẹ ni fun Ọlọrun fun ore nla to ti ṣe.

Ọọni Adeyeye ni oun ki gbogbo ara ile Oduduwa ati Olori Silekunola to ṣẹṣẹ bi Arole ọmọ fun itẹẹ Oduduwa.

O si fi to awọn eeyan leti wipe ilera pipe ni iya ati ọmọ wa.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ṣaaju ni nkan bii oṣu kan o le diẹ sẹyin ni awọn rẹdio ẹlẹjẹ n gbe iroyin kiri nigba ọjọ ibi ko tii to pe Ọọni ti bimọ ṣugbọn ti BBC Yoruba kan si aafin Ọọni Adimula gangan, a bu ẹnu atẹ lu iroyin ofege pe ko ri bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Ọọni Ogunwusi Adeyẹye pe fun itọju awọn ọdọ

A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?