Lẹyin iku Ginimbi ọrẹ rẹ, Davido ni asan lohun meremere aye jẹ

Davido

Oríṣun àwòrán, Twitter/davido

Ilumọọka olorin takasufe ọmọ Naijiria ti ọpọ mọ si Davido ti ni gbogbo ohun meremere aye ko jẹ nkankan si oun.

Davido to se pe a maa safihan awọn ẹsọ ati ọkọ ayọkẹlẹ lorisirisi ninu fidio orin rẹ ati loju opo ayelujara lo di ẹni to n waasu lẹyin iku ọrẹ rẹ ni, gbajumọ ayelujara ọmọ Zimbabwe, Ginimbi.

Lasiko to n kopa ninu eto kan lori ileesẹ redio Apple Music pẹlu DJ Cuppy lo sọrọ yi to si ni awọn nkan yoyoyo aye ko jọ ohun loju mọ.

Lori eto naa Davido sọ pe lọwọ yi, nini anfaani lati maa mi soke silẹ lo se patakai si oun.

O wa fi lede bakan naa pe lati igba ti ọrẹ oun Ginimbi ti papoda ni oun ti ri pe asan lori asan lawọn nkan meremere aye jẹ.

''Nise lo da bi ẹni pe gbogbo awọn nkan meremere aye ko jẹ nkankan si mi mọ.

Mo sẹsẹ padanu ọrẹ timọtimọ kan ni lati Zimbabawe torukọ rẹ n jẹ Ginimbi.

Eeyan daada lo jẹ, Ki si ni nkan ti eeyan n ni laye ti ko ni.

Gbogbo nkan lo ni''

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?

Asẹyinwa asẹyinbọ, iku rẹ kọmi lẹkọ pe ko si nkan ta ni laye yi to ju atẹgun taa n mi sinu lọ.

O le jẹ olowo tabi talaka sugbọn ipo kipo too ba wa, maa dupẹ pe o wa laye''

Akọrin yi tunbọ salaye pe okiki toun ni jẹ ki awọn eeyan maa gbe ọmọ rẹ obinrin gẹgẹ nileẹkọ rẹ.

''Nigbakigba ti ọmọ mi ba lọ si ileewe, a maa sọ fun awọn eeyan pe 'Davido ni baba mi.Wọn a maa tori eleyi foju ọtọ wo sawọn akẹgbẹ rẹ.''