Shasha Fire: Ìgbìmọ̀ tí adelé alága ìjọba ìbílẹ̀ Guusu-Akinyẹle yàn sí ọja Shasha ló da iná ọjà náà rú

Shasha

Alaga ọja Shasha to jona ni Ibadan, Alhaji Usman Idris Yakub ti sọ pe igbimọ kan ti adele alaga ijọba ibilẹ Guusu-Akinyẹle, Ahmed Kazeem Adekunle yan si ọja lo da ina ọja naa ru ki ina to ṣẹyọ nibẹ.

Idris Yakub lo fi ọrọ naa lede nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to gbagbọ pe o ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.

O ni nnkan bii aago mẹrin aabọ idaji ọjọ Iṣẹgun ni wọn ṣa dede gbọ pe ọja wọn gbina nipasẹ ina ijọba ti wọn mu de.

O tẹsiwaju pe ni ọjọ kẹta ṣaaju ọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹ, igbimọ ti adele alaga ijọba ibilẹ Guusu-Akinyẹle yan si ọja ọhun wa da ina ọja naa ru.

Shasha

Yakub ni wọn gbe igbeṣe yii botilẹ jẹ wi pe ina ọba ti n tan nibẹ lati nnkan bi i ọdun mẹwaa sẹyin.

Alaga ọja Ṣaṣa ọhun ni aṣiṣe igbimọ naa lo ṣokunfa ijamba ina to ṣe akoba fun ọpọlọpọ ṣọọbu ati awọn dukiya mii.

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?

Bakan naa lo fi ẹsun kan adele alaga ijọba ibilẹ naa pe gbogbo owo ti wọn n gba lọwọ awọn ontaja ni ko si koko nnkan gidi kan ti wọn fi n ṣe.

Yakub fi kun ọrọ rẹ pe ọpọlọpọ owo ti awọn ontaja dá jọ si ofisi oun lo ti jona bayii.

O wa rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Ọyọ lati boju aanu wo awọn eeyan ti wọn padanu dukiya wọn sinu ijamba ina naa ki wọn le bọriyọ ninu gbese to n bẹ nilẹ bayii.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ọwọ́jà iná ńlá sọ ọjà Shasha dahoro n'Ibadan

Ijora

Awọn onimọ ti kilọ lasiko yii pe bi asiko ọyẹ ṣe n sumọ, ki awọn eeyan ṣọra gidi ki wọn ma baa ṣe afọwọfa ija ina.

Iru eyi gaan lo burẹkẹ gẹgẹ bi ikọlu kọgba ṣe waye ni ọja ilu Shasha ni Ibadan tii ṣe olu ilu ipinlẹ Oyo.

Lọjọ Iṣẹgun ọsẹ ni wọn dede ri i ti ina bẹ silẹ to si bẹrẹ si ni jo oile itaja lọ raurau pẹlu ọpọlọpọ dukia to ṣofo.

Àkọlé fídíò, Àṣírí tú! Ikọ̀ ìwádìí BBC ṣí àwọn tó ń jí ìkókó gbé sí gbangba

Ọgbẹni Adewale to gbẹnusọ fun awọn ọlọpaa sọ fun awọn oniroyin pe "wọn pe wa ni nkan bii agogo mẹrin owurọ kọja iṣẹju mẹẹdogun nigba ti ina yii bẹrẹ si ni jo ni ọja naa".

Adewale ni agọ awọn to wa ni agbegbe Oyo State Secretariat lo tara ṣaṣa lọ si ibẹ ti wọn si fabọ jẹni pe ile itaja bii ọgbọn lo jona raurau.

"A gbọ pe iṣẹlẹ naa waye lasiko ti wọn mu ina ijọba to ti lọ de pada lagbegbe ọhun lowurọ kutukutu ọjọ Iṣẹgun naa.

Ọja Shasha jẹ ibi itaja nla fun oniruuru eso torinaa idi, apẹrẹ lọpọlọpọ ni wọn ko jọ si ibẹ lo sare ran mọ ina ọhun.

O wa ṣekilọ fawọn eeyan pee oju lalakan fi n ṣọri lasiko ọyẹ bo ba ti n sunmọ si ni ki wọn ti maa ṣọra ki wọn ma baa ri ija ina loriṣiriṣi ọna.

"A gbudọ rii pe ka to jade kuro ni ile tabi ibi iṣẹ, gbogbo oju amunawa ni wọn yọ kuro lati dena ina jijo.

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?