Ibadan Tailor: Ilé-ẹjọ́ dá ẹjọ́ lòdì sí ìwà ọ̀gá ọlọ́pàá sí télọ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Oyo Insight
Ileẹjọ majisreeti to wa lagbegbe Iyakangu niluu Ibadan ti yi ẹjọ ti ọga ọlọpaa DPO, CSP Alex Sani Gwazah pe telọ kan, Lukman Adeniyi danu.
DPO Gwazah eleyii ti ko tii yọju sile ẹjọ lati igba ti igbẹjọ naa ti bẹrẹ pe Adeniyi lẹjọ pe o ba aṣọ ti oun gbe fun lati ran jẹ.
Ọga ọlọpaa DPO naa sọ ninu ẹjọ to pe telọ Adeniyi pe iwa ọdaran gbaa ni aranṣọ ọhun hu.
Aṣoju ọga ọlọpaa naa sọ fun ileẹjọ pe DPO naa ko le yọju sile ẹjọ nitori o wa igbimọ to n ṣewadi iwadii ifẹhonuhan EndSARS.
- Genesis Global: Ṣé lóòtọ́ ni pásítò ìjọ Celestial, Israel Oladele Ogundipe rẹ́wọ̀n hẹ?
- Adájọ́ ní Seun Egbegbe ṣì lẹ́jọ́ láti jẹ́ lórí ẹ̀sùn gbájúẹ̀
- Kíní ìtumọ̀ ''Sọ̀rọ̀ Sókè'' tí àwọn afẹ̀họ́núhàn EndSars ń lò káàkiri
- Ẹ̀mí ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò lọ tí ààrẹ Trump kò bá gbé ìpò sílẹ̀ - Joe Biden
- Báwo làwọn agbébọn ṣe rí ASP Ọlọ́pàá méjìlá jígbé lójú ìbọn?
- Ìtàn ayé Abiola Peller, ọlọ́wọ́ idán tó fi ọ̀bẹ gé ìyàwó rẹ̀ sí méjì
Ṣugbọn agbẹjọro telọ sọ pe irọ nla ni, o fidi rẹ mulẹ pe DPO naa ko si lara igbimọ to n ṣewadi iwọde EndSARS.
Ninu idajọ rẹ, Majisreeti Olajumoke Akande yi ẹjọ DPO naa danu, o si ni ki telọ Adeniyi maa lọ lalaafia.
Adajọ Majisreeti Akande sọ ninu idajọ rẹ pe bi ẹjọ to pe telọ yìí ba ṣe pataki si i, yoo waye lati wa nile ẹjọ fun igbẹjọ.
Adajọ ni ọga ọlọpaa Gwazah ko ni idi bo ti le wu kori lati ma yọju sile ẹjọ, to ba jẹ pe ọrọ naa ka a lara.
Ẹwẹ, agbẹjọro telọ Adeniyi, Jubril Mohammed ni oun ṣetan lati gbe ẹjọ naa lọ siwaju igbimọ igbẹjọ ti Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ṣẹṣẹ ṣe ifilọlẹ rẹ.
O ni ọga ọlọpaa DPO gbọdọ san owo gba maa binu fun Adeniyi nitori ẹjọ to pe e ko l'ẹsẹ nlẹ.
Ṣaaju nigba ti ọrọ yii ṣẹlẹ̀, DPO ọlọ́pàá naa ju télọ̀ yii sátìmọ́lé, o tun gbé e lọ sílé ẹjọ́ n'Ibadan torí o ni "ó ba aṣọ mi jẹ́''.
Telọ Lukman Adeniyi wọ gau niluu Ibadan lẹyin ti DPO ileeṣẹ ọlọpaa to wa lagbegbe Iyaganku gbe lọ sile ẹjọ.
Ẹsun ti DPO naa, Alex Gwazarzah fi kan Adeniyi ni pe o gbe aṣọ oun fun ọmọṣẹ rẹ lati ran.
Aawọ ṣẹlẹ laarin awọn mejeeji lẹyin ti ọga ọlọpaa ni Adeniyi ti ba aṣọ oun jẹ.
- Kàyééfì! Tọkọ taya kú lọ́jọ́ kan náà l'Abeokuta lẹ́yìn ìgbéyàwó ọdún méjìléláàdọ́rin 72
- Remilekun Fatolu bú sẹ́kún fún ohun tó ti pàdánù láyé torí ọyàn ńla rẹ̀.
- A ó ṣèrànwọ́ fáwọn ẹbí ọlọ́pàá tó bá rògbòdìyàn EndSARS lọ láti inú N500m tí a yà sọ́tọ̀- Makinde
- Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo jáwée lọ sinmi nílé fún alága ìgbìmọ̀ mẹ́tàlá káàkiri ìjọba ìpínlẹ̀
- Èèyàn mẹ́tàdínlógóje 137 ló kó covid-19 lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ọgọ́ta wá láti ìpínlẹ̀ Eko
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi ṣalaye pe ọga ọlọpaa Gwazarzah ti sọ fun Adeniyi tẹlẹ pe oun lo ma ran aṣọ ti oun gbe fun un funra rẹ.
Ọgbẹni Fadeyi ni ọrọ bẹyin yọ nigba ti Adeniyi gbe aṣọ ọhun fun ọmọ iṣẹ rẹ lati ran.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti gbọ si ọrọ naa, yoo si wa nkan ṣe sii.
Telọ naa ni Alhaji Idris Bawa kan ti oun ti mọ fun ọun mẹwaa lo mu oun mọ DPO ọhun.
Adeniyi ni DPO Gwazarzah dunkoko mọ oun nigba ti oun lọ gbe aṣọ rẹ fun un lori ẹsun pe oun ko ran aṣọ naa daadaa.
''Ọga ọlọpaa Gwazarzah gbami leti, o si tun gba aṣọ mejila ti mo ba ran an lai san ọgọta ẹgbẹrun un naira ti a jọ fẹnu ko si,'' Adeniyi lo sọ bẹẹ.
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Joe Biden, tó ń kojú Trump nínú ìbò America
- Kíní ọ̀nà àbáyọ sí ìjàmbá ọkọ̀ tó ń wáyé lemọ́lemọ́ ní Ọjà Akungba,ní Ondo?
- Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo jáwée lọ sinmi nílé fún alága ìgbìmọ̀ mẹ́tàlá káàkiri ìjọba ìpínlẹ̀
- 'Ìdí tí kámẹ́rà táa rí ní Lekki Tollgate kò fi ká gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé rè é'
- Wo àfipábánilòpọ̀ ẹni ọdún 51 tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti tú làṣirí ní gbangba
Adeniyi ṣalaye pe DPO ọhun ni ki oun wa gba owo lọjọ Abamaẹta ọjọ kinni oṣu kọkanla ni o fi o ju oun si atimọle.
Iroyin sọ pe ọjọ Aje ni Adeniyi kuro latimọle ọjọ Iṣẹgun ni ọga ọlọpa DPO gbe lọ si ileẹjọ.
- Banki Nàìjíríà, CBN ṣàlàyé nípa àwọn tó máa rí gbà nínú owó ìrànwọ́ N75b tíjọba gbé kalẹ̀
- Wo ọ̀nà àbáyọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí àjọ WAEC gbẹ́sẹ̀ lé èsì ìdánwò wọn
- Ẹ dẹ̀kun lílo Sniper àti Dichlorvos fún ìtọ́jú oúnjẹ- NAFDAC kìlọ̀
- ''Àjọ NERC ti fún Disco láṣẹ láti padà sí owó tàríìfù tuntun iná mọ̀nàmọ́ná''
- EFCC bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn ìwà jẹgúdújẹrá tí wọ́n fi kan Fowler tó jẹ́ Alága iléeṣẹ́ FIRS tẹ́lẹ̀
Ìgbónára ló máa ń mú àwọn èèyàn ṣe "Jungle justice" tí ìjàmbá ọkọ̀ bá ṣẹlẹ̀- Dokita
Dokita to n ṣetọju arun ọpọlọ kan, Dare Omowumi, ti sọ pe idi ti awọn eeyan ṣe maa n ṣedajọ gbigbona latọwọ ara wọn ni ara gbibona ati ai lee ni suuru.

Omowumi tun ni a i ki n riidajọ ododo gba lati ọdọ awọn agbofinro lo faa ti awọn eeyan ṣe maa n ṣe idajọ lati ọwọ ara wọn.
Dokita Omowumi lo sọ ọrọ naa lẹyin ti awọn ọdọ kan dana sun ọkọ akero lẹyin ti awakọ rẹ pa ọlokada kan ninu ijamba ọkọ to waye lagbegbe Idi Ape, ni ilu Ibadan.
- Oyinkan Abayomi, akọni obìnrin tó fi ìfẹ́ pa orúkọ ọkọ kejì dà sí ti ọkọ àárọ̀
- 'Àwọn ọlọ́pàá tó farapa nínú ìwọ́de EndSARS yóò gba ìgbéga, a ó ṣèrànwó f'ẹ́bí àwọn tó kú'
- Àwọn agbébọn kọlu iléèwé, wọn bọ́ olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ sí ìhòhò
- Wo àwọn ọmọ Naijiria mẹ́ta tó jáwé olúborí nínú ìdìbò sílé aṣòfin ilẹ̀ Amẹrika
Dokita ọhun sọ fun BBC Yoruba pe, ni ọpọ igba ti awọn eeyan ba ko ẹjọ lọ si agọ ọlọpaa, awọn ọlọpaa naa kii ṣe idajọ ododo nitori bi wọn ṣe maan gbe ẹbi fun alare nigba miran lo n jẹ ki awọn eeyan ṣe idajọ funran wọn.
O fi kun pe kii ṣe ohun to bojumu ki awọn eeyan maa dana sun ọkọ nigba ti ijamba ọkọ ba ṣẹlẹ nitori wọn ko mọ ẹni to jẹbi iṣẹlẹ naa ki wọn to ṣe idajọ ọwọ ara wọn.
Dokita naa pari ọrọ rẹ pe ni ṣe lo yẹ ki awọn eeyan gbe ẹnikẹni to ba ṣeṣe ninu ijamba ọkọ lọ sile iwosan, ki wọn si tun fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti kaka ki wọn ṣedajọ funra wọn.
Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi sọ fun BBC Yoruba pe kii ṣe ohun to bojumu ki awọn ara ilu maa ṣe idajọ lati ọwọ ara wọn.
O ni "atubọtan ṣiṣe idajọ lati ọwọ ara ẹni kii so eso rere nitori kii jẹ ki awọn agbofinro mọ ẹni to jẹbi."
Fadeyi ni "awọn ara ilu ko laṣẹ lati ṣe idajọ lati ọwọ ara wọn, idi niyẹn ti ọlọpaa fi wa laarin ilu."
O fi kun pe awọn eeyan to maa n dana sun ọkọ n ru ofin to rọ mọ didana sun dukia.
Agbofinro naa ṣalaye pe ti ijamba ọkọ ba waye, ohun to yẹ ki awọn ara ilu ṣe ni ki wọn fi to ọrọ naa lọ ọlọpaa lati bẹrẹ iwadii.
Fadeyi pari ọrọ rẹ pe ai kii fi ọrọ ijamba ọkọ to ọlọpaa leti ni kii jẹ ki awọn eeyan ri idajọ ododo gba lẹyin iru iṣẹlẹ bẹẹ.
Lẹyin naa lo gba awọn ara ilu niyanju lati dẹkun ṣiṣe idajọ ọwọ ara ẹni nitori o lodi si ofin.

Àwọn ọ̀dọ́ dáná sun ọkọ̀ akérò tó ṣekúpa ọlọ́kadà ní Ibadan
Awọn ọdọ kan to n fapajanu ti dana sun ọkọ akero kan lowurọ Ọjọru nilu Ibadan lẹyin ti awakọ naa kọlu ọlọkada kan ti o si da ọmi rẹ legbodo.
Aṣoju ẹṣọ aabo oju popo ni agbegbe naa, Arabinrin Uche Chukwurah fi idi ọrọ mulẹ pe ni agbegbe Idi-Apẹ ni rogbodiyan naa ti ṣẹlẹ.
Chukwurah ni eeyan mẹjọ ni ijamba naa kan lara awọn to n bẹ ninu ọkọ akero kan, ọkọ ayọkẹlẹ kan ati ọlọkada, ṣugbọn ọlọkada yẹn nikan lo gbẹmi mi.
- A ti gbé ìwádìí dìde lórí ìpànìyàn tó wáyé lásìkò ìwọ́de EndSARS- Ilé ẹjọ́ àgbáyé, ICC
- A kó ní sanwó oṣú ASUU láìjẹ́ pé wọ́n gba IPPIS- Ìjọba Àpapọ̀
- Oṣú mẹ́fà ni òṣìṣẹ́ ìjọba tó bá bímọ yóò máa lò nílé kó tó wọṣẹ́ padà- Seyi Makinde
- DPO ọlọ́pàá ju télọ̀ sátìmọ́lé, gbé e lọ sílé ẹjọ́ n'Ibadan torí ''ó ba aṣọ rẹ̀ jẹ́''
Aṣoju ẹṣọ aabo oju popo naa tẹsiwaju pe ijanu ọkọ akero naa to dẹnukọlẹ lo fa ijamba naa, pẹlu alaye wi pe awọn ọdọ kan ti inu bi lori iṣẹlẹ naa ni wọn dana sun ọkọ akero naa loju ẹsẹ.
O ṣoju mi koro naa fi idi ọrọ mulẹ wi pe lori ere ni ọkọ naa ti kọlu ọlọkada ti gbemi mi loju ẹsẹ.
Lẹsẹkẹsẹ ni awakọ sa lọ ti awọn ọdọ kan si dana sun ọkọ akero naa.
Wọn tẹsiwaju wi pe ọkọ akero naa dede ya lọ si oju opopona ibi ti ọlọkada naa n gba bọ ti o ko si ẹnu rẹ.
Afẹ́fẹ́ gáàsì gbiná ní Ijora ìpínlẹ̀ Eko, bó ṣe n ṣẹlẹ̀ rèé
Agolo afẹ́fẹ́ gáàsì kan ti gbina ni agbegbe IJora nipinlẹ Eko lọsan Ọjọbọ, ko si tii lojutuu ni akoko ti a n ko iroyin yii jọ.
Ẹnikan to mọ ẹkunrẹrẹ to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ gaasi naa sọ fun BBC pe o ti le ni wakati kan ti ina yii ti n jo.
Lara ohun ti a kojọ, ibi iṣẹlẹ naa jẹ ibi ti wọn n ko gaasi pamọ si ti wọn si n pe ni "gas farm" ni agbegbe ibi ti ileeṣẹ ati katakara pọ si ni Eko.
Awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA ti de ibi iṣẹlẹ ina naa ti wọn si n gbiyanju lati pa a.
O to ọkọ panapana marun to ti wa nikalẹ lati pa ina ọhun.
A o maa mu ẹkunrẹrẹ wa fun yin loju opo yii bo ba ṣe n lọ...


















