Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo: Oṣú mẹ́fà ni òṣìṣẹ́ ìjọba tó bá bímọ yóò máa lò nílé kó tó wọṣẹ́ padà- Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, @Makinde
Oṣu mẹfa ni oṣiṣẹ ijọba to ba bimọ yoo maa lo nile ki o to wọṣẹ pada-Kọmisọnna Oyo
Ijọba ipinlẹ Oyi ti buwọlu fifun awọn aboyun lẹnu iṣẹ ijọba laaye oṣu mẹfa lati duro nile tọju ọmọ lẹyin ti wọn ba bimọ tan.
Kọmisọnna to n moju to eto idasilẹ ati ikọni ọjọgbọn Daud Sangodoyin, lo sọ eyi di mimọ nilu Ibadan lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lori abajade ipade igbimọ alasẹ ijọba ipinlẹ Oyo.
- Banki Nàìjíríà, CBN ṣàlàyé nípa àwọn tó máa rí gbà nínú owó ìrànwọ́ N75b tíjọba gbé kalẹ̀
- Ẹ dẹ̀kun lílo Sniper àti Dichlorvos fún ìtọ́jú oúnjẹ- NAFDAC kìlọ̀
- Wo ọ̀nà àbáyọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí àjọ WAEC gbẹ́sẹ̀ lé èsì ìdánwò wọn
- ''Àjọ NERC ti fún Disco láṣẹ láti padà sí owó tàríìfù tuntun iná mọ̀nàmọ́ná''
- EFCC bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn ìwà jẹgúdújẹrá tí wọ́n fi kan Fowler tó jẹ́ Alága iléeṣẹ́ FIRS tẹ́lẹ̀
Gẹgẹ bi Sangodoyin se sọ, igbesẹ igbimọ alasẹ ijoba lori ọrọ yii wa ni ibamu pẹlu ajọ isokan agbaye lori ọrọ ilera WHO nitori pe o pọn ni dandan lati fun ọmọ lọyan fun odidi osu mẹfa lai si amulumala.
O wa fi kun pe igba mẹrin ni osiṣẹ ni ore ọfẹ lati gbaaye ibimọ yii lẹnu iṣẹ ijọba ipinlẹ Oyo.
Kọmisọnna salaye pe ile lilọ ni aago meji fun awọn ọlọmọ wẹwẹ ko ni waye mọ ti wọn ba ti wọ iṣẹ pada lẹyin osu mẹfa.
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Joe Biden, tó ń kojú Trump nínú ìbò America
- Kíní ọ̀nà àbáyọ sí ìjàmbá ọkọ̀ tó ń wáyé lemọ́lemọ́ ní Ọjà Akungba,ní Ondo?
- Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo jáwée lọ sinmi nílé fún alága ìgbìmọ̀ mẹ́tàlá káàkiri ìjọba ìpínlẹ̀
- Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo jáwée lọ sinmi nílé fún alága ìgbìmọ̀ mẹ́tàlá káàkiri ìjọba ìpínlẹ̀











