WAEC 2020 result checker: Wo nkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí àjọ WAEC gbẹ́sẹ̀ lé èsì ìdánwò wọn

Awọn akẹkọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Miliọnu kan abọ awọn akẹkọọ to pegede ninu idanwo naa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Wo nkan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí akẹ́kọ̀ọ́ tí àjọ WAEC gbẹ́sẹ̀ lé èsì ìdánwò wọn.

Ajọ to n mojuto idanwo asejade nileewe girama, WAEC gbẹsẹ le awọn esi idanwo àwọn akẹkọọ kan.

Ajọ to n ṣeto idanwo WAEC sọ pe esi idanwo akẹkọọ to le ni ẹgbẹrun lọna igba (215, 149) to ṣe idanwo ọdun 2020, ni oun gbẹsẹ le.

Ìdá 13.98% awọn to ṣe idanwo ni ọrọ yii kan.

Patrick Areghan to jẹ oludari ajọ naa ni Naijiria sọ ninu atẹjade kan pe igbesẹ naa waye nitori pe awọn fura pe awọn akẹkọọ náà ṣe mago-mago lasiko idanwo.

Agbenusọ fun ajọ WAEC, Demianus Ojieogu sọ fun BBC Pidgin pe awọn akẹkọọ ti ọrọ kan ko ti i le ṣe nkankan, nitori pe awọn ṣi n ṣe iwadii lati mọ boya lootọ ni wọn ṣe mago-mago lasiko idanwo.

Igbimọ oluwadii ni yoo sọ boya wọn o gbẹsẹ le esi akẹkọọ to ṣe mago-mago, tabi wọn yoo gbe esi awọn ti ko jẹbi jade.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa lórí BBC Yorùbá: Mọ̀ síi nípa ẹ̀kún ìyàwó níbí

Ẹni ti wọn ba gbẹsẹ le esi idanwo rẹ yoo tun IDANWO WAEC ṣe ni, sugbọn lẹyin ọdun meji.

Ọdun meji ni ajọ WAEC yoo fi fi ofin de wọn, gẹgẹ bi ibawi fun ṣíṣe mago-mago lasiko idanwo.

Yatọ si eyi, akẹkọọ 81,718 ni wọn ko ti i gbe esi idanwo wọn jade, nitori pe àṣìṣe wa lori rẹ. Ni kete ti ajọ naa ba ti pari atunse lori wọn, ni awọn akẹkọọ naa yoo ni anfaani si i.

Akẹkọọ n ṣe'danwo

Oríṣun àwòrán, @Omojuwa

Ajọ WAEC gbé èsì ìdánwò ọdun 2020 jáde

Ajọ WAEC to n ṣe akoso idanwo ile iwe girama ni apa iwọ oorun ilẹ Afirika ti gbe esi idanwo awọn akẹkọọ oniwe mẹwaa ọdun 2020 yii jade.

Oludari ofiisi ajọ naa ni Naijiria, Ọgbẹni Patrick Areghan lo fi ikede naa soju opo Twitter ajọ WAEC.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ninu awọn akẹkọọ 1,549,740 to ṣe idanwo naa, awọn 1,338, 348 lo pegede ninu iṣẹ marun un ninu mẹsan an ti wọn ṣe eyi to jẹ ida mẹrindinlaadọrun un ninu ida ọgọrun un to ṣe idanwo naa.

Ṣugbọn awọn akẹkọọ 1,003, 668 lo pegede ninu iṣẹ marun un to fi mọ ede Gẹẹsi(English Language) ati Iṣiro(Mathematics).

Ajọ WAEC ni esi idanwo naa ko ba ti jade tẹlẹ ṣugbọn rogbodiyan to ṣẹlẹ lẹyin ifẹhonuhan #EndSARS lo ṣe idiwọ.

Ajọ WAEC ni awọn ọfiisi ohun kan naa faragba ninu iṣẹlẹ lasiko rogbodiyan #EndSARS to ṣẹlẹ lorilẹede Naijiria.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Laarin ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2020 lawọn akẹkọọ ṣe idanwo naa eleyi to yẹ ki esi rẹ jade lọjọ ketadinlọgbọn, oṣu kẹwaa tii ṣe ọjọ marundinlaadọta ti wọn ṣe idanwo ọhun.

Àkọlé fídíò, EndSars, EndSwat Protest: Òbí agbábọ̀ọ̀lù Gbenga Tiamiyu Kaka àtàwọn míì tí ọlapàá pa sọ̀r

Bayii ni o ṣe le wo esi idanwo WAEC rẹ

  • Lọ si oju itakun ayelujara www.waecdirect.com
  • Tẹ nọmba idanwo rẹ ati ''pin'' ti ajọ WAEC fun ọ ki o to ṣe idanwo sibẹ
  • Fi ọdun idanwo sibẹ ati irufẹ idanwo ti o ṣe sibẹ bo ya GCE tabi SSCE.
  • Duro ki esi naa fi jade

Alukoro ajọ WAEC, Demianus Ojijeogu tun ṣalaye pe awọn akẹkọọ le ri esi idanwo wọn ninu atẹjiṣẹ ori foonu.

Bayii ni o ṣe le wo esi idanwo rẹ lori foonu

Awọn nọmba kan wa ti o nilo lati fi wo esi idanwo rẹ.

Ohun ti wa fi ranṣẹ si ''32327'' ni ''WAEC*ExamNo*PIN*ExamYear.''

Àkọlé fídíò, John Amanam: Ìfẹ́ tí mo ní sí àbúrò mi ló sọ mi dí ẹni tó ń ṣe 'Prosthetic' báyìí