Akinwumi Isola: Wo ohun tí Abeni fi ojú ọkọ rẹ rí tórí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nínú ìwé "Nitori Owo"

Àkọlé fídíò, Láàrín ìṣẹ́jú díẹ̀, ẹ ka ìwé Akinwumi Ishola, "Nítorí Owó" lórí Akomolede Yoruba

Awọn iwe Ọjọgbọn Akinwumi Ishola jẹ ibi ikẹkọọ fun ọpọlọpọ gẹgẹ bo ṣe jẹ agba ọjẹ onkọwe lede Yoruba.

Lori eto Akomolede ati Asa lori BBC Yoruba fun tọsẹ yii, ohun ta gbeyẹwo ni kika latinu iwe Akinwumi Iṣola ti akọle rẹ n jẹ "Nitori Owo".

Akori ọrọ gangan ti atupalẹ iwe yii wa labẹ rẹ ni Litiresọ Apilẹkọ.

Idile Adio ni afojusun iwe yii. Bi wọn ṣe n ṣe daadaa tẹlẹ ti gbogbo nkan n dan fun wọn ṣugbọn ti ọrọ wa di olowe pe "O wa di akọ aja to n gbo lasan ninu ile". Loju iyawo Adio, o di pe "agba ti ko lowo lọwọ, ti n fọn ni kaa, akọ aja lasan to n gbo ni".

Adio di ẹni iwọlẹ loju Abẹni, iyawo rẹ ti ko si ọrọ lẹnu rẹ mọ ninu ile.

Ohun ti iyawo ṣe pẹlu ọmọ wọn Oyeladun, o ṣi ni lẹnu silẹ koda iroyin rẹ ko ṣee foju ba ni ninu fidio to wa loke yii.