Ikire Tussle: Ìdí tí àwọn ọ̀dọ́ Ikire fí ni dandan ọba gbọdọ̀ kúrò lórí àpèrè

Oríṣun àwòrán, daily trust
Iroyin to n tẹ BBC Yoruba lọwọ ni pe awọn ọdọ kan nilu Ikire nipinlẹ Osun, gbiyanju lati ji ọba ilu naa gbe.
Iṣẹlẹ naa, to waye lọsan ọjọ Aje, lo n kọ ọpọ eeyan lominu.
Iroyin naa salaye pe awọn ọdọ ilu Ikire lo anfaani rogbodiyan lori iwọde ENDSARS to n lọ lọwọ lati ji oriade naa, Akire tilu Ikire, ọba Falabi gbe lọ.

Oríṣun àwòrán, Daily trust
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun BBC Yoruba, agbenusọ fun Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola ni ọpẹlọpẹ awọn araalu kan to raga bo ọba ọhun, ti ko jẹ káwọn ọdọ ji gbe lọ.
Opalola ni awọn ko tii ri ẹnikẹni mu lori iṣẹlẹ naa, amọ iwadii si n tẹsiwaju.
Iṣẹlẹ naa lo da jìnnìjìnnì bo awọn araalu naa, to si tun da omi alaafia ilu ru. Iroyin kan salaye pe, ó ti to ọdun mẹtadunlogoji ti laasigbo ti n waye lori ọrọ ọba ilu naa.
Ẹsun tàwọn ọdọ naa fi n kan ọba Falabi ni pe, o yi idajọ ile ẹjọ to ga julọ lorilẹ-ede yii po, eyi to wọgile ilana to yan ọba ọhun sipo lọdun 1993.Lọdun 2014 si ni ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa gbe idajọ kalẹ lati ẹnu adajọ agba tẹlẹ ni Naijiria, Walter Onnoghen pe ilana to gbe ọba Falabi de ipo bii Akire, ku díẹ̀ kaato.
Bàbá Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́, Elérúwà àti àwọn Ọba Ilẹ̀ Yorùbá míràn tí wọ́n rọ̀ lóyèỌba Falabi si lo gba ile ẹjọ giga lọ lati beere fun ìtumọ̀ idajọ ile ẹjọ to ga julọ naa, eyi to mu ko nira fun gomina ana nipinlẹ Osun, Rauf Aregbesola lati yọ nipo












