ENDSARS Protest Update: Iyabo Ojo ní ìpolongo tàbí ìbò dídì fáwọn olóṣèlú APC, PDP di eewọ f'óun

Oríṣun àwòrán, Instagram/iyaboojofespris
Awọn oniruuru gbajumọ osere tiata atawọn ilumọọka lawujọ, ni wọn ti n ṣe ipinnu ọtun tori rogbodiyan to waye lasiko iwọde ENDSARS.Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni gbajumọ osere tiata kan lobinrin, Ronke Ojo, ti ọpọ mọ si Ronke Oshodi Oke, n kabamọ pẹlu omije loju opo Instagram rẹ. Ronke lo n fi ika hanu pe, oun polongo ibo fawọn oloselu Naijiria lasiko ibo gbogbo gboo to kọja.Nibayii, ilumọọka osere tiata mii, Iyabo Ojo, naa tun ti bọ soju opo ayelujara rẹ pẹlu ileri tuntun.

Oríṣun àwòrán, Screenshot/iyabo ojo
Iyabo, loju opo Twitter ati Instagram rẹ lo n leri leka, to si n tọ ilẹ la pe, oun ko ni polongo ibo fun oloselu kankan ni Naijiria mọ, to ba jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu APC tabi PDP.
Iyabo ni "Emi Alice Iyabo Ojo, ko ni ṣe atilẹyin, polongo tabi dibo fun ọmọ ẹgbẹ oselu APC tabi PDP mọ laelae laye mí."Gbajumọ osere tiata naa fikun pe "Koda, iru oloselu bẹẹ ko ba a jẹ mọlẹbi tabi ọrẹ mi tori a nilo agbekalẹ orilẹede Nigeria tuntun." Iyabo salaye pe a nilo lati dẹkun didi ibo fun irufẹ awọn oloselu kan naa ninu ẹgbẹ APC tabi PDP, ka le fopin si iṣejọba buburu.Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko tí kéde ìlànà ìséde tuntun fún ará ìlú
A o ranti pe ọpọ awọn gbajumọ osere tiata atawọn ilumọọka ọmọ Naijiria miran, ni wọn ṣe ìpolongo ibo fawọn oloselu lọdun 2015 pẹlu orin ati ijo lati ipinlẹ kan si omiran ati nijọba apapọ pẹlu.












