Titus Badejo Ejanla Death: Ẹ wo bí àwọn agbébọn ṣe gbẹ̀mí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, Titus Badejo Ejanla ní ìlú Ibadan

Oríṣun àwòrán, Instagram
Gbajugbaja sọrọsọrọ nipinlẹ Ọyọ paapaa ni ilu Ibadan, Titus Badejo ti awọn eniyan mọ si Ejanla ni awọn agbẹbọn ṣekọlu si ni agbegbe Oluyole ni ilu Ibadan.
Badejo to jẹ sọrọsọrọ aladani to ba ileeṣẹ redio Space ati Naija FM ṣiṣẹ ni ilu Ibadan naa ni o ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ogoji ọdun rẹ, ki awọn agbebọn naa to da ẹmi rẹ legbodo.
Iroyin i ile igbafẹ 407 Club ni Oluyole Estate, Ibadan to ti n ṣiṣẹ DJ ni wọn ti yinbọn pa a ni asalẹ Ọjọ Satide, Ọjọ Kọkandinlogun, Oṣu Kẹfa, ọdun 2021.
Ẹjanla ni wọn sọ wi pe lẹyin iṣẹ ni awọn agbebọn kan lori ọkada ṣigun bo wọn si sọ fun gbogbo wọn lati doju bolẹ, lẹyin naa ni wọn da ibọn bo oun nikan ti wọn ko si mu owo tabi nkankan lara rẹ.
- Ẹ ṣeun, ẹ kú àdúrótì mi! Ẹ wo ọ̀rọ̀ tí Tope Alabi padà sọ nípa awuyewuye tó wáyé lóri orin Oniduro Mi
- Dino Melaye fi ọkọ Rolls Royce bùgá lórí Instagram, ni oníṣòwò ọkọ́ bá ní kó wá san gbèsè owó ọkọ̀ tó jẹ́ òun
- Ọwọ́ tẹ ọmọdébìnrín tó jí ara rẹ̀ gbẹ́ nítorí ìyá rẹ̀ ní kó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ láti ṣe dókítà
- Women Life saver car: Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yì ti gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ aláboyún àtọmọ ọwọ́ lá ní Jigawa
Ijọba gbọdọ ṣewadii awọn to ṣekupa Titus Badejo Ejanla -FIBAN Ibadan
Ọkan lara awọn agba ẹgbẹ awọn sọrọsọrọ nipinlẹ Ọyọ, Seun Awodele ti ni ijọba ipinlẹ Ọyọ gbọdọ ṣe iwadii finifini lori iku to pa Titus Badejo Ejanla ni ilu Ibadan.
Lasiko to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC News Yoruba lo ni ibanujẹ ọkan ni iroyin iku ojiji naa jẹ fun gbogbo awọn sọrọ sọrọ lorilẹede Naijiria, paapaa ni ipinlẹ Ọyọ ati ni ilu Ibadan.
Ninu ọrọ rẹ, Awodele ni titi ilẹ afisu ni awọn yoo ma logun lori redio kaakiri ilu Ibadan nipa iku oloogbe naa ati ọna abayọ si eto aabo to dẹnukọlẹ kaakiri orilẹede Naijiria.
''O ṣeni laanu pe eto aabo lorilẹede Naijiria ti dẹnukọlẹ patapata, ti ko si si eto aabo kankan fun awọn eniyan paapaa awọn sọrọsọrọ to jẹ wi pe ọrọ ilu lo jẹ awọn logun.''
''Ilu ko rọgbọ lọwọ bayii, i'ṣekupani lọtun ati losi bẹẹ si ni ẹnu iṣẹ ni arakunrin Ejanla wa ti awọn agbebọn si lo pa a.''
- Timothy Obadare ìránṣẹ́ Ọlọ́run to fọ́ lójú ìta ṣùgbọ́n tó ríran jù ọ́pọ́ wòlíì lọ
- Mo kú tì, nítorí pé àsìkò mi kòì tó láti padà sí ọ̀run- Kunle Ologundudu
- O kú ogun àjàyé Tope Alabi, odò Jodani lo ṣẹ̀ṣẹ̀ là kọjà yìí o! Àmọ́ rántí pé ... - Mike Bamiloye
- Ṣé lóòtọ́ ni ilẹ̀ America ti bẹ̀rẹ̀ 'visa lottery padà fún àwọn ọmọ Naijiria? Wo àlàyé níbí
- Rahmon ń múra láti lọ rí ìyàwó àti ìbèjì tó bí ní US ni wọ́n bá pa á níbi ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ ní Iwo road
''Lọwọlọwọ bayii, a ti n ba awọn ọga ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ sọrọ lati parapọ pe ipade gbogboogbo pẹlu gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde lori eto aabo fun awọn oniroyin ati agbohunsafẹfẹ.''
''Wọn gbọdọ ṣewadii bi iṣẹlẹ naa ṣe waye nitori oṣiṣẹ aladani ni oloogbe naa to si le e ṣiṣẹ ni ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ to ba wu u.''
Alaga FIBAN ni: ''Awọn sọrọsọrọ nilo eto aabo nitori awọn ni olulaja laarin awọn araalu ati ijọba nitori naa ni iwadii finifini gbọdọ waye lori iṣẹlẹ naa.''
Bakan naa ni ẹgbẹ FIBAN fikun pe awọn ti parapọ lati lọ si ile oloogbe naa lati sabẹwọ si awọn ẹbi oloogbe naa.
Ọmọ mi kii ṣe ẹlẹgbẹ okunkun, ejo lọwọ ninu lori iku rẹ - Iya Titus Badejo Ejanla
Amọ iroyin ni iya oloogbe naa ti ke gbajare sita wi pe kii ṣe oju lasan ni iku ọmọ oun.
Iya oloogbe Ejanla ni iku ti agbebọn fi pa ọmọ oun nilu Ibadan lọwọ ninu.

Oríṣun àwòrán, Instagram
Iya oloogbe naa ni ọmọ ohun kii ṣe ẹlẹgbẹ okunkun nitori naa oun ko mọ idi ti awọn agbegbọn yoo ṣe lọ yinbọn pa a.
O kesi awọn ileeṣẹ agbofinro ati Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lati maṣe jẹ ki iku ọmọ oun lọ lori asan.
- Ìjọba, ẹ bá mi wá ẹni tó pa ọmọ mi jáde - Ẹ̀bí olóògbé gbarata
- Sunday Igboho ní December lòpin ìrìn àrè, Yorùbá ń lọ kúrò ní Nàíjíríà
- Mọ̀ si i nípa ìtàn eégún Gelede àti pàtàkì eégún náà sí àwọn obìnrin nílẹ̀ Yoruba
- Mo kú tì, nítorí pé àsìkò mi kòì tó láti padà sí ọ̀run- Kunle Ologundudu
- Ṣé lóòtọ́ ni ilẹ̀ America ti bẹ̀rẹ̀ 'visa lottery padà fún àwọn ọmọ Naijiria? Wo àlàyé níbí
- Rahmon ń múra láti lọ rí ìyàwó àti ìbèjì tó bí ní US ni wọ́n bá pa á níbi ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ ní Iwo road















