Gelede festival: Mọ̀ si i nípa ìtàn eégún Gelede àti pàtàkì eégún náà sí àwọn abiyamọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Olumide Owaduge
- Role, BBC Yoruba, Lagos
Ọpọ awọn ọmọ ilẹ Yoruba aye ode oni lo maa n gbọ ti wọn maa n sọ pe eeyan n jo Gelede, ṣugbọn ọpọ ni ko mọ ohun ti Gelede tumọ si.
Ninu itan ati iṣedalẹ Yoruba, eegun kan lo n jẹ Gelede.
Bo tilẹ jẹ pe Gelede yii ko pin si Naijiria nikan, o tan de awọn orilẹ-ede mii bi Benin ati Togo ti ọpọ ọmọ Yoruba tẹdo si.
Gelede jẹ eegun, wọn a si ma lo eegun naa layajọ ọdun Gelede lati da awọn eeyan laraya, lati kọ wọn lẹkọọ, ati lati mu ki aṣa ilẹ Yoruba gbilẹ sii.
Wọn maa n fi Gelede ṣe ayẹsi awọn obinrin ati iya nilẹ Yoruba, lai yọ awọn oriṣa to jẹ obinri silẹ.
O tun maa n ṣapẹre irufẹ agbara ti awọn obinrin ni nilẹ Yoruba.
Orisun Gelede
Gẹgẹ bii awọn to mọ nipa itan aṣa ilẹ Yoruba ṣe sọ, orisun Gelede so mọ ilu Oyo, Ketu ati Ilobi.
Ninu itan naa, eegun Gelede bẹrẹ pẹlu ọba kan to ti n mura lati waja, ti awọn ọmọkunrin rẹ si n lakaka lati gori itẹ rẹ.
- Ilé aṣòfin Naijiria buwọ́lu òfin tí yóò fi òpin sí ìdẹ́yẹsí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ní ìwé ẹ̀rí HND
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàwárí ibi tí wọ́n ti ń rọ ìbọn AK-47 lábẹ́lé ní Jos
- Nàìjíríà ti di orílẹ̀èdè tó ń ṣàn fún ìbànújẹ́ àti ìpayínkeke- Obasanjo
- Àjọ NYSC kò gbèrò rírán àwọn àgùnbánirọ̀ lọ sójú ogun- Àjọ NYSC
- Makinde ṣàfikún owó oṣù àwọn àgùnbánirọ̀ ìpinlẹ Ọyọ láti ẹgbẹ̀rún márùn ún sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún náírà
Ọkan lara awọn ọmọkunrin naa, nigba to ti ri pe o ṣeṣe ki oye naa bọ lọwọ oun, lo ba daa bi ọgbọn lati gbẹmi arakunrin rẹ.
Ṣugbọn nigba ti arakunrin rẹ naa gbọ pe ibatan oun n gbimọ lati gbẹmi oun lo ba da bi ọgbọn to si ṣe iboju kan lati parada ki arakunrin rẹ naa ma baa da mọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi itan ọhun ṣe sọ, iboju naa ni wọn n lo fun eegun Gelede laye ode oni.
Ẹsẹ ifa kan tun tan imọlẹ si orisun Gelede, iyẹn bo ṣe tan mọ yemoja.
Lasiko kan ti Yemoja ko tete ri ọmọ bi, o gba ile alawo lọ, alawo naa sọ fun pe ko gbe ẹbọ lọ si orita, ko si maa jo pẹlu ere kekere kan lori rẹ ati ẹgba ni ẹsẹ rẹ.
Lẹyin to pari irubọ naa tan ni ọmọ ba de, o bi akọbi to jẹ ọkunrin to pe ni Efe, o si tun bi obinrin pẹlu, ti orukẹ rẹ n jẹ Gelede.
Ṣugbọn o ṣeni laanu pe, obinri ti Yemoja bi yii naa ko tete ri ọmọ bi lẹyin igbeyawo rẹ, loun naa ba tun gba ile alawo lọ, alawo naa si sọ fun pe ko gbe ẹbọ, irufẹ eyii ti iya rẹ kọkọ gbe ṣaaju.
Lẹyin to gbe ẹbọ naa tan, iyẹn pẹlu ere kekere kan lori rẹ ati ẹgba ni ẹsẹ rẹ to si n jo ni oun naa to bi ọmọ. Etutu ti Gelede ṣe yii lo bi ijo Gelede.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹwẹ, onimọ nipa Gelede kan, to tun jẹ olori Gelede niluu Eko, oloye Adio Erinfolami sọ fun awọn akọrọyin nigba ọdun Gelede lọdun 2017 pe, ẹmi to wa nidii gelede ni "iya nla."
O ṣalaye pe oriṣa naa jẹ onisuuru, o si maa n sọ awọn agan di abiyamọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ "Idi ree ti awọn obinrin ti ko ba bimọ ṣe maa n fori balẹ fun Gelede ki wọn le ri ọmọ gbe jo.
Awo Gelede
Ọkunri ati obinrin lo n ṣe awo Gelede bo tilẹ jẹ pe ọkunrin lo maa n wa labẹ ẹku, ṣugbọn awọn obinrin lo ṣaba maa n pọ ju ninu ẹgbẹ naa.
Awọn kan gbagbọ pe obinrin pọ ninu ẹgbẹ naa nitori ki wọn le tete ri ọmọ bi.
Olori awo gelede ni wọn n pe "Iyalaṣẹ," oun si lo maa n jẹ alarena laarin oriṣa naa ati awọn eeyan ilu.
Iyalase yii nikan lo ni aṣẹ lati wọ inu ile ti wọn ti n ṣe oro Gelede.
Babalaṣẹ, to jẹ ekeji Iyalaṣẹ ni o maa n ṣakoso gbogbo nnkan atawọn oun elo ti wọn fi n gbe eegun Gelede ọhun.
Abọrẹ lo wa nidii gbogbo ohun to jọ mọ irubọ ati etutu ninu awo Gelede.
Elefe lo n mojuto iboju ti wọn fi n gbeegun Gelede ọhun.
Arugi ati Onilu naa wa lara awọn to wa ninu awo Gelede pẹlu, gbogbo awọn eeyan wọnyii lo ni ojusẹ ti wọn n ṣe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọdun Gelede
Ọdọdun ni wọn ma n ṣe ọdun Gelede nilẹ Yoruba, ṣugbvọn kii ṣe gbogbo awọn ipinlẹ ti wọn ti sọ Yoruba ni wọn ti n ṣe ọdun naa.
Eredi ti wọn fi ṣe ọdun naa ni ki ki ilu le tuba, ko si tuṣẹ, ki ojo rọ lasiko to yẹ ki awọn awọn agbgẹ le ri ti aje ṣe ki iyan ma baa ja laarin ilu.
Wọn maan n lo oriṣiriṣi awọn iboju, pẹlu orin ati ilu ni wọn si maa n ṣe ọdun naa.
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa bí 'twitter' tíjọba dá dúró ní Nàijíríà yóò ṣe kan ọ
- 'Mo bá òkú Blessing tí wọ́n so ọwọ́ ẹ̀ sẹ́yìn pẹ̀lú ìwé pélébé tí wọ́n kọ pé ...'
- Wo ìdí tí àgbẹ̀ kan, Muhammad fi da májèlé sínú kànga mẹ́sàn án tí àwọn èèyàn ń mu
- Ìpínlẹ̀ Èkìtì ṣetán láti gbà àlejò ìwọ́de ìlànà Ọmọ Odua
- Kò sí ìjà kankan láàrín èmi àti Saheed Osupa - Muri Thunder
Lara awọn ẹku ti wọn fi n gbe egun Gelede ni ti iya to n fun ọmọ lọmu, eyii to n tumọ si ibaṣepọ laarin iya ati ọmọ ikoko.
Ohun kan gboogi to ṣe pataki ninu odun naa ni lati ṣe ayẹsi awọn obinrin, paapaa julọ awọn abiyamọ.
















