AK-47 production factory: Àwọn afurasí méjì tó ń rọ ìbọn AK-47 lábẹ́lé kó sọ́wọ́ ọlọ́pàá ní Jos

AK-47

Oríṣun àwòrán, @CharityTerfa

Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Plateau ti ṣawari ileeṣẹ kan ti wọn ti n rọ ibọn AK-47 ni ijọba ibilẹ Guusu Jos, ọwọ wọn si ti tẹ awọn afurasi meji.

Ilẹeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa lo fi ọrọ naa lede lasiko ti wọn fi oju awọn afurasi han fun awọn akọroyin.

Wọn tun ṣafihan awọn afurasi mọ́kàndínláàdọ́rin miran ti wọn fẹsun kan pe wọn jẹ ajinigbe, janduku, adigunjale, awọn to n rọ ibọn lọna aitọ atawọn to n ṣe ayederu nọmba ọkọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ọhun tun ni awọn afurasi to ṣekupa Christopher Dega, to jẹ olubamọran si gomina Samuel Oton ti ipinlẹ Benue lori eto abo tọpasẹ oloogbe naa lọ sile ounjẹ kan ni Jos ki wọn to gbẹmi rẹ.

Wọn ni orukọ awọn afurasi to n rọ ibọn naa ni Joe Michael ati Illiya Bulus.

AK-47

Oríṣun àwòrán, @macmaduson

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Frank Mba sọ fun awọn akọroyin pe awọn oṣiṣẹ ẹka ileeṣẹ naa to n fimu finlẹ lo mu awọn ọdaran ọhun kaakiri ipinlẹ Plateau

Mba ṣalaye pe o jẹ ohun to n ba awọn ninu jẹ pe ibọn AK-47 ti wọn pilẹ rọ ni Naijiria ni ọpọ awọn ọdarann n lo lati fi ṣọṣẹ julọ lasiko yii.

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....

O tẹsiwaju pe ko fẹ ẹ si iyatọ kankan laarin irufẹ ibọn AK-47 ti wọn n ṣe ni Jos ati eyii ti wọn n ṣe nilẹ Yuroopu.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, wọn gba ogun ibọn lọwọ awọn afurasi naa lẹyin ti wọn ti n tọpinpin wọn fun ọjọ pipẹ.

O ni "Ti ẹ ba wo awọn ibọn ti wọn n rọ labẹle yii daadaa, ko si iyatọ kankan lara rẹ atawọn eyii ti wọn n ko wọle lati oke okun, ayafi ti ẹni to n wo ba ni imọ daadaa nipa ibọn ati ohun ija oloro."

"A oo maa tọpinpin awọn to wa nidii ileeṣẹ ti wọn ti rọ ibọn naa, a oo si maa ṣiṣẹ pẹlu ajọṣepọ awọn ileeṣe agbofinro miran lati tuṣu de isalẹ ikoko bi ọrọ naa ṣe jẹ."

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

Ẹwẹ, ọkan lara awọn to n rọ ibọn naa, Michael, to jẹ akẹkọọ jade nilẹ ẹkọ imọ ẹrọ to wa ni Jos ṣalaye pe oun ti rọ ibọn bii ọgọ́sàn án lati igba ti oun ti bẹrẹ iṣẹ naa, oun si maa n ta ọkọọkan ibọn ọhun ni ẹgbẹrun lọna ọgọrin naira.