Buhai 2021 Babacar Ndiaye: Aàrẹ Muhammadu Buhari gba àmì ẹ̀yẹ Adarí tó dára jùlọ

Oríṣun àwòrán, @Muhammadu Buhari
Iroyin tuntun to tun gbode kan ni pe lọjọ kejiidinlọgbọn oṣu karun ọdun 2021, wọn darukọ Muhammadu Buhari to jẹ aarẹ orilẹede to pọju lọ nilẹ Afirika gẹgẹ bi ọkan lara awọn to jawe olubori ti yoo si gba ami ayẹ 2021 Great Builder Super Prize for Trophée Babacar Ndiaye.
Oun ni yoo gba eku ida ipo yii lọwọ Abdel Fattah al-Sissi ti orilẹede Egypt to ipo naa lọdun 2020.
Gẹgẹ bo ṣe jade ninu atẹjade Banki idagbasoke ilẹ Afirika, Buhari ni wọn kede gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori nibi eto ifilọlẹ Africa Road Builders to waye ni Cairo, Egypt lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹta.
Ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹfa yii ni aarẹ Buhari yoo tẹwọ gba ife ẹyẹ ami ẹyẹ naa nigba ti wọn ba n ṣe ifilọlẹ ipade ọlọdọọdun ti Banki idagbasoke ilẹ Afirika.
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo
- Bíi ti UK, USA, Germany, France lẹ ó lè ṣe ẹ̀sìn tó bá wù yín yàlàyòlò ní orílẹ̀èdè Yorùbá Nation - Igboho
- Wo bí àwọn arúgbó ṣe le jẹ́ ìgbádùn ètò tí Buhari fi lọ́lẹ̀ fún wọn
- Ohun tí wọ́n ní kí òkóbó Buhari bọ̀ lórí ọ̀rọ̀ àbò ni kó bọ̀, dípò dídúnmọ̀huru mọ́ aráàlú- PDP
- Èrò Akeredolu ni yẹ́n, àwa aṣòfin á ṣẹ̀sẹ̀ jókòó láti yọ tàǹda kúrò nínú ìrẹsí nígba tó bá ya- Senetọ Ajibola
Ni ti Fattah al-Sissi, o gba ami ẹyẹ naa fun bi o ṣe n ṣe idari rẹ ati akitiyan rẹ lati rii pe abo to daju wa loju popo ati eto ilera fun awọn araalu.
Kí ni amuyẹ ti wọn ri lara Aarẹ Buhari?

Oríṣun àwòrán, @Muhammadu Buhari
Igbimọ to n yan ẹni ti yoo jawe olubori ri akitiyan orilẹede Naijiria lati mu agbega ba aabo loju popo ati fun awọn araalu.
Bakan naa wọn tu kan sara si akitiyan Naijiria lati ni abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ati eto igbega fun awọn iṣẹ akanṣe fun irina paapaa ni ẹka irina oju irin.
Awọn to ṣe agbekalẹ ami ẹyẹ Babacar Ndiaye Africa Road Builders Award ni"Acturoutes, ileeṣẹ to n gba iroyin nipa awọn nkan amayerọrun ati awọn opopona ni Afirika pẹlu ajọṣepọ Media for Infrastructure and Finance in Africa (MIFA) to jẹ akojọpọ awọn oniṣẹ iroyin Afirika to n royin nipa amayerọrun bii oju popo ni.
Aarẹ Banki idagbasoke ilẹ Afirika lo maa n ṣe onigbọwọ eto ami ẹyẹ naa.
Igbimọ to n yan ajawe olubori jẹ awọn aṣoju akoroyin marun lati ẹkun maraarun ilẹ Afirika ti wọn si n lo awọn iroyin atawọn akọṣẹmọṣẹ lori ọrọ idagbasoke ọọrundunrun ni wọn n lo lati wo ohun amuyẹ.
Ami ẹyẹ naa ni wọn n ṣe ni iranti Babacar Ndiaye to jẹ aarẹ Banki idagbasoke Afirika (AFDB) laarin ọdun 1985 si 1995.
- Agbébọn pa ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nígbàkan rí, Christopher Deja
- Lẹ́kṣọ́rà fásitì FUOYE kan tún kó sí gbaga ẹ̀sùn aṣemáṣe pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́
- Ènìyàn 28 kú lẹ́yìn ààrùn Coronaviris láàrín wákàtí 24 ní Nàìjíríà
- Ọwọ́ ikọ̀ Amọtẹkun ba Mutiu Abdul-Rasheed, afurasí tó ń ta ẹ̀yà ara èèyàn ní Ibadan
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ ìjọba, dẹndẹ ìyà yóò jẹ orí yín bí Nàìjíríà bá pínyà pẹ́rẹ́, toríi Yoruba Nation! - Oluwo

















