Man selling body parts, Ibadan: Ọwọ́ ikọ̀ Amọtẹkun ba Mutiu Abdul-Rasheed, afurasí tó ń ta ẹ̀yà ara èèyàn ní Ibadan

Amotekun

Ọwọ ikọ Amọtẹkun ba afurasi to n ta ẹya ara eeyan n'Ibadan

Awọn oṣiṣẹ ikọ ẹṣọ aabo Amọtẹkun ti nawọ gan ẹni afurasi kan, Mutiu Abdul-Rasheed ti wọn fi ẹsun kan pe o n ta ẹya ara eeyan fun etutu ọla.

Ẹni ogoji ọdun naa ni kele ofin gbe ti wọn si ṣe afihan ọwọ tutu ati awọn ẹya ara mii ti wọn fi han gẹgẹ bi ẹri aridaju ti wọn ri gba lọwọ rẹ.

Abdul-Rasheed ti iroyin sọ pe o wa lati ilu Ẹdẹ n'ipinlẹ Ọṣun ṣe alaye wi pe oun wa ninu ẹgbẹ kan to n ṣe karakata ẹya ara eeyan for awọn onibara kan.

O ni ọna ti awọn n gba ṣiṣẹ ni lati maa wu oku awọn eeyan ti wọn mọ orukọ wọn ati orukọ awọn obi wọn ko to di pe wọn jade laye.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

Awọn alabasiṣẹpọ rẹ ti o ku ti na papa bora bayii.

Adari ikọ Amọtẹkun n'ipinlẹ Ọyọ, Ajagunfẹyinti Col Olayinka Olayanju ṣe alaye fun awọn oniroyin pe iṣẹ iwadi waye lori afurasi naa laarin oṣu melo kan ki ọwọ palaba rẹ to segi.

Àkọlé fídíò, Adebayo Murital David: Gbogbo iṣẹ́ tó ń múni là láyé wá láti ọpọlọ ni kìí ṣe agbára

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn ipe ti n wọle ati awọn igun wi pe ki awọn fi ẹni afurasi naa silẹ, botilẹ jẹ wi pe ko darukọ awọn eeyan to n gbe iru igbesẹ bẹẹ.

Ọlayanju ṣe alaye wi pe ikọ naa yoo fi afurasi naa le awọn ọlọpaa lọwọ fun alekun iṣẹ iwadii.

Àkọlé fídíò, 'Èmi ọmọ Ikorodu ọ̀ga, ọmọ aṣalẹ̀ jẹ́jẹ! Wo bí àwọn ọmọdé tó "tuush" yìí ṣe ń fi oríkì Yorùbá dábíra