Tegina Attack: A ti rí ọmọ ilé kéú 11 míì nínú àwón tí agbébọn jí gbé ní ìpínlẹ̀ Niger

Niger

Oríṣun àwòrán, NIGER STATE GOVERNMENT

Awọn alasẹ nipinlẹ Niger ti kede pe mọkanla lara awọn aadọjọ akẹkọọ ile keu kan ti awọn agbebọn gbe lọ nilu Tegina ti gba ominira.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun BBC pe awọn agbebọn naa tu diẹ lara wọn silẹ nitori pe ọjọ ori wọn kere.

Ati pe nise ni wọn yinbọn mọ awọn eeyan kan nile keu naa ki wọn o to ko awọn akẹkọọ lọ.

Sugbọn ṣa, ijọba sọ ninu atẹjade kan pe eeyan meji ni wọn yinbọn pa, ti ẹnikan si tun wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun nileewosan.

Bakan naa lo ni iwadii n lọ lọwọ lati mọ igbesẹ to yẹ lati gbe.

Ọga Agba ile keu sọ fun BBC pe akẹkọọ bi igba lo wa nibẹ nigba ti awọn agbebọn kọlu wọn ni irọlẹ ọjọ Aiku.

"A ko ti i le sọ iye akẹkọọ ti wọn gbe lọ, nitori pe awọn akẹkọọ kan gba oju ferese salọ.

Wọn yọnda awọn akẹkọọ mọkanla ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun marun-un si mẹfa."

O ṣalaye pe tọkunrin-tobinrin ni awọn akẹkọọ ti wọn gbe, to fi mọ diẹ lara awọn olukọ wọn.

Àkọlé fídíò, Adebayo Murital David: Gbogbo iṣẹ́ tó ń múni là láyé wá láti ọpọlọ ni kìí ṣe agbára

Oga agba ile keu naa ni ọkada ni awọn agbebọn naa gùn wọ ilu Tegina, pẹlu ìbọn lọwọ wọn, ti ko si si ẹnikẹni to le koju wọn laarin ìlú, nitori pe ṣe ni wọn n yinbọn léraléra.

Ijọba ipinlẹ Niger ti n wádìí lori bi awọn agbebọn ṣe tun ji àwọn akẹkọọ ile keu kan gbe.

Oga agba ile keu naa ṣalaye fun BBC pe akẹkọọ meji le ni ọọdunrun lo wa nile ẹkọ naa.

Àkọlé fídíò, Democracy day 2021: Kí ni Nàìjíríà ti jèrè lára gbogbo ààrẹ tó ti jẹ látọdún 1999?

Nǹkan bíi ọmọ ilé kéú 150 ni àwọn agbébọn jí gbé lọ ní Niger

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo sọ pe awọn agbebọn ti ji ogunlọgọ awọn akẹkọọ ile keu kan gbe lọ niluu Tegina, ni ipinlẹ Niger.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣalaye fun BBC pe awọn gende agbebọn naa tu diẹ lara awọn akẹkọọ ọhun silẹ nitori ọjọ ori wọn kere.

Ọsojumi koro na fi kun pe wọn yinbọn lu ẹni to n tọju awọn ọmọ naa lori ki wọn to ko wọn lọ.

Adari ilẹ ẹkọ ọhun ṣalaye fun BBC pe ko din ni igba akẹkọọ to wa nile ẹkọ Musulumi naa ki awọn agbebọn ọhun to ya bo wọn.

O ni "Ọpọ akẹkọọ lo wa nibẹ lasiko ti awọn agbebọn naa de, ṣugbọn awọn kan salọ lati oju ferese."

"Gẹgẹ bii oun ti a mọ, ko din ni ọgọrun akẹkọọ ti wọn ji gbe lọ ṣugbọn wọn fi awọn ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹrin si mejila silẹ nitori pe wọn kere."

O ṣalaye pe alupupu ni awọn agbebọn naa gbe lati ṣakọlu ọhun pẹlu oniruru ibọn lọwọ wọn ti wọn si n yinbọn soke bi ẹni to wa loju ogun.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun, DSP Wasiu Abiodun fi ṣowọ si awọn akọroyin, o ni iṣẹlẹ naa waye ni nnkanbii aago mẹta ọsan lọjọ Aiku.

Atẹjade naa ni "Ọgbọn ọjọ, oṣu Karun un, ọdun 2021 ni awọn agbebọn kan yabo ile keu Salihu Tanko to wa ni ilu Tegina, ni ijọba ibilẹ Rafi."

"Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le e sọ ni pato iye akẹkọọ ti wọn ji gbe lọ, awọn agbebọn pa ẹnikan."

Abiodun pari ọrọ rẹ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati doola awọn akẹkọọ ọhun.