Remi Tinubu: Èmi kò pe Arinola Oloko ní 'Thug' o, ìbéèrè ni mó bèèrè lọ́wọ́ ẹ- Remi Tinubu

Arinola ati Sẹnetọ Remi Tinubu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Arabinrin Remi Tinubu to jẹ aya oloye ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Tinubu lo ti sọrọ soke nipa iṣẹlẹ to ṣẹlẹ laarin oun ati Arabinrin Arinola Oloko.

Saaju ni won ti fi iroyin jade pe Remi Tinubu pe obinrin naa ni 'Thug'ninu fọnran fidio to jade naa.

Remi Tinubu to jẹ ẹni ọdun mọkandinlaadọta naa salaye pe: Ariwo ni mo gbọ, gẹgẹ bi ẹni ti ọrọ naa kan, mo sọ fun wọn pe ki wọn fi tọwọtọwọ se gbogbo eto naa nitori pe orukọ mi lo wa nibẹ gẹgẹ bii alaga.

O ni: 'Ọpọlọpọ iṣẹ ti mo ti ṣe sẹyin ni mo ti ri iranlọwọ obinrin gba lori wọn. bẹẹ mo maa n bọwọ pupọ fun obinrin nitori pe abo ni emi naa.

Remi Tinubu ni pe: Mi o si lara awọn agbatẹru eto iforukọsilẹ nibẹ rara, mo kan ba wọn da sii ni bi mo ṣe gbọ ariwo pe ki a yanju rẹ jẹjẹ.

Àkọlé fídíò, Simple tricks to identify designer shoes: Ṣe ìwọ lè wọ bàtà #2 mílíọ̀nú

Remi Tinubu ni pe: Idi pataki ti mo dẹ fi da si ọrọ naa ni pe obinrin ni Arinola to n pariwo nibẹ.

Mo dẹ beere ibeere lọwọ rẹ pe ṣe 'Thug' ni ẹ ni ti o fi n pariwo, ṣe 'thug' ni mo n ba sọrọ ni? Bẹẹ, o kere si mi lọjọ ori ki lo wa de ti maa fi pee ni 'thug'laiṣe pe mo mọ ọ ri?

Ibeere lasan ni mo beere o.

Àkọlé fídíò, Wọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi

Wọ́n gbà mi nímọ̀ràn láti dákẹ́ jẹ́ẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Sẹ́nétọ̀ Remi Tinubu tó pè mí ní tọ́ọ̀gì - Arinola Oloko

Arabinrin Arinola Oloko to ni iriri iṣẹlẹ gbọ́nmi sii omi oto pẹlu iyawo Asiwaju Tinubu to tun jẹ Sẹnetọ Oluremi Tinubu ti sọ nipa awọn imọran to n gba lẹyin iṣẹlẹ eyi ti gbogbo aye ri.

Niu ifrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu iowe iroyin The Punch Newspaper, Arinola ato jẹ oloṣelu ati onimọ nipa ẹkọ ohun to mu ki oun l fun eto atunyẹwo iwe ofin to waye ni Eko nibi to ti pade Remi Tinubu ni pe oun wa nibi eto idibo ọdun 2019 oun si ri gbogbo nkan to ṣẹlẹ lọna aitọ ni oun ṣe ba awọn akẹgbẹ oun lọ fun ipade itagbangba fun ayẹwo ofin ki awn baa le fi iwe lelẹ lati da si atunyẹwo naa.

Àkọlé fídíò, Democracy day 2021: Kí ni Nàìjíríà ti jèrè lára gbogbo ààrẹ tó ti jẹ látọdún 1999?

Nigba ti wọn bi i nipa ohun to ṣẹlẹ gangan laarin rẹ ati Sẹnetọ Remi Tinubu, o ni oun ko fibẹẹ fẹ ki iṣẹlẹ yii bo ọrọ ipenija to n koju orilẹede yii mọlẹ. "Iṣoro taa ni ni Naijiria kọja nkan to ṣẹlẹ l'Ọjọru lọ kii sii ṣe ọrọ to kan emi nikan nitorinaa, ẹ jẹ ka fii lẹ ko lọ bẹẹ".

"Yiyipo loju kan naa ti su awọn ọmọ Naijiria. "Ìṣẹ́ pọ̀ nilu, ko si aabo, o ti rẹ awọn eeyan wọn si n fẹ awọn oloṣelu ti yoo ṣoju wọn ni to si ṣetan lati sin wọn fun ayipada rere".

Arinola ni amọ "ka to gbogbo ilan bo ba ṣe tọ ati bo ṣe yẹ. O ni ẹ o le pe eeyan sibi eto kan kẹẹ ma ṣe eto bi gbogbo nkan yoo ṣe lọ ni wọọrọwọ.

"Bẹẹ ba le da a ṣe, ẹ gbe iṣẹ naa fun awọn alagbaṣe ti yoo ṣe bi ẹ ṣe fẹ tori iṣẹ ti wọn n gba owo fun ni".

O ni gbọngan ti wọn lo ko koju osuwọn fun iru ipade to ko eeyan lati Eko, Oyo ati Osun papọ ni ijoko ti ko ju eyi to lee gba eeyan igba ati abọ pere lọ.

Arinola Ola ni tori iru eero ti wọn nreti, ita gbangba TBS ni Eko ni wọn kọkọ polowo pe yoo ti waye ki wn to yi i pada nigba tọjọ ku diẹ.

Àkọlé fídíò, King Sunny Ade's son: Ohùn orin bàbá mi nìkan kọ ni l’Ọlọrun fún mi, ijó bíi kòkòrò ni ṣáá

Ki lo ṣe ni Marriot Hotel ti Sẹnetọ Tinubu ṣe sọ̀rọ̀ si i?

Arabinrin Arinola ni Sẹnetọ oun ni Oluremi Tinubu ti oun si bọwọ fun un gẹgẹ bii aṣoju awọn tori o ni oun ni ibọwọ pupọ fun aṣẹ ilu.

Ẹwẹ Arinola ṣalaye pe ṣe lawọn duro lori ila fun iforukọsilẹ afi to de ibi kan ti wọn ni wọn ti pa iwe de, ko saye fun iforukọsilẹ mọ.

"A ba ri awọn mii to n wọle, awọn sẹnetọ, gomina alaga ijọba ibilẹ, awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn mii naa to wa fi iwe lelẹ bii tiwa eyi ko si boju mu".

Àkọlé fídíò, India, Coronavirus: Ìtọ́jú aláìsàn ló jẹ́ mi lógún nítorí ètò ìlera wa mẹ́hẹ- Nọ́ọ̀sì Kama

Arinola si ni tinutinu oun lo fi wu oun lati wa nibi eto atunyẹwo naa, o si n ba awọn to wa lẹnu na sọrọ pe ki wọn ṣe bo ṣe tọ fun awa naa ki awọn wọle, loun ba gb ti Sẹnetọ Remi dede ni "ẹ pe obinrin to n sọrọ yẹn wa! wa sibi!".

'"Lai ṣe iye meji, mo dahun mo si lọ ba a. Mo sọ orukọ mi fun un ati pe ẹkun ti oun (Remi) n ṣoju ni mo ti wa, pe Sẹnetọ mi si ni ati pe a ti wa lori ila funigba pipẹ".

O ni bi oun ṣe gbiyanju lati ṣalaye gbogbo nkan "ti mo si ro o pe yoo sọ pe oh, eyi ko tọna ko si boju mu o. Amọ o sọ pe ki n gbẹnu dakẹ to si ni ki wọn pe awọn aṣọna ki wọn wa gbe tọọgi yii kuro".

O ni ibẹ loun naa ti wa sọ fun un pe "Ma, mi o kii n ṣe tọọgi, mi o jọ tọọgi, mi o huwa ipa, mi o si jọ ọdaran" Arinola ni awọn abuda tọgi loun ka silẹ yii.

Àkọlé fídíò, Mo máa ń déédé ṣubú lulẹ̀, tẹ́ẹ bá fi ọwọ kàn mí lásán, kódà lójú ọ̀nà márosẹ̀ - Fatimah

Lori ọrọ yii, ṣe lawọn ọmọ Naijiria to fi mọ idile tirẹ gangan n kan sara si iru igboya ti arabinrin yii ni lati sọ ẹdun ọkan rẹ fun Tinubu ti wọn si tun n wa ẹnu eebu le Remi Tinubu lori pe iwa yii kii ṣe igba akọkọ rẹ.

Pẹlu bi awọn eeyan ṣe n pariwo pe o yẹ ki Tinubu tọrọ aforiji lọwọ obinrin naa, Arinola ni tirẹ ni ni toun o, ẹ lee mu ẹṣin lọ odo ni, ẹ o le fi tipa mu u mu omi.

Tori naa, o ni bi Tinubu ba wo o pe ko nilo ki oun bẹbẹ, ko da nkankan. O ni ẹkọ ni fun gbogbo eeyan lati kọ iwa irẹlẹ ki o si loye pe boo ba tilẹ wa nipo agbara, o wa nibẹ lati sin awọn eeyan.

Titi di asiko yii, o ni Sẹnetọ Remi Tinubu ko kan si oun lati sọ ohunkohun nipa ọrọ naa. O ni o ti baba sọ pe oun ko ni tọrọ aforiji.

Nigbẹyingbẹyin, o ni iwe ti oun atawọn akẹgbẹ oun fẹ fi lelẹ gan nibi atunyẹwo ofin ọhun, awọn ko rii ṣe tori naa, oun ko tilẹ ro o lati lọ fun ti ọjọ keji.

"Koda, awọn eeyan pe mi lori foonu pe ki n ma wulẹ wa. Awọn kan ni ki n rọra dakẹ jẹẹ ki n simẹdọ lori ọrọ naa tawn kan si n sọ pe mi o ba ti fi igboya wa fi iwe temi lelẹ. Amọṣa mo ti fi ranṣẹ.

Ìgboro ayélujára ń gbóná lọ́wọ́lọ́wọ́ mọ́ Remi Tinubu lẹ́yìn tó pe obìnrin kan ní Tọ́ọ̀gì

Foo foo lori ayelujara n gbona lati ana gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe n wa eguna ọrọ le Sẹnetọ Remi Tinubu lori lẹyin to sọrọ abuku si arabinrin kan.

Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Eko ni fidio kan gba ori ayelujara kan nipa rẹ nibi to ti n pe arabinrin kan ni Janduku.

Gẹgẹ bi awọn iwe iroyin ṣe sọ ọ, iṣẹlẹ yii waye nibi eto ṣiṣe atunyẹwo iwe ofin eyi ti Eko ati awọn ipinlẹ agbegbe rẹ waye ni ile itura Mariot.

Tinubu lo ṣaju awọn Sẹnetọ toku nibi ayẹwo iwe ofin ọdun 1999 ọhun.

Iroyin sọ pe bi awọn araalu Eko ṣe to lati forukọ silẹ ṣaaju ki wọn to le wọle sinu gbọngan eto naa.

Amọ wọn ni lẹyin ti Gomina Sanwo-Olu ti gba ọna ẹyin wọle, ṣe ni wọn tilẹkun ti wọn si dawọ iforukọsilẹ duro.

Eyi lo mu ki awọn to wa lori ila maa fẹhonu wọn han pe wọn ko jẹ ki awọn wọle sibi eto naa.

Arinola ati Sẹnetọ Remi Tinubu

Lasiko ti wọn ni Remi Tinubu jade lati ibi ilẹkun ẹyin lati jẹ ki awọn aṣofin wọle ni iroyin ni obinrin kan to n fi aidunu han pe wọn o jẹ ki oun wọle ọrọ sita pe wọn n ṣe ojuuṣaaju.

Nigba ti Snetọ naa pe oun ati awọn meji mii ni iroyin sọ pe o pe obinrin naa ni janduku tọọgi fun bi o ṣe n fi ohun rara sọrọ.

Eyi lo fa rugudu laarin Tinubu ati obinrin naa to fi mọ awọn to n gbọ ti wọn n pariwo pe ko yẹ ko pe e ni tọọgi.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ṣe lawọn to n gbeja arabinrin yii ni afi dandan ki Sẹnetọ Remi Tinubu tọrọ aforiji lọwọ arabinrin ọhun.

Ni ti Tinubu gẹgẹ bi fidio ọhun ṣe ṣafihan rẹ , o tun tẹnu mọọ pe iwa arifin ni arabinrin naa hu ti iroyin si ni o sọ pe "mi o ni tuba fun ohun ti mo sọ, mo ri i mo si sọ ọ".

Àkọlé fídíò, 'Èmi ọmọ Ikorodu ọ̀ga, ọmọ aṣalẹ̀ jẹ́jẹ! Wo bí àwọn ọmọdé tó "tuush" yìí ṣe ń fi oríkì Yorùbá dábíra

Ṣe lawọn to wa nibẹ naa n pariwo pe ki "Sẹnetọ ma pe e ni tọọgi, o bẹbẹ kaa to dibo fun ẹ wọle ni".

Nigba ti awọn ọmọ Naijiria yoo fi da si ọrọ naa, ṣe ni wọn bọ sori Twitter ti wọn si n sọ oko ọrọ Sẹnetọ Tinubu pe ṣe ẹni to n gbero ati di iyawo aarẹ lo ti n huwa bayii.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4