UCL results: Wo ìdí tí ó fi rọrùn fún Chelsea láti bu ìfọ́jú lu Manchester City lẹ́ẹ̀mẹẹ̀ta léra wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yoruba bọ, wọn ni paa lẹẹkinni, paa lẹẹkeji, paa lẹẹkẹta. Bi oju ọhun ko ba fọ, yoo di bai bai.
Bayii ni Chelsea ṣe dijgbaju olooyi ru Manchester City nini ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba UEFA Champions to waye lalẹ ọjọ Abamẹta ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun ọdun 2021.
Ninu idije Premier League ni Chelsea ti kọkọ fagba han Man City lẹyin ti Thomas Tuchel di akọnimọọgba Chelsea.
Kẹrẹ kẹrẹ, Man City ati Chelsea tun pade nini ipele to kangun si aṣekagba idije FA Cup, iya naa lo tun bade fun Man City lọwọ Chelsea.
Ọpọ lo ti ro pe ina eṣi ko le jo Man City nigba mẹta lere wọn, amọ ina yii jo wọn raurau nio.
- Adeherself sọ̀rọ̀ sókè lẹ́yìn tí Cute Abiola ṣe ìgbéyàwó ìdánkọ́nkọ́ l'Ogbomoso
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Greenfield tí wọ́n jí gbé ní Kaduna gba òmìnira lẹ́yìn tí àwọn òbí wọn san "180 mílíọ́nù naira"
- Àyà mi ń já, ẹ̀rù ń bà mí torí iṣẹ́ abẹ ìdí tí mo fẹ́ ṣe - Bobrisky
- Toyin Abraham pàrokò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sáwọn tó ń gbèjà rẹ̀ lórí ayélujára
Aṣeju Pep Guardiola ṣakoba fun Manchester City
Ọpọ onimọ nipa ere bọọlu ni wọn ti di ẹbi ru olukọni Man City, Pep Guardiola fun aṣeju nipa bi o ṣe maa n to awọn agbabọọlu to maa n lo fun awọn ifẹsẹwọnsẹ to lamilaaka.
Iru iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ fun igba meji ninu idije Champions League nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Lyon ati Monaco lo City jade ninu idije naa lai ro tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun to ya gbogbo eeyan lẹnu to fi mọ olukọni Chelsea fun ra rẹ, Tuchel ni pe Guardiola ko fi agbaọjẹ agbabọọlu arin gbungbun rẹ Fernandinho sara awọn to bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba Champions League ọjọ Abamẹta.
Ohun to tumọ si nipe ko si agbabọọlu to le di aarin mu fun City ni wọn igba ti o jẹ pe Rodri tabi Fernandinho ko si nibẹ.
Eyi lo ṣakoba fun City nitori ti wọn ba ti lọ siwaju bayii ni Chelsea ri ọna lọ si ile wọn lati ṣe wọn ni suta.
Apa keji ere bọọlu naa ni Guardiola gbe Fernadinho wọle, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.
- Chelsea pòfo nínú ìdíje FA Cup, báwo ni Champions League yóò ṣe rí pẹ̀lú Man City?
- Tí Benue kò bá ní Sunday Igboho tIẹ̀, ìṣekúpaní yóò tẹ̀síwájú - Reno Omokri
- Ìjọba Buhari ti jáwọn ọmọ Nàìjíríà kulẹ̀, àwọn aṣòfin yarí àmọ iléeṣẹ ààrẹ ni...
- Àyà mi ń já, ẹ̀rù ń bà mí torí iṣẹ́ abẹ ìdí tí mo fẹ́ ṣe - Bobrisky












