Toyin Abraham: Àwọn èèyàn tó ń rí jẹ ní ìdí mọ̀dàrú ló ń bu pẹtiró sí ìjà tó wà nílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Toyin_Abraham/Instagram
Gbajugbaja osere tiata nni, Toyin Abraham ti tun sọrọ soke lẹyin aawọ to waye laarin rẹ ati osere Tiata miran, Lizzy Anjorin.
Bẹẹ ba gbagbe, gbajumọ sọrọsọrọ lori ayelujara, Tokunbo Aboderin, ti ọpọ eeyan mọ si ESABOD lo ba wọn pari ija naa lọjọ Isẹgun.
Amọ ni irọlẹ Ọjọbọ ni Toyin tun n wi lele pe, oun ko lọwọ tabi mọ ohunkohun nipa bi ẹnikẹni to ba ni oun n gbeja oun, se n bu ẹnikẹni.
- Ìjà Toyin Abraham àti Lizzy Anjorin tún búrẹ́kẹ́
- Lẹ́yìn ọdún méjì tí iná ìjà tí n jó láàrin wọn, Lizzy Anjorin sọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Toyin Abraham ṣẹ̀ ẹ́
- Gìrì àparò lásán ni gbogbo èpè wọn! àwọn tó ń ti Toyin Abraham lẹ́yìn rèé lórí ìjà tó paá pọ́ mọ́ Lizzy Anjorin ati ESABOD
- Toyin Abraham jọ̀wọ́ dáríjì mí - Yomi Fabiyi
- Àwọn ọmọ ìṣọta àti Toyin Abraham jọ wàákò lásìkò tó ń ya sinimá
- Kí ló fa ìjà rọ̀fọ̀rọ́fọ̀ láàrin Toyin Abraham àti olólùfẹ́ rẹ̀ lórí ayélujára?
- Lẹ́yìn tí mo gbé ayé mi yẹ̀wò, mo ríi pé asán layé - Toyin Abraham
- Ìrìnàjò Toyin Abraham, láti orí gbèsè jíjẹ, ó di onílé, onimọto àti aya lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ
Toyin ni ki wọn mase di ẹbi kankan ru oun ti ẹni to n gbeja oun ba n sepe tabi se ẹẹkẹ eebu.
"Mo ri awọn fidio kan lori ayelujara ninu eyi ti awọn eeyan kan ti wọn ni awọn n gbeja mi ti n sẹ epe fawọn eeyan miran.

Oríṣun àwòrán, Toyin_Abraham/Instagram
Bakan naa, ni wọn si tun n fa awọn ọmọde ti ko ni ẹsẹ lọrun sinu wahala ti wọn n da silẹ.
Ẹ jọwọ n ko fara mọ iru iwa yi ni ọnakọna.
Koda, n ko fi igba kankan ran yin ni iru isẹ bayii ri, ẹ jọwọ, ẹ yọ awọn ọmọde kuro ninu ere itage tẹ n se."
Toyin Abraham tẹsiwaju pe, awọn ọmọde naa yoo dagba, amọ gbogbo hun ti wọn ti sọ nipa wọn ni yoo si wa lori ayelujara, ti ko si le lọ sokun igbagbe laelae.
O fikun pe oun mọ riri ifẹ ati itara awọn eeyan nipa oun amọ ko si awijare kankan lati maa ba ọja ẹlomiran jẹ.
Toyin ni oun fura pe awọn eeyan kan n ri jẹ nidi mọdaru to n waye loore koore naa, nitori fidio ti oun sẹsẹ wo tan fidi eyi mulẹ.
"Mo ri fidio kan tawọn eeyan kan ti n sẹ epe fun awọn alabasisẹpọ mi kan lagbo tiata atawọn ọmọ wọn.
Eyi ko se dandan, iwa ibi si ni pẹlu, ọna ati jẹ si ni wọn se n bu epo eebo si ere oitage to n lọ lọwọ naa, eyi to ti toju su ni."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àyà mi ń já, ẹ̀rù ń bà mí torí iṣẹ́ abẹ ìdí tí mo fẹ́ ṣe - Bobrisky
- Àwọn ọ̀dọ̀ wa ò kí ń ṣe òkú ní Nàìjíríà, ẹ jẹ́ kí wọ́n wà ní gbogbo ìpele ìpinu - Ooni
- Góòlù ₦14bn, ilé $80m la rí gbà padà lọ́wọ́ Diezani Alison-Madueke - EFCC
- Òkú èèyàn 60 ni wọ́n rí yọ nínú àwọn tó bá ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ ní Kebbi
- Ìdí rèé tí ọ̀gágun 30 fi gbọdọ̀ kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí ìyànsípò olórí ọmogun tuntun
- Àwọn olórí lágbáyé tó ti wọ inú ibojì Ànọ́bi Muhammad rí
- Kàyéèfì! Ọwọ́ tẹ òkú tó ń ká àwọn èèyàn mọ́lé, to sì ń jà wọ́n lólè dúkìá
- Fayemi dá ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ gíga Health Tech Ijero dúrò lẹ́nu iṣẹ lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ 100 déèdé di èrò iléèwòsàn
Toyin wa n ke si awọn eeyan ti wọn ba ti sọrọ odi si lori ayelujara, pe ki wọn fa ọrọ naa de ibi to lapẹrẹ, ki ẹni to sọrọ odi si wọn naa si sanwo gba ma binu.
"Ohun ti mo gbero lati maa se ree lati akoko yii lọ, igba ikẹyin si ree ti maa gbe iru ikede yii sita.
Ohun to wa lọkan mi bayi ni bi sinima mi tuntun yoo se jade, mo dupẹ, ẹ se pupọ.




















