Diezani Alison-Madueke: Àwọn aṣòfin àti èrò ìwòran yanu sílẹ̀ torí owó tí EFCC rí gbà padà

Oríṣun àwòrán, Efcc
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu atawọn iwa ọdaran to jẹ mọ lorilẹede Naijiria, EFCC, ti kede iye apapọ awọn dukia ile, ẹsọ ara ati goolu, ti wọn ri gba lọwọ minisita tẹlẹ fọrọ epo rọbi, Diezani Alison Madueke.
Madueke, ẹni to jẹ Minisita laye isejọba Goodluck Jonathan to kọja, ni EFCC ri ẹsọ ara to to biliọnu mẹrinla ati miliọnu lọna ọtalenirinwo naira (₦14.460BN) gba pada lọwọ rẹ.
Alaga ajọ EFCC, Abdulrasheed Bawa lo sisọ loju ọrọ yii fun ile asofin tawọn asoju lọjọ Ẹti.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn ọ̀dọ̀ wa ò kí ń ṣe òkú ní Nàìjíríà, ẹ jẹ́ kí wọ́n wà ní gbogbo ìpele ìpinu - Ooni
- Òkú èèyàn 60 ni wọ́n rí yọ nínú àwọn tó bá ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ ní Kebbi
- Ìdí rèé tí ọ̀gágun 30 fi gbọdọ̀ kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí ìyànsípò olórí ọmogun tuntun
- Àwọn olórí lágbáyé tó ti wọ inú ibojì Ànọ́bi Muhammad rí
- Kàyéèfì! Ọwọ́ tẹ òkú tó ń ká àwọn èèyàn mọ́lé, to sì ń jà wọ́n lólè dúkìá
- Fayemi dá ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ gíga Health Tech Ijero dúrò lẹ́nu iṣẹ lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ 100 déèdé di èrò iléèwòsàn
Igbimọ tẹẹkoto nile asofin tawọn asoju lo n joko tọpinpin iye apapọ ohun ti ajọ EFCC ri gba pada lọwọ awọn eeyan ti wọn fi ẹsun ajẹbanu kan.
Se ni awọn asoju-sofin naa atawọn ero iworan to wa nibi ijoko igbimọ naa la ẹnu silẹ, lai le pade mọ nigba ti wọn gbọ ikede ajọ EFCC naa lori dukia Ẹsọ ara ti wọn gba lọwọ Diezani.

Oríṣun àwòrán, Efcc
Bakan naa ni alaga ajọ EFCC tun sọ fun awọn asoju-sofin naa pe apapọ iye owo awọn ile ti wọn ri gba pada lọwọ Diezani to ọgọrin miliọnu dọla ($80M).









