Ijero Ekiti Health Tech: Ìjọba Ekiti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ tó gbé akẹ́kọ̀ọ́ 100 dé ilé ìwòsàn

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe ki ọga agba ileewe giga College of Health Sciences, Ijero-Ekiti, kuro lẹnu iṣẹ naa, lẹyin ti awọn akẹkọọ kan di eero ile iwosan.
Ọjọbọ ni Gomina Kayọde Fayẹmi paṣẹ pe ki Ọmọwe Cecilia Adebayọ lọ ọ rọkun lile, titi igbimọ oluwadii yoo fi pari iwadii lori nkan to fa aisan to deedee kọlu akẹkọọ to le ni ọgọrun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ṣaaju ni iroyin jade pe awọn ikọ afinko kan gba aṣẹ lọwọ awọn alaṣẹ ileewe naa lati fin oogun apakokoro sinu ọgba ileewe, lasiko ti awọn akẹkọọ n ṣe idanwo lọwọ.
Lẹyin ti wọn fin oogun naa, ti igbagbọ wa pe nitori Covid-19 ni wọn fi ṣe bẹ ẹ, ni awọn akẹkọọ naa bẹrẹ si ni dubulẹ aisan.
Eyi si lo mu ki awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga naa ba ọpọ dukia jẹ láti fẹhonuhan lẹyin tawọn akẹẹgbẹ wọn kagbako.
Awọn oṣiṣẹ panapana ijọba apapọ lo wa fin ile ẹkọ naa lasiko tawọn akekọọ n ṣe idanwo lọwọ.Kẹ́míkà oogun ipakokoro náà ni a gbọ pe o mu kí awọn akẹkọọ kan ṣubu nigba ti awọn miran ko le ṣọrọ daadaa.Koda, iroyin tun sọ pe ori lo ko awọn oṣiṣẹ panapana ọhun yọ pẹlu atilẹyin awọn ọlọpaa.

Oríṣun àwòrán, Ekiti state ministry of health and human sciences
Ẹwẹ, kọmiṣọnna eto ilera ipinlẹ Ekiti, Oyebanji Filani ti ṣabẹwo s'awọn akẹkọọ naa nile iwosan.O ni awon kan tiẹ ti gbadun ti wọn si ti lọ si ile wọn.Kọmiṣọnna ni ijọba yoo moju to awọn to si n gba itọju nile iwosan titi ti ara wọn yoo fi ya.

Oríṣun àwòrán, Ekiti state ministry of health and human sciences
O fikun ọrọ rẹ pe awọn to lọ fin ọgba ile ẹkọ gíga naa lasiko tawọn akekọọ n ṣe idanwo lọwọ ko ni ṣai foju ba ile ẹjọ.
Akọwe ikede fun gomina, Yinka Oyebọde sọ ninu ikede to fi sita pe ọsẹ meji ni igbimọ oluwadii naa yoo fi ṣe isẹ rẹ, bẹrẹ lati ọsẹ to n bọ.
Bakan naa lo sọ pe wọn ti sọ fun awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ti ijọba apapọ to wa fin oogun naa, lati pada si ọfiisi wọn nilu Abuja.














