Ìjàmbá iná lọ́jà Alaba l'Eko, ará ọjà àti iléeṣẹ́ panápaná tako ara wọn lórí aìráye pa iná náà

Oríṣun àwòrán, screenshot
Iroyin sọ pe pe ina nla ti sọ ni Ọja Alaba International Market to wa ni Ọjọọ ni ipinlẹ Eko lọjọ Ẹti
Ko tii si ẹni lee sọ ni pato ohun gan to ṣe okunfa ijamba ina naa tabi iye awọn eeyan to faragba ijamba ina naa.
Awọn ti i’sẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe gbogbo akitiyan lati pe awọn panapana lo ja si pabo eyi lo si mu ki awọn eeyan to wa nibẹ gbiyanju ati funrawọn pa ina ọhun.
Amọṣa o, ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko ti fi ẹsun kan awọn eeyan ọja naa pe wọn kọ lati jẹ ki awọn oṣiṣẹ panapana o wọ agbagbe naa lati pa ina to n jo naa.
Ileeṣẹ panapana ni awọn ọlọja ko jẹ ki awọn raye de ọja naa
Atẹjade kan ti ọga agba ileeṣẹ panapana ni ipinlẹ Eko, Margaret Adeṣẹyẹ fi sita, sọ pe “Awọn oṣiṣẹ panapana lati jọ, Sari-Iganmu ati Ajegunlẹ gbiyanju lati de ibẹ pa ina naa ṣugbọn awọn ero to wa lagbegbe naa da wọn pada, lai jẹ ki wọn raye de ibẹ lati ṣe iṣẹ wọn.”

Oríṣun àwòrán, screenshot








