Serikin Hausa sọ̀rọ̀ gbá orí àwọn Hausa oníṣòwò bí wọ́n ṣe kọlu ikọ̀ Amotekun ní Ekiti
Ni opin ọsẹ to kọja ni iroyin jade pe awọn ẹya Hausa to n ta ọja ni ilu Ado Ekiti, ipinlẹ Ekiti gbe ina woju ikọ Amotekun.
Rogbodiyan naa bẹ silẹ niluu Ado Ekiti lọjọbọ lasiko ti awọn oniṣowo kan to jẹ ẹya Hausa kọju ija si awọn ẹṣọ alaabo Amotekun.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, wọn yinbọn pa ọkan lara awọn oniṣowo ọhun, nigba ti ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ Amotekun farapa yanayana, ti wọn si ti n gba itọju bayii nile iwosan amọ ninu ifọrọwanilẹnuwo yii, olori ikọ Amotekun ni bẹẹ kọ lo ri.

ijọba ipinlẹ Ekiti ti kọkọ gbiyanju lati ko awọn oniṣowo naa kuro ninu ọja Atikankan, eyii ti igbagbọ wa pe awọn ọdaran kan atawọn to n ta oogun oloro n lo, lọ sinu ọja mii ti ijoba ti pese fun wọn, amọ wọn kọ jalẹ.
Ẹnikan ti ko fẹ fi orukọ rẹ lede sọ fun awọn akọroyin pe lakọlakọ ni iro ibọn laarin ikọ mejeji n dun leralera fun ọpọ wakati, eyii to mu ki awọn oniṣowo mii to wa lagbegbe ọhun ti ilẹkun ṣọọbu wọn lọsan gangan.
Amọ awọn adari ikọ mejeji yii ti sọ ohun ti oju wọn ri lọjọ naa.












