Amotekun àtàwọn oníṣòwò kọlu ara wọn nílùú Ado Ekiti, ọ̀pọ̀ dèrò ilé ìwòsàn

Amotekun

Oríṣun àwòrán, Amotekun Ondo

Rogbodiyan bẹ silẹ niluu Ado Ekiti lọjọbọ lasiko ti awọn oniṣowo kan to jẹ ẹya Hausa kọju ija si awọn ẹṣọ alaabo Amotekun.

Iroyin ni ija naa ko ṣẹyin igbesẹ ijọba lati ko awọn oniṣowo naa kuro ninu ọja Atikankan si ọja Agric Olope.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, wọn yinbọn pa ọkan lara awọn oniṣowo ọhun, nigba ti ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ Amotekun farapa yanayana, ti wọn si ti n gba itọju bayii nile iwosan.

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Ekiti ti kọkọ gbiyanju lati ko awọn oniṣowo naa kuro ninu ọja Atikankan, eyii ti igbagbọ wa pe awọn ọdaran kan atawọn to n ta oogun oloro n lo, lọ sinu ọja mii ti ijoba ti pese fun wọn, amọ wọn kọ jalẹ.

Ẹnikan ti ko fẹ fi orukọ rẹ lede sọ fun awọn akọroyin pe lakọlakọ ni iro ibọn laarin ikọ mejeji n dun leralera fun ọpọ wakati, eyii to mu ki awọn oniṣowo mii to wa lagbegbe ọhun ti ilẹkun ṣọọbu wọn lọsan gangan.

Amọ ṣa, awọn akọṣẹmọṣẹ ikọ Rapid Response Sqaud, RSS atawọn ọlọpaa lo pada pana rogbodiyan ọhun.

Olori awọn Hausa naa, Abdul Yusuf, sọ pe diẹ lo ku ki ẹmi oun naa lọ si iṣẹlẹ ọhun amọ Ọlọrun lo ko oun yọ.

Yusuf da ẹbi iṣẹlẹ naa le awọn Hausa bii tirẹ lori latari pe wọn kọ lati kuro ninu ọja naa lọ sibi ti ijọba pese fun wọn.

Ẹwẹ, alaga ijọba ibilẹ Ado, Bosun Oshaloni ti sọ pe awọn ti bẹrẹ ijiroro pẹlu awọn Hausa naa bayii lati ri daju pe alaafia pada si agbegbe ọhun.

Oshaloni tẹnumọ pe Atikankan ti da ibudo awọn ọdaran, ijọba ko si ni la oju rẹ silẹ ki awọn kọlọrọsi kan maa lo ọja naa fun iwa ọdaran.