Buhari kọ̀wé sílé aṣòfin fún àṣẹ́ láti yá $800m lọ́wọ́ báǹkì àgbáyé

Aarẹ Buhari

Bí ó ṣe kú ọjọ́ péréte kí sáà Ààrẹ Muhammadu Buhari wá sí òpin, Ààrẹ ti rọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà láti buwọ́lu ìbéèrè òun láti yá $800m lọ́wọ́ ilé ìfowópamọ́ àgbáyé láti fi ṣètò “National Safety Net Programme”.

Nínú àkọránṣẹ́ kan tí Ààrẹ fi ṣọwọ́ sílé, èyí tí Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, sẹ́nétọ̀ Ahmad Lawan kà níwájú ìgbìmọ̀ ilé ló ti ń bèèrè fún àṣẹ ilé náà.

Ààrẹ Buhari ní ohun tí àwọn fẹ́ lo owó náà fún ni láti àtìlẹyìn fún àwọn aláìní, tó sì jẹ́ wí pé àwọn ìdílé tí kò rí jájẹ káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni àwọn máa pín owó náà fún.

Ó ní ó wà lára ètò fífún àwọn aláìní lówó èyí tí ìjọba àpapọ̀ ti ń ṣe tẹ́lẹ̀.

Ààrẹ fi kun pé akoto báǹkì àwọn tí yóò jẹ àǹfàní ètò náà ni àwọn máa fi owó náà tí ilé bá ti buwọ́lu fún àwọn láti yá owó yìí.

Bákan náà ló ní ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìjọba ìyẹn Federal Executive Council (FEC) ti ní kí àwọn yá owó náà, tó sì ní ìbuwọ́lù ilé aṣòfin àgbà ni àwọn ń dúró dè kí àwọn tó bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti gba owó ọ̀hún láti ilé ìfowópamọ́ àgbáyé.

Ṣáájú ni Mínísítà fétò ìsúná àti ààtò ìlú, Zainab Ahmed ti kéde pé ìjọba àpapọ̀ fẹ́ yá ẹgbẹ̀rin mílíọ̀nù dọ́là èyí tí wọ́n máa pín fún àádọ́ta mílíọ̀nù ọmọ Nàìjíríà tó jẹ́ àwọn aláìní.

Ó ní èyí ń wáyé láti fi dín ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàìjíríà yóò kojú lẹ́yìn tí ìjọba bá yọ ìrànwọ́ orí bẹntiróòlù nínú oṣù Kẹfà.

Láìpẹ́ yìí ni àjọ tó ń mójútó gbèsè tí Nàìjíríà jẹ ní gbèsè Nàìjíríà ti wọ tírílíọ̀nù 46.25 náírà tàbí bílíọ̀nù 103.1 dọ́là ní ìparí oṣù Kejìlá ọdún 2022.

Èyí ló fi tírílíọ̀nù méje náírà lé kún gbèsè Nàìjíríà ọdún 2021.