Ààrẹ Buhari fi ọ̀ṣẹ̀ kan kún ìrìnàjò rẹ̀ sí ìlú London láti ṣe àyẹ̀wò eyín

Buhari

Oríṣun àwòrán, State House

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti kede pe oun yoo lo ọṣẹ kan sii ni ilu London to wa lọwọlọwọ.

Aarẹ Buhari fi eyi lede ninu atẹjade ti oluranlọwọ pataki fun aarẹ Buhari, Bashir Ahmad fi lede loju opo Twitter rẹ.

Ikede naa ni aarẹ Buhari yoo wa ni ibẹ fun ọṣẹ kan sii nitori dokita onimọ nipa eyin rẹ ni ki aarẹ naa duro fun ayẹwo pipẹ.

O ni dokita aarẹ naa ni oun fẹ rii fun ayẹwo miran ni ọjọ marun un si isinyin fun ayẹwo lori eto iwosan ti wọn ti bẹrẹ.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Aarẹ Buhari lo gbẹra lọ si ilu Ọba lati lọ darapọ mọ awọn adari orilẹede miran lati ṣe ajọyọ fifi Ọba Charles III jẹ ni Ilẹ Gẹẹsi.

Ọjọ Kẹfa, Osu Karun un, ọdun 2023 ni ifinijoye naa waye ti aarẹ Buhari si kopa nibẹ.

Ibeere mi ni pe ṣe ko si dokita eyin to dantọ ni Naijiria to lee wo eyin aarẹ Buhari ni? - Shehu Sani

Atẹjade naa ni ‘’ Aarẹ Buhari yoo wa ni ilu London fun ọṣẹ kan sii nitori dokita eyin rẹ ni oun fẹ ṣe ayẹwo rẹ.

Onimọ naa ni ki aarẹ ri oun ni ọjọ marun un si iṣinyii ki awọn le bẹrẹ eto iwosan ti wọn ti bẹrẹ’’.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Igba akọkọ kọ niyii ti aarẹ Buhari yoo wa ni Ilẹ Gẹẹsi fun eto ilera rẹ. Lọpọ igba si ni awọn ọmọ Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu igbeṣẹ naa.

Sẹnetọ Shehu Sani to fesi si igbesẹ aarẹ ni ibeere oun ni pe ṣe ko si dokita eyin to dantọ ni Naijiria to lee wo eyin aarẹ Buhari ni?

Bẹẹ si ni o kesi awọn ajọ eleto ilera, Nigerian Medical Association, National Association of Resident Doctors, Nigerian Dental Association ati National Association of Nigerian Nurses & Midwives lati fi esi si ibeere rẹ.