Ẹ tẹ́wọ́ gba àṣeyọrí Adeleke - Oyetola sí APC Osun

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola ni oun ti tẹwọgba esi ileęjọ to ga ju lorilẹede Naijiria to ni ojulowo ni idibo to gbe Sẹnẹtọ Ademola Adeleke wọle gẹgẹ bii Gomina Ipinlẹ Osun.

Oyetola ninu atẹjade kan to buwọlu ni idajọ ile ẹjọ naa ko tẹ pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC lọrun sugbọn awọn ni lati tẹwọgba esi lati fun alaafia laye nipinlẹ Osun.

Gomina tẹlẹ wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC ati awọn to dibo fun ninu eto idibo ọdun to kọja lati tẹwọgba esi naa gẹgẹ bii amuwa Ọlọrun, ki wọn si tẹsiwaju.

"A ní igbagbọ pe ẹjọ to daa ni a gbe wa si ileęjọ sugbọn ọna miiran ni ileęjọ fi wo. Pẹlu bi idajọ naa ko ṣe tẹ wa lọrun pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ wa, a ni lati tẹlẹ ofin gẹgẹ bi olugbe to fẹran ilu".

O tẹsiwaju pe: "Si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC kaakiri ipinlẹ Osun, mo rọ yin lati tẹwọgba esi ileęjọ. Nnkan to sẹlẹ yii lo jẹ anfani gbogbo wa. Bi a ṣe padanu ipinlẹ Osun, a jogun gbogbo Naijiria.

"Ọrọ idagbosoke ipinlẹ Osun si jẹ mi logun pupọ. Maa ṣi maa ṣisẹ pẹlu awọn eeyan ipinlẹ Osun lati mu idagbasoke wa si ipinlẹ wa.

"Mo rọ gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Osun to fọwọsowọpọ lati mu idagbasoke de si ipinlẹ Osun lai wo ti ẹgbẹ oselu kankan lati tẹsiwaju".

Mo ki Adeleke ku orire - Oyetola

"Si gomina ipinlẹ Osun, Sẹnẹtọ Ademola Nurudeen Jackson Adeleke, mo fi asiko yii ki ẹ ku orire fun aseyọri rẹ ni ileęjọ gíga.

"Mo gbaa ladura pe ki saa rẹ san awọn eeyan nipinlẹ Osun. Mo rọ ẹ lati gba ju mọ ṣẹ.

"A ní lati gbe oselu si ẹgbẹ kan, asiko ti to lati mu aye dẹrun fun awọn eeyan nipinlẹ Osun lai wo ẹṣin tabi ẹya kankan.

"Gbogbo ede aiyede ti a jọ ni papọ ni a gbọdọ gbe si ẹgbẹ kan bayi, ọrọ eto abo awọn ipinlẹ Osun di ọwọ rẹ. Mo gbaa ladura pe ki alaafia jọba ní saa ijọba rẹ."