Ilé ẹjọ́ ju tọkọtaya tó n fi ipá bá ọmọ ọ̀dọ̀ wọn lòpọ̀ sí ẹ̀wọ̀n nípìnlẹ̀ Eko

Ile ẹjọ Majisireti to wa ni agbegbe Ogudu nipinlẹ Eko, ti ju tọkọtaya kan, Omolara Alashe ati ọkọrẹ, Ramoni Lateef, si ọgba ẹwn fun ẹsun pe wọn fi ipa ba ọmọ ọdọ wọn lo.
Tọkọtaya naa to n gbe ni adugbo Igbonla ni Ketu, ni iroyin sọ pe wọn n koju ẹsun ifipabanilopọ, ifiyajẹni, ati ole jija.
Ileeṣẹ iroyin NAN jabọ pe, ninu oṣu Kẹta ni tọkọtaya Ramoni ati Omolara, da ọran naa nile wọn.
Ọlọpaa to ko wọn wa sile ẹjọ, Donjor Perezi, sọ fun adajọ pe ọkọ, Ọgbẹni Ramoni Lateef, ma n fi ipa ba ọmọ ọdọ wọn, to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogun lopọ, pẹlu iranlọwọ iyawo rẹ.
“Iyawo lo ma n ji ọmọbinrin naa ni aarin oru. Lẹyin naa ni yoo bọ ọ si ihoho, ko to sọ fun ọkọ rẹ pe ko ba a ni ibalopọ.”
Yatọ si eyi, ọlọpaa ṣalaye pe Arabinrin Alashe funra rẹ lo kọkọ ki ika ọwọ si oju ara ọmọbinrin naa titi ti ẹjẹ fi jade.
“Bakan naa lo kọ lati ma a san owo oṣu fun, to si tun gba siimu to wa ninu foonu rẹ, ati kaadi ATM.”
Àwọn iwa wọn yii ni Isipẹtọ ọlọpaa, Perezi, sọ pe o tako ofin iwa ọdaran nipinlẹ Eko.
Adajọ to n gbọ ẹjọ naa, Arabinrin M.O. Tanimola, paṣẹ ki wọn o fi tọkọtaya naa si ọgba ẹwọn Ikoyi, titi di ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ti igbẹjọ wọn yoo tẹsiwaju.














