Taa ni Dele Giwa, àgbà akọ̀ròyìn tí wọ́n fi àdó olóró pa lásìkò ìjọba olọgun?

Dele Giwa

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bawo ni Dele Giwa se ku ?

Bi a ba ni ka maa p'ori akọni laarin awọn akọroyin orile-ede Naijiria, ko si igba ti ida Dele Giwa ko ni lalẹ gaaraga.

Olootu agba iwe iroyin Newswatch ni Giwa, o si jẹ ọkan lara awọn akoroyin ti o dantọ ni Naijiria ki ọlọjọ to de.

Ọrọ iku rẹ jẹ nnkan to ṣokunkun titi di bi a ti ṣe n sọrọ yii.

Orisirisi alaye si ni awọn eeyan ti fi sita lati na ika si awọn ti wọn lero pe o lọwọ ninu iku rẹ.

A ko ridi eyikeyi awọn alaye yi fi mulẹ ṣugbọn ohun ti ko ruju ni pe ado oloro ni wọn fi pa Dele Giwa eleyi ti wọn gbe sinu apo ifiweranṣẹ si ni.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC, Kayode Soyinka to jẹ olootu iwe iroyin Newswatch ni London sọ pe oun ati Dele Giwa jijọ wa nile rẹ ni GRA lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 1986 ni.

Iyawo Dele Giwa, Funmilayo gẹgẹ bi Kayode ti ṣe sọ gbe akara fun wọn ti wọn si jijọ n ṣaroye nipa bi awọn ọtẹlẹmuye ti ṣe fọrọ wa Dele Giwa lẹnuwo ṣaaju ọjọ naa.

Ṣaa deede ni wọn gbọ ti eeyan kan n kan ilẹkun ti ọmọ Dele Giwa, Kayode si wa jiṣe apo iwe naa fun Dele Giwa lọjọ naa.

Kete ti Dele Giwa ṣi apo iwe yii ni ado oloro bu gbamu ti o si gbina jẹ.

Ori ko Kayode Soyinka yọ ninu ibagbamu ado oloro naa amọ o farapa diẹ.

Dele Giwa, Yakubu Mohammed ati dokita Doyin Abiola

Oríṣun àwòrán, Yusuf Mohammed

Àkọlé àwòrán, Dele Giwa, Yakubu Mohammed ati dokita Doyin Abiola
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC, Kayode Soyinka to jẹ olootu iwe iroyin Newswatch ni London sọ pe oun ati Dele Giwa jijọ wa nile rẹ ni GRA lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 1986 ni.

Ọjọ buruku, Eṣu gbomi mu naa bọ si ọjọ Aiku.

Iyawo Dele Giwa, Funmilayo gẹgẹ bi Kayode ti ṣe sọ gbe akara fun wọn ti wọn si jijọ n ṣaroye nipa bi awọn ọtẹlẹmuye ti ṣe fọrọ wa Dele Giwa lẹnuwo ṣaaju ọjọ naa. Ṣaa deede ni wọn gbọ ti eeyan kan n kan ilẹkun ti ọmọ Dele Giwa, Kayode si wa jiṣe apo iwe naa fun Dele Giwa lọjọ naa. Kete ti Dele Giwa ṣi apo iwe yii ni ado oloro bu gbamu ti o si gbina jẹ. Ori ko Kayode Soyinka yọ ninu ibagbamu ado oloro naa amọ o farapa diẹ.

Toun ti pe wọn tara ṣaṣa gbe e lọ si ile iwosan, Kayode sọ pe ibẹ ni o dakẹ si.

Nigba ti iṣẹlẹ yi waye lọdun 1986, Naijiria si wa labẹ ijọba ologun labẹ akoso Ọgagun Ibrahim Babangida.

Igba akọkọ si re e ti wọn yoo fi ado oloro pa eeyan ni Naijiria.

Iṣẹlẹ naa titi di oni jẹ eleyi ti awọn eeyan ṣi fi n ṣakawe ewu to wa nibi iṣẹ akọroyin ni Naijiria.

Ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kí ìwádìí ikú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ padà

Aworan Dele Giwa

Oríṣun àwòrán, Others

Adajọ agba ni ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ niluu Abuja, Inyang Ekwo ti pasẹ fun agbẹjọro agba lorilẹede Naijiria to tun jẹ minisita fun eto idajọ pe ki iwadii bẹrẹ pada lori iku gbajugbaja akọroyin, Dele Giwa.

Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Adajọ Ekwo sọ pe wọn gbọdọ pese awọn to lọwọ ninu iku awọn akọroyin lorilẹede Naijiria.

Ọdun 1986 ni Dele Giwa jade laye lẹyin to tẹwọ gba ado oloro ti wọn fi sinu lẹta ni ọfisi rẹ nipinlẹ Eko.

Yatọ si igbẹjọ nipa Ọgbẹni Giwa, ile ẹjọ ọrọ naa kan gbogbo awọn to lọwọ ninu iku awọn akọroyin to n sisẹ wọn, ki wọn si fi iya jẹwọn ni ilana to ba ofin mu .

Adajọ Ekwo wa rọ ijọba apapọ lati pese aabo to yẹ fun awọn akọroyin ni ilana ti ofin gbe kalẹ.