Kí ló tún dé tí PrimeBoy, ọ̀rẹ́ Mohbad tún fi pe iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lẹ́jọ́?

Oríṣun àwòrán, Collage
Ibrahim Owodunni tawọn eeyan mọ si Primeboy, ọrẹ Ilerioluwa Aloba, (Mohbad) tun ti pe ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lẹjọ lẹyin ọsẹ diẹ to leri lati pe Iya Mohbad lẹjọ fun ẹsun ibanilorukọjẹ.
Ẹsun ti Primeboy ka si awọn ọlọpaa lẹsẹ lasiko yii ni pe wọn fi orukọ oun si ara orukọ awọn eeyan ti wọn n wa (wanted) latari iku Mohbad.
Ọmọkunrin toun naa n kọrin taka-sufee yii sọ pe ko pẹ ti ọlọpaa ni koun yọju lati sọ tẹnu oun lori iku naa, loun fa ara oun kalẹ.
O ni ṣugbọn wọn ko yọ orukọ oun kuro ninu iwe orukọ awọn eeyan ti wọn wa naa titi doni.
Kí ló ṣẹlẹ̀ láàrin Primeboy àti ọlọ́páà?
Lọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa ọdun 2023, awọn ọlọpaa gbe ikede kan jade ti wọn fi ni awọn n wa Primeboy.
Eyi waye lẹyin ti wọn ni Primeboy ko jẹ ipe ti awọn ti kọkọ pe e lati waa sọ ohun to mọ lori iku Mohbad.
Gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ṣe wi, agbẹjọro fun Primeboy, Akinpelu Ogunbona, ti pe ileeṣẹ ọlọpaa lẹjọ.
Ile-ẹjọ giga to wa n’Ikoyi, nipinlẹ Eko ni lọọya naa pe ẹjọ ọhun si lọjọ kọkanla, oṣu kẹwaa, 2024 bi wọn ṣe sọ.
Igbesẹ wo ni Primeboy gbé?
Apa kan iwe ipejọ naa ka pe, ’’Primeboy ti pe ileeṣẹ ọlọpaa lẹjọ si ile-ẹjọ giga to wa n’Ikoyi, o si n beere awọn ẹtọ rẹ kan.
‘’Lara ohun to n beere ni pe iwe ti ọga ọlọpaa patapata kọ, to fi kede Primeboy bii ẹni ti wọn n wa, jẹ titẹ ẹtọ ẹni mọlẹ labẹ ofin.
‘’Bakan naa ni Primeboy fẹ ki wọn yọ orukọ oun kuro ninu iwe awọn eeyan ti wọn n wa fun iwa ọdaran ’’
Tẹ o ba gbagbe,latigba ti Mohbad ti ku lọjọ kejila, oṣu kẹsan-an ọdun 2023 ni ariwo ti bẹrẹ lori iku ọhun.
Oṣu kẹsan-an to kọja yii ni iku naa pe ọdun kan, ṣugbọn oni ẹjọ,ọla aroye ko ti i sinmi lori iku ọmọ naa.
Ọrẹ ati igba kekere ni Oloogbe Mohbad ati Primeboy, ki iku too ya wọn.
Ọsẹ meloo sẹyin ni Primeboy loun yoo pe Iya Mohbad lẹjọ fun ibanilorukọjẹ, oun ati ọlọpaa ni wọn si tun fẹẹ jọ fa a bayii.
Mohbad wa nibẹ, wọn o ti i sin i.















