Liam Payne, gbajúmọ̀ akọrin ẹni ọdún 31, kú lẹ́yìn tó jábọ́ ní àjàkẹta ilé ìtura

Oloogbe Liam Payne.

Oríṣun àwòrán, Getty image

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Liam Payne.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja akọrin ilẹ Gẹẹsi, Liam Payne, ti jade laye lẹni ọdun mọkanlelọgbọn (31).

Aja kẹta ile itura Buenos Aires, lorilẹede Argentina, ni ijamba to pa Liam Payne ti waye, gẹgẹ bi awọn ọlọpaa Buenos Aires ṣe sọ.

Atẹjade awọn ọlọpaa naa ṣalaye pe awọn ri oku Payne lẹyin tawọn gba ipe pajawiri lagbegbe Palermo, l’Ọjọruu, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹwaa ọdun 2024 yii.

Wọn ni ipe tawọn kọkọ gba ni pe ọkunrin kan to ṣee ṣe ko ti mu ọti yo ati oogun oloro, wa ninu otẹẹli naa.

Nigba ti wọn debẹ ni wọn tun gbọ pe ariwo nla kan ti sọ lapa ibi kan, ko pẹ sigba naa ni wọn si ri oku Liam Payne.

Ẹsẹkẹsẹ ni iwadii awọn ọlọpaa bẹrẹ bi wọn ṣe wi.

Bẹẹ ni wọn ni ayẹwo yoo waye fun oku naa lati mọ ohun to pa a gan-an.

Alabojuto ẹka itọju pajawiri, Alberto Crescenti, ṣalaye fun awọn akọroyin pe Payne fi ara ṣese gan-an.

Wakati diẹ ṣiwaju iku rẹ, Liam fi ọrọ to fi kede pe oun wa ni Argentina sori ẹka Snapchat rẹ, o ka bayii pe : Oni daa l’ Argentina."

Awon olubakẹdun ree niwaju otẹẹli ti Liam ku si

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awon olubakẹdun ree niwaju otẹẹli ti Liam ku si.

Ta a ni Liam Payne?

Liam James Payne gan-an lorukọ rẹ.

Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹjọ ọdun 1993 ni wọn bi i si ileewosan New Cross Hospital,Wolverhampton, ni England.

Baba rẹ ni Karen Payne, nigba ti iya rẹ n jẹ Ruth Payne.

Olorin taka-sufee ti awọn eeyan mọ gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ olorin One Direction ni.

O ti figba kan lọ danra wo lori amohumaworan ijọba ilẹ Gẹẹsi ri BBC.

Ọdun 2010 ni Oloogbe Liam Payne di olokiki lagbo orin, nipasẹ eto kan, X Factor TV show, lori ẹrọ amohunmaworan ilẹ Gẹẹsi.

Oloogbe pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ bii Harry Styles, Louis Tomlinson, Niall Horan ati Zayn Malik ni wọn jọ n ṣe e nigba naa.

Ni ibẹrẹ oṣu kẹwaa yii, Liam Payne ṣi lọ si ode orin kan to jẹ ti One Direction, eyi ti Niall Horan, gbe kalẹ.

Gbogbo awọn ololufẹ orin rẹ ni wọn ti n ranṣẹ ibanikẹdun lori ayelujara.