Kí ló dé tí Seyi Makinde àti INEC tahùn sí ara wọn lórí ìdìbò gómìnà l‘Ondo?

Gomina SAeyi Makinde ti ipinlẹ Oyo, Ademola Adeleke ni Osun ati eekan ọmọ ẹgbẹ oselu PDP miran

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Eto idibo si ipo Gomina ipinlẹ Ondo yoo waye lọjọ kẹrindinlogun oṣu kọkanla ọdun yii, gbogbo ẹgbẹ oṣelu ti yoo kopa ninu eto idibo naa si ti bẹrẹ ipolongo ibo jakejado ipinlẹ naa.

Lọjọ Iṣẹgun ni ọkan lara awọn ẹgbẹ oṣelu naa, 'Peoples Democratic Party, PDP', ti igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹri, Agboọla Ajayi jẹ aṣoju fun ninu idije naa ṣe ipolongo ibo.

Lara awọn alejo pataki to pejupesẹ si ibi eto naa ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde.

Lasiko ti Makinde n ba awọn eeyan sọrọ nibi ipejọpọ yii lo fi ẹsun kan wi pe ọmọ bibi ipinlẹ Ondo ni Arabinrin Oluwatoyin Babalọla to jẹ Kọmisana ajọ eleto idibo ti wọn yan lati ṣe amojuto eto idibo naa.

Nitori idi eyii lo si fi kede wi pe awọn ko ni fi aye gba iru igbesẹ naa.

Ipade apapọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP ni Ondo

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig

"INEC gbọdọ yọ Kọmisana rẹ ni Ondo, Oluwatoyin Babalọla, ori pe ọmọ bibi ipinlẹ Ondo ni"

Makinde ni, "Mo ni nnkan kan lati sọ, ọrọ yii si wa fun alago ajọ eleto idibo, INEC, Ọjọgbọn Yakubu Mahamood.

O gbọdọ yọ Kọmisana ajọ eleto idibo ni ipinlẹ Ondo, Arabinrin Oluwatoyin Babalọla nitori pe ọmọ bibi ipinlẹ Ondo ni.

Ohun ti ẹ ṣe ni Edo, ẹ ko le rii ṣe ni Ondo.

A maa fi ẹhonu han titi ti yoo fi kuro ni ipo naa.

Ẹ gbe Kọmisana ajọ eleto idibo mii ti yoo jẹ olotitọ wa."

Ọrọ ti Makinde sọ yii ko dun mọ ajọ eleto idibo, INEC ninu, eyii lo si mu ki wọn fi ọrọ lede lori ikanni ikansiraẹni X, nibi ti ajọ naa ti ṣe alaye wi pe ko si ọtitọ kankan ninu ẹsun ti Makinde fi kan ajọ naa.

Ipade apapọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP ni Ondo

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig

INEC fesi pada fun Seyi Makinde

Ninu atẹjade naa ajọ INEC fi idi ọrọ mulẹ wi pe Arabinrin Oluwatoyin Babalọla kii ṣe ọmọ bibi ipinlẹ Ondo, nitori ko si ninu aṣa ajọ naa lati gbe Kọmisana ajọ eleto idibo lọ si ipinlẹ ti wọn ti wa.

Ajọ INEC ni bakan naa ni Makinde fi ẹsun kan awọn l'ọdun 2020 lasiko ipolongo ibo Gomina wi pe ọkan lara awọn aṣoju ajọ naa to ṣiṣẹ pẹlu Giwa fasiti ijọba apapọ to n bẹ nilu Akurẹ, FUTA, yoo da oju ibo naa ru, to si jẹ wi pe irọ lasan ni ẹsun naa.

Ajọ naa rọ gbogbo awọn oloṣelu to wa ni ipo iṣakoso bii Gomina Makinde lati maa ṣe iṣẹ iwadii to kuna ki wọn to maa fi awọn ẹsun ti ko ni ẹsẹ nilẹ kan.

Àkọlé fídíò, Ikiso River: Odò yìí kìí gbẹ lásìkò ẹ̀ẹ̀rùn, kìí gbé èèyàn lọ, ó ń fa òjò, bí ọ̀dá bá wà

Gómìnà Ondo, Aiyedatiwa buwọ́lu ₦73,000 gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́

Gómìnà Lucky Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, Hon Lucky Orimisan Aiyedatiwa/Facebook

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Lucky Aiyedatiwa ti kéde ẹgbẹ̀rún mẹ́tàléláàádọ́rin náírà (N73,000) gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ náà.

Aiyedatiwa kéde ìròyìn náà níbi ìfilọ́lẹ̀ ìpolongo ìbò rẹ̀ tó wáyé ní ìlú Akure, olú ìlú ìpínlẹ̀ náà lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Ní ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Kọkànlá, ọdún 2024 ni ètò ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo yóò wáyé, tí Aiyedatiwa sì ń du ipò náà lábẹ́ ṣgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC.

Gómìnà náà ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin náírà (N70,000) ni ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fẹnukò lé lórí, ó ní ìpínlẹ̀ Ondo ń gbìyànjú láti ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Ó sọ pé ìṣèjọba òun ní ìfarajìn sí ìgbáyégbádùn àwọn òṣìṣẹ́ àtàwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ondo lápapọ̀.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nígbà tó ń bá àwọn alátìlẹyìn ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ sọ̀rọ̀ níbi ètò ìpolongo náà, Aiyedatiwa rọ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà láti jáde dìbò fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC lásìkò ìbò tó ń bọ̀ ọ̀hún.

Ó ní èyí yóò fún àwọn ní àǹfàní láti túnbọ̀ tẹ̀síwájú láti máa ṣe àwọn nǹkan ribiribi tí yóò mú ìdàgbàsókè bá ìpínlẹ̀ Ondo.

Ó fi kun pé àwọn ìwòye tí òun ń rí àtàwọn nǹkan tí òun ń gbọ́ jẹ́ kí òun ní ìgboyà pé àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ ń fẹ́ kí àwọn tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìṣèjọba òun.

Nígbà tó ń ṣàlàyé àwọn nǹkan tí ó ti gbéṣe láti oṣù mẹ́wàá sẹ́yìn tó ti gba àkóso ìpínlẹ̀ Ondo, ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ìdàgbàsókè ni àwọn ti parí, tó fi mọ́ èyí tí gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ náà, Rotimi Akeredolu bẹ̀rẹ̀ kó tó jáde láyé.

Aiyedatiwa ní àwọn àkànṣe iṣẹ́ lẹ́ka ètò ọ̀gbìn ni àwọn ti gbé ṣe láti mú kí oúnjẹ pọ̀ nílùú àti pé àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ tún buwọ́lu bílíọ̀nù kan náírà fún ètò ọ̀gbìn pàápàá fún ilẹ̀ kíkọ ní àwọn ìgbèríko.

Bákan náà ló ní àwọn ti mú àlékún bá owó oṣù àti àjẹmọ́nú àwọn dókítà ní ìpínlẹ̀ náà ní èyí tó fà á táwọn dókítà ìpínlẹ̀ náà kìí fi sáré láti kúrò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ó wá rọ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ ọ̀hún láti ṣe kóríyá fún òun pẹ̀lú ìbò wọn.