Mọ̀ nípa ìlú Sawonjo, níbi tí kò sí olè bí Naijiria ṣe le tó
Niluu Sawọnjọ ni ijọba ibilẹ ariwa Yewa, nipinlẹ Ogun, awọn araalu kí ti ilẹkun ile wọn koda ìta gbangba ni wọn ma gbe ọkọ ayọkẹlẹ wọn si.
O ya yín lẹnu abi, bẹẹ naa lo ṣe ya Ileeṣẹ BBC News Yoruba lẹnu tí a fi morile ilu Sawonjo
Ole o ki n ja nibi ni ilu yii, wọn gbagbọ pe ole to ba n ja nibẹ, o n fi ẹmi ara ẹ wewu ni.
Bi Naijiria ṣe le to, ko si wahala kan rara iluu yii fun awọn ara ilu.
Ṣugbọn kí ni idi ti wọn ko fi ki n jale?
Awọn araalu to ba wa sọrọsalaye pe ninu iṣẹda wọn, ní awọn Babanla wọn ti fi kọ wọn nípa eewu ole jija.
” Ni bi ọdun marun-un si mẹwaa, tẹ sọ sẹyin yẹn, ọja yii o kun rara, ṣugbọn lati bi ijọ mẹta sẹyin bii ọdun meji si isinyii, ọja yii ti wa bẹrẹ si n kun, latara pe iroyin n ba awọn ọpọlọpọ eeyan pe ninu ọja Sáwọnjọ yii o, idaabobo ibẹ lagbara gan.
“Koda, nisinyii, ba ti ri to ilọpo, eeyan mẹta si igba ta n na, ti wọn n bawa na nisinyii, tawọn naa dẹ n ri aridaju pe ọja yii; ko si wahala, ko si nnkankan tan gbe kalẹ, ti wọn ma fọwọkan rara.”
Ẹkunrẹrẹ ń bẹ ninu fidio tí a gbe soke





