Ibà Lassa pa èèyàn 172, kọlu ẹgbẹ̀rún nípìnlẹ́ méjìdínlọ́gbọ̀n -NCDC

Aworan eku

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Aworan eku
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ to n ri si amojuto ati idena itankalẹ arun ni Naijiria, Nigeria Centre for Disease Control and Prevention (NCDC), ti kede pe iba Lassa ti pa eeyan ọgọrun-un kan ati mejilelaadọrin (172) kaakiri orilẹede yii.

Bakan naa ni wọn ni arun yii kọlu eeyan ẹgbẹrun kan o le mejidinlogun ( 1,018) kaakiri ipinlẹ mejidinlogun lorilẹede Naijiria.

Ninu atẹjade kan ti NCDC gbe jade loju opo ayelujara X wọn, ni wọn ti fidi ọrọ yii mulẹ. Ajọ naa ṣalaye pe onka to wa nilẹ ree titi di oṣu kẹsan-an ọdun 2024.

Ikede NCDC yii fi bi kokoro aifojuri Virus to n fa iba Lassa ṣe n tan kalẹ, pẹlu gbogbo bi wọn ṣe n gbiyanju lati kapa rẹ to.

Wọn ni bi iba yii n ṣe pa awọn eeyan n pọ si i. Ìdá 16.8 eeyan ni ajọ naa sọ pe Lassa pa niwoyi ọdun 2023, o si ti fo si 16.9 bayii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Kí ló ń fa Iba Lassa?

Iba Lassa jẹ arun kan to maa n waye lati ara kokoro aifojuri ti a mọ si Virus.

Kokoro yii maa n de ara eeyan lati ara ounjẹ tabi nnkan eelo ti ekute to ni kokoro lara naa ba tọ si, tabi to ṣe igbọnsẹ si .

Ajọ eleto ilera agbaye, World Health Organisation (WHO), sọ ọ di mimọ pe iba Lassa pọ ni apa Iwọ Oorun Africa, paapaa ni Naijiria, Liberia, Mali, Togo, Guinea, Ghana, Sierra Leone ati Benin.

Bakan naa, iba Lassa yii tun maa n tàn lati ara ẹnikan si ikeji, nibi ti ko ba ti si idaboobo ati itọju to peye.

Gẹgẹ bi NCDC ṣe wi, arun Lassa n lagbara si i , pẹlu bo ṣe jẹ pe onka awọn to n kọlu n pọ si i.

Wọn ni ipinlẹ Ondo ati Edo ni onka wọn pọ ju lọwọlọwọ.

Eeyan 172 to si ti ku latari iba Lassa n fi han pe ọwọja rẹ n ga si i.

Yatọ si Ondo ati Edo, ipinlẹ Bauchi ni NCDC sọ pe Lassa tun ti ṣọṣẹ ju.

Nipa iru awọn eeyan ti iba yii saaba maa n kọlu, ajọ naa sọ pe awọn eeyan ti ọjọ ori wọn wa laaarin ọdun mọkanlelọgbọn (31) si ogoji ọdun (40), takọ-tabo ni wọn ni o si le mu.

Awọn eleto ilera rọ awọn eeyan lati dena arun yii ni gbogbo ọna, titi to fi mọ titọju ounjẹ lọna ti ekute ko fi ni i le debẹ.

Wọn gba araalu niyanju lati maa wa ni imọtoto nigba gbogbo.Bẹẹ ni wọn rọ awọn olutọju naa lati maa tẹle ilana ti ko ni i jẹ ki wọn lugbadi arun naa nibi ti wọn ba ti n tọju alaarẹ.