Láti ọmọ ọdún mẹ́rin ni mo ti ń lùlù - Ayanwura, ọmọ ọdún mẹ́fà tó lùlù níbi ètò ìbúrawọlé Aàrẹ Tinubu ṣàlàyé
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọmọ tó bá máa jẹ́ àṣàmú kékeré ló ti máa ń ṣe ẹnu ṣámúṣámú.
Èyí ni ìtàn ayé Sofiat Olaide tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ayanwura lórí ayélujára.
Sofiat ló jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà tó ń lùlù láti ìgbà tó ti wà ní ọmọ ọdún mẹ́rin.
Ó ní òun fẹ́rà láti máa lùlù nítorí pé ó máa ń mú inú òun dùn.
Sofiat ló ti lùlù níbi ètò ìbúrawọlé ààrẹ Tinubu tó wáyé ní Abuja.

Ìyá Sofiat, Morenike Olaide ní láti ìgbà tí òun ti ṣe àkíyèsí pé Sofiat fẹ́ràn láti máa lùlù ni òun mu un lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn tó ti máa kọ́ ìlù lílù dáadáa.
Ó ṣàlàyé pé ìfẹ́ tí ọmọ òun ní sí ìlù lílù ni àwọn fi fi Àyàn kún orúkọ rẹ̀ tó jẹ́ Wúrà nítorí àwọn kò wá láti ìdílé tí wọ́n ti máa ń lùlù.
Ó ní bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe gba orúkọ Ayanwura tó ń jẹ́.
Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ayanwura fẹ́ràn láti máa lùlù, kò dín ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ nítorí ó máa ń ṣe dáadáa nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti pé àwọn olùkọ́ rẹ̀ máa ń kan sárá si.
Morenikeji ní òun kò tilẹ̀ mọ̀ pé ọmọ òun yóò tètè di ìlú mọ̀ọ́ká nígbà tí òun ń fi fídíò rẹ̀ sórí ayélujára.
Ó tẹ̀síwájú pé inú òun dùn gan nígbà tí gbajúmọ̀ òṣèré Toyin Abraham tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ sí òun pé òun fẹ́ kí Ayanwura kópa nínú eré tí òun fẹ́ gbé jáde.
Ó rọ àwọn òbí láti máa gbárùkù ti àwọn ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá ti rí ẹ̀bùn kan tí wọ́n ní.



