Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin SS3 gún akẹgbẹ́ rẹ̀ pa ní ìpínlẹ̀ Ondo

Aworan ile ẹkọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ iwadi lori bi akẹ́kọ̀ọ́ Akoko Anglican Grammar School Community, Sandra ṣe gun akẹẹgbẹ rẹ, Habib Salau pa lasiko ija to waye laarin wọn.

Iroyin fi yeni pe ariyanjiyan waye laarin awọn akẹkọọ mejeeji ni kete ti wọn kuro ni ile ẹkọ niluu Arigidi-Akoko, ni Ọjọru, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹwaa.

Lasiko ija naa ni Sandra fi ọbẹ to gba lọwọ akẹkọọ miran to wa lati Ajiroke Technical School pa Habib.

Ileeṣẹ Ọlọpaa wa ti seleri pe wọn yoo ri daju pe wọn ṣe iwadii to peye lati mọ ohun gan to fa iṣẹlẹ naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya sọ fun BBC pe wọn ti gbe ẹjọ naa le ẹka to n se iwadii iwa ọdaran (CID) lọwọ, fun iwadii.

Odunlami-Omisanya sọ pe komisona Abayomi Oladipo seleri pe wọn ko ni fi igba kan bọ kan ninu lori iṣẹlẹ naa.

"A o ri daju pe a ṣe isẹ wa bi isẹ lati mọ awọn ohun ti o rọ mọ iku Habib"

Bi ibẹrubojo ṣe suyọ laarin awọn obi lori iṣẹlẹ naa bẹ naa ni awọn adari ile ẹkọ n wa ojutuu si ọna ti wọn yoo gba dabo bo awọn akẹkọọ ki irufẹ iṣẹlẹ yii ma ba pada waye.

Wọn ti gbe oku Habib lọ si mọṣuari to wa ni ile iwosan ijọba to n'ilu Ikare-Akoko.