''Aráàlú gbọdọ̀ múra sílẹ̀ torí epo bẹntiróòlù sì tún máa wọ́n síi''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alagbata epo bẹntiroolu lorilẹede Naijiria ti sọ wi pe araalu gbọdọ mura silẹ tori epo si tun maa wọn sii.
Awọn alagbata epo bẹntiroolu to jẹ aladaani ṣalaye wi pe awọn naa maa fi owo le epo bi awọn ba ṣe n ra lati ileeṣẹ ifọpo Dangote.
Akọṣẹmọṣẹ nipa ohun amuṣagbara, Ọmọwe Joseph Obele sọ pe N1,045 lawọn alagbata n ra epo bẹtiroolu niluu Port Harcourt ati agbegbe rẹ nigba ti wọn n ra ni N1,010 niluu Eko.
Ọmọwe Obele ni o ṣe pataki fun araalu lati mọ pe iye tawọn alagbata n ra epo kọ ni wọn maa ta a.
Ọgbẹni Obele ni o ṣee ṣe ko jẹ wi pe igbesẹ ajọ NNPCL lati ma ṣe bi alarina mọ laarin ileeṣẹ ifọpo Dangote ati awọn alagbata epo bẹntiroolu lo ṣokunfa bi owo epo tun sẹ lọ soke si.
O ni afikun owo epo bẹntiroolu yoo tun jẹ ki ọwọngogo nnkan to gbode buru si ni Naijiria.
Bakan naa ni o sọ pe ọpọ awọn oniṣowo epo bẹntiroolu ni yoo kogba wọle eyi ti yoo jẹ ki iṣẹ bọ lọwọ ọpọ oṣiṣẹ.
Ìjọba Tinubu gbé owo epo láti N187 lọ sí N1,100 láàrin ọdún kan, aráàlú pariwo'
Ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria lo ti n pariwo bayii latari bi ajọ NNPCL tun ti kede afikun owo epo bẹntiroolu lọsan Ọjọru ọjọ kẹsan an oṣu Kẹwaa yii.
Ojiji ni ọrọ naa ba ọpọlọpọ ni Ọjọru nigba ti wọn ṣadeedee gbọ wi pe owo epo tun ti le sii.
Igba kẹta niyii ti ijọba yoo ṣe afikun owo epo bẹntiroolu ninu ọdun 2024 yii nikan.
Ni Ọjọru kan naa yii lawọn ile epo to jẹ ti NNPCL bẹrẹ si ni ta lita epo bẹtiroolu kan ni 998 Naira.
Bakan naa niluu Abuja tii sẹ olu ilu orilẹede Naijiria, N1,030 lawọn ile epo NNPCL ti bẹrẹ si ni ta epo bẹntiroolu.
Ọpọ ọmọ Naijiria to fi aidunnu wọn han loju opo Facebook BBC Yoruba lo bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ajọ NNPCL lati ṣe afikun owo mii lẹyin eyi ti wọn ṣe loṣu to kọja.
Raji Busari ni afikun owo epo ti ijọba ṣẹṣẹ ṣe yoo tun jẹ ki inira pọ si fun araalu.
O rawọ ẹbẹ si ijọba Aarẹ Bola Tinubu lati ṣiju aanu wo araalu pẹlu awọn igbesẹ to n gbe.

Adura tipatipa ni Ọgbẹni Oluwole Makinde ati Olori Aduke Ogunjimi n gba ni tiwọn lori ọrọ afikun owo epo bẹntiroolu ti ajọ NNPCL ṣẹṣẹ ṣe.
Adura to wa lẹnu wọn ni pe ki Eledua mu inira ba gbogbo ẹda to ba n ni ọmọ Naijiria lara.


Awọn eeyan kan tiẹ di gbogbo ẹbi ru ajọ NNPCL wi pe wọn o fi ọmọniyan ṣe e bi wọn ti n ṣe afikun owo epo bẹntiroolu loorekoore.
Wọn ni NNPCL gan gan an igi wọrọkọ to n da ina ru lori ọrọ owo epo bẹntiroolu to n lọ soke lati igba de igba.
















