Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ìlú kan wà ní Naijiria, níbi tí wọ́n ti ń ju ọmọ sígbó nítorí pé 'àjẹ́ ni wọ́n'?

Ko si ẹni ti wọn yoo pè ti ko ni i jẹ ni Yoruba maa n wi, ṣugbọn sibẹ, wọn gba pe awọn eeyan kan wa to jẹ ajẹ ni wọn, iyẹn ẹlẹyẹ.
Obinrin ni a mọ si ajẹ, ibaa jẹ ọmọde tabi agbalagba obinrin, nigba ti wọn maa n pe ọkunrin ti wọn gbagbọ pe ẹlẹyẹ ni, ni oṣó.
Ẹmi okunkun, agbara buruku ti wọn le fi ṣeka wa lọwọ awọn ẹlẹyẹ gẹgẹ bi igbagbọ Yoruba, ṣugbọn bẹẹ naa igbagbọ yii wa kaakiri Naijiria, ki i ṣe ilẹ Yoruba nikan.
Eyi naa lo fa a ti ọna ti wọn fi maa n da sẹria fun ẹni ti wọn ba pe ni ajẹ ṣe yatọ kaakiri orilẹede yii.
Awọn eeyan ki i fẹ ki ajẹ gbele aye nitori iṣẹ ibi ti wọn gbagbọ pe o kun ọwọ wọn.
Nitori ẹ ni wọn fi maa n sọko pa awọn obinrin ti wọn ba ro pe ajẹ ni wọn, paapaa nilẹ Yoruba, nigba ti wọn ba ni ajẹ naa n kà.
Ninu iroyin yii, ẹ o ka nipa ipinlẹ Akwa Ibom, lapa Guusu Naijiria, nibi ti wọn ti gbagbọ pe ọmọde lo maa n ni ẹyẹ laya ju.
Wọn yoo lu ọmọ naa bii ko ku, wọn yoo ja ọmọ bẹẹ si ihoho, le e jade nile pẹlu, tabi ki wọn sọ ọ nu si aarin ọja lai wale mọ.
‘ Ó lé ní ọ́gọ́rùn-ún ọmọ tí wọ́n ti mú lájẹ̀ẹ́ ní Akwa Ibom’
Ni ipinlẹ Akwa Ibom, o ti le ni ọgọrun-un ọmọde ti wọn ti mu lajẹẹ, ti wọn si ti fi oju wọn gbolẹ gidi.
Eyi saaba n waye ni agbegbe ijọba ibilẹ Oron, nibẹ ni wọn ti maa n f’oju ẹlẹyẹ wo awọn ọmọ ju.
Bo tilẹ jẹ pe lati ọdun 2012, ọdun mejila sẹyin ni ijọba ti ṣe ofin to tako ki wọn maa mu ọmọde lajẹẹ, o jọ ni loju pe awọn kan ṣi n ṣe bẹẹ ninu awọn eeyan yii.
Bi wọn ba lu ọmọ ti wọn ba mu lajẹẹ tan, wọn yoo gbagbe rẹ, ọmọ naa le ku danu nigba ti ko ba ri olutọju kankan.
‘Ọmọ orogùn ìyá mi kú, ìyá rẹ̀ ní èmi ni mo pa á, bàbá mi lé mi jàde nílé nítorí èyí
Boya ọmọkunrin kan, Udeme, to ti di ẹni ọdun mọkandinlogun bayii, ko ba ti ku tipẹ, bi ko ba jẹ ti alaanu kan to gba a sọdọ nigba ti baba rẹ le e jade nile nitori iku ọmọ orogun iya rẹ.
’’Orogun iya mi ni ọmọ rẹ ku, iya ọmọ naa si ni emi ni mo pa a.
"O sọ fun baba mi pe ajẹ ni mi. Mo wa ni kilaasi keji nile ẹkọ alakọọbẹrẹ nigba yẹn.
“Baba mi le mi jade nile nitori eyi, o ni oun yoo pa mi ti oun ba tun ri mi layika oun.
Bi mo ṣe di alarinkiri niyẹn.”
Udeme lo ṣalaye bẹẹ fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo kan.
Ìyá àgbà, Mary Okon Okpoyo, ni olùgbàlà àwọn ọmọ tí wọ́n ń jù nù l’Akwa Ibom
Iya agbalagba ẹni ọdun mọkanlelọgọrin kan, Mary Okon Okpoyo, to n gbe ni ipinlẹ Akwa Ibom lo fi ara rẹ jin lati maa ran iru awọn ọmọ bẹẹ lọwọ.
Awọn ọmọde mejilelogun (22) ti awọn obi wọn ti le danu nitori ọrọ ajẹ yii ni wọn n gbe lọdọ iya agba yii.
Lọkunrin, lobinrin ni awọn ọmọ naa, ṣugbọn obinrin lo pọ ju ninu wọn.
Ọkan ninu awọn ọmọ naa ni Udeme ti baba rẹ le nile nitori iku ọmọ orogún.
"Mo n lọ ni titi lọjọ kan ni mo ri ọmọdekunrin kan lọna, o gbẹ pupọ, ẹgbẹ akitan lo si duro si.
"Mo beere pe ki lo de ti ọmọ naa fi ri bi eyi, wọn ni ajẹ ni, oun lo pa iya rẹ.
Mo tun beere pe bawo niru ọmọde bayii yoo sẹ jẹ ajẹ ti yoo si pa iya rẹ."
Eyi lo mu ki Arabinrin Okpoyo mu ọmọ naa wa si ile ara rẹ.
O ni awọn ti wọn n ri oun pẹlu ọmọ naa waa sọ fun oun pe awọn ọmọ bẹẹ pọ laaarin ọja ti wọn gbagbe wọn si, "mo si lọ s’ọja, mo lọọ ko wọn wale".
Iya agba Mary Okon Okpoyo lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
O ni bi oun ba ti ko wọn bẹẹ, ni oun yoo fi wọn si ile ẹkọ.
Iya agba naa sọ pe obinrin lo pọ ninu awọn ọmọ ọhun , nitori awọn ni wọn wa lọwọ ewu ifipanilopọ ati iwakiwa mii, oun ko si fẹẹ ki nnkan bẹẹ ṣẹlẹ si wọn.
O koro oju si awọn olori ẹsin ti wọn maa n ṣe itusilẹ to nira fun awọn ọmọ ọlọmọ, ti wọn yoo ni ajẹ ni wọn.
Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀mí òkùnkùn wọnú ọmọ lóòótọ́- Pasitọ Enang
Lati mọ oju ti ẹsin fi wo ọrọ aje yii, BBC ba pasitọ kan, Joseph Okon Ekpong Enang, sọrọ niluu Oron.
Enang ni oun gba pe ẹmi okunkun le gbe awọn ọmọde wọ loootọ.
“A ni awọn eeyan to jẹ ajẹ ni wọn, awọn kan tiẹ sọ bẹẹ fun wa funra wọn pe ajẹ lawọn. A ti ri iru ẹ ri laduugbo wa yii.”
O ni ṣugbọn awọn obi ti ko ba ni Jesu ni wọn ki i gbe ọrọ aje naa gba ibi to yẹ, ti wọn yoo maa lu ọmọ, ṣe ọmọ baṣubaṣu.
Pasitọ Enang sọ pe itusilẹ ni awọn pasitọ to ba mọ ohun to yẹ maa n ṣe fun awọn ọmọ bẹẹ, lati yọ ẹmi okunkun jade lara wọn.
Bakan naa ni Ọmọwe Mbosowo Udok, ẹni to ti ṣe oriṣiriṣi iṣẹ iwadii lori ajẹ ni Yunifasiti Uyo, sọ pe loootọ ni awọn ajẹ wa nilẹ Africa.
Ọmọwe Udok ṣalaye pe awọn eeyan Africa gbagbọ ninu ẹmi airi, oriṣa ati ajẹ.














