'Bí ibòjì òkú pẹ̀lú sáàrè tó fọ́n káàkiri ìgboro ni Gaza rí'

Aworan awọn obinrin ti wọn padanu ọpọ ninu ogun Gaza
    • Author, Amira Mhadhbi
    • Role, BBC News Arabic
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni ọjọ keje oṣu, Kẹwaa ọdun 2023, Hamas sekọlu alarotẹlẹ si guusu orilẹede Israel, ti ọpọ eeyan si padanu ẹmi wọn, ti wọn si ji eeyan mii gbe.

Ikọlu yii lo fa gbọmisi omi o to laaarin Israel ati Hamas, eyi ti wọn ti ṣapejuwe gẹgẹ bi ogun to buru ju ni agbegbe naa.

BBC News ti se akojọ awọn ohun to waye lasiko ogun naa, ti a si tun ba awọn eeyan ti ajalu naa se akoba fun un sọrọ.

Fatma Edaama ati mọlẹbi rẹ n gbe ni apa Ariwa Gaza. Wọn ti fi oju wina ọpọ oṣu iṣekupani, ibalu jẹ ati ebi.

Fatma ṣapejuwe ipo ti o wa gẹgẹ bii eyi ti o ti ni loju pupọ.

O ni o da bi pe oun wa lori aisan fun ọdun kan, ti oun si lero pe oun yoo dide lọjọ kan, ti oun yoo ri Gaza ti oun mọ tẹlẹ pada.

Fatma si ni igbagbọ.

“A yoo tun ilu yii kọ, ti a yoo si da pada.”

Aworan
Àkọlé àwòrán, Gaza City beach before and after the Israeli military invasion

Iku ni Gaza

Fun Ashraf al Attar, ogun yii ti mu ayipada ba ile aye rẹ.

Ashraf n siṣẹ gẹgẹ bii nọọsi ni ile iwosan Yuroopu ni agbegbe Guusu Khan Yunis.

O sọ fun BBC pe iyawo oun ati ọmọ mẹfa ni wọn padanu ẹmi wọn sọwọ ado oloro to bu gbamu ni Deir al Balah ni aarin gbungbun Gaza ni ẹẹkan naa.

Aworan iyawo Sharaf Hala, pẹlu awọn ọmọ mẹfa

Ileeṣẹ ologun Israel ko ki n fi bẹ sọrọ nipa awọn ikọlu ti wọn ba se, ti wọn ko si ni sọrọ ni kiakia nipa ikọlu to sekupa idile Ashraf ni owurọ ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹjọ.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede ni ọjọ keji ikọlu naa ni awọn ologun ti ṣalaye ohun to waye ni Deir Balah, ti wọn si ni awọn lepa awọn janduku, eyi to jẹ ki ikọlu naa waye.

Hala ati ọmọ rẹ mẹfa jẹ ọkan ninu ẹgbẹrun lọna ogoji eeyan to ti padanu ẹmi wọn lati ibẹrẹ ogun Gaza.

Ni ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹsan an ọdun 2024, ajọ agbaye UN ni eeyan 639 ni wọn padanu ẹmi wọn ni West Bank ati ni ila oorun Jerusalem.

Aworan

Ibi ti nnkan de duro ni Israel

Ikọlu ọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023, ni wọn ṣapejuwe gẹgẹ bii eyi ti o buru ju ninu itan orilẹede Israel, nibi ti eeyan to le ni egbẹrun kan ti padanu ẹmi wọn.

Ni oṣu Kọkanla ọdun 2023, BBC gba awọn ẹri kan to safihan bi ikọ ologun Palestine marun un se darapọ mọ ikọ Hamas nibi ikọlu ọjọ keje si Israel.

Aworan

Yatọ si pe wọn pa awọn eeyan, eeyan 251 ni wọn tun ji gbe pamọ.

Lati bi ọdun kan bayii, ọpọ ninu wọn ti gba itusilẹ, ti awọn mii si wa ni ahamọ.

Yarden Bibas, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn pẹlu iyawo rẹ ati ọmọ wọn meji wa lara awọn eeyan ti ikọ Hamas ji gbe pamọ.

Ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 2023, Hamas ni Shiri ati awọn ọmọ meji ti padanu ẹmi wọn nigba ti Israel ju ado oloro kan.

Orfi Bibas Levy to jẹ aburo si Yarden ni inu ibẹrubojo ni oun wa lori ipo ti ẹgbọn rẹ ati mọlẹbi rẹ wa sugbọn o si ni igbagbọ pe wọn wa laaye. O sọ fun BBC

Aworan Yarden ati ọmọ rẹ

Ko si ibo miiran lati lọ

Ni ọgbọnjọ, oṣu Kẹsan na, ọdun 2024, ajọ UN ni o le ni eeyan milọnu meji ti wọn di alaini ile lori mọ.

Lasiko ogun yii, ikọ ologun kede fawọn araalu ni Gaza pe ki wọn kuro ni agbegbe wọn lọ si agbegbe miiran.

Iwadii UNICEF ni oṣu Kẹjọ ọdun 2024 ni eeyan to le ni miliọnu kan (1.7m) ni Gaza ni wọn le kuro lọ si agbegbe miiran.

Aworan

Njoud Abu Kaloubm ẹni ọdun mọkanlelọgbọn jẹ ọkan lara awọn eeyan ti ko ni ile lori mọ ni Gaza.

Njoud ati ọmọ rẹ mẹrin ni lati bọ si ibi kan lati ibi kan ni igba mọkanla nitori ikọlu Gaza.

Bayii, o n gbe ni ile kekere kan ni Al-Mawasi ni agbegbe Khan Younis, ti ko si gbero lati tun kuro lọ si ibo miiran.

Bi awọn eeyan miiran ni Gaza, Njoud Abu Kaloub ko ni ibo miiran lati lọ tabi pada si ti ogun ba pari.

Ninu oṣu kẹta ọdun 2024, olumọ ni UN ni o le ni ida adọrin ile to wa ni Gaza ni wọn ti najẹ lai ibẹrẹ ogun naa.

Bakan naa ni wọn kede pe yoo gba ọpọ ọdun lati fi kọ awọn ile naa pada.

Aworan
Aowran