Mọ̀ nípa Ogunnaike, afurasí apànìyàn tó ní kí iléejọ́ fún òun l'óúnjẹ kí wọ́n tó pa òun

Philip Ogunnaike

Oríṣun àwòrán, Ogun Police Command

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

O kere tan, ẹmi eeyan mẹta ti wọn jẹ ọdọmọbinrin lo ti bọ lati ọwọ ọkunrin kan, Philip Ogunnnaike, ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ to n pa eeyan nipinlẹ Ogun.

Ni nnkan bii oṣu meloo sẹyin, awọn iṣẹlẹ ipaniyan kan waye nipinlẹ Ogun nibi ti wọn ti kọkọ ji awọn ọmọbinrin kan gbe, ti wọn si pada ri oku wọn lẹyin ti tawọn kan fipanilopọ.

Gẹgẹ bi Philip funra ẹ ṣe ṣalaye fun awọn ọlọpaa lẹyin ti ọwọ ba a, o ni o kere tan, oun pa Akinsanya Habibat;ẹni ọdun mejidinlogun,Abigail Dina; ẹni ọdun mejilelelogun ati Mary Ogunyemi; ẹni ọdun mẹtalelogun.

Nigba to n jẹwọ ẹṣe rẹ fun awọn ọlọpaa , Ogunnaike, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29) sọ pe oun pa awọn ọmọdebinrin yii loootọ.

O ni oun ko fẹ idajọ mi-in ni kootu ju ki ile-ẹjọ dajọ iku foun pẹlu ẹnikan to n jẹ Danjuma, ati awọn miran ti wọn mu oun wọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ.

Philip tẹsiwaju pe ki kootu ma wulẹ gbọ ẹjọ kankan lẹnu oun mọ, ki wọn ṣaa dajọ iku foun atawọn yooku oun ni.

O ni bi wọn ba dajọ naa tan, ki wọn waa foun lounjẹ, koun jẹun ṣiwaju iku, nitori o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn toun pa naa ṣẹṣẹ jẹun tan ki wọn too riku he lati ọwọ oun ni.

Irú èèyàn wo ni Philip Ogunnaike?

Philip Ogunnaike

Oríṣun àwòrán, Ogun Police Command

Àkọlé àwòrán, Philip Ogunnaike

Yatọ si akọsilẹ awọn ọlọpaa to fi han pe ogbologboo apaayan ni Philip Ogunnaike,SP Omolola Odutola, Alukoro ọlọpaa Ogun tun fidi ẹ mulẹ pe ẹlẹwọn to sa lọgba ẹwọn ni.

Gẹgẹ bi kọmandi ọlọpaa Ogun ṣe wi, ni nnkan bii ọdun meji sẹyin ni Philip sa lọgba ẹwọn Ibara, l’Abeokuta.

Wọn ni wọn n gbe e lọ sile ẹjọ Majisireeti to wa n’Isabo ni lọjọ naa, lati jẹjọ idigunjale to n jẹ lọwọ, o si sa lọ mọ wọn lọwọ.

Ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ ni Philip Ogunnaike, adigunle ati ajinigbe ni pẹlu bi wọn ṣe fidi ẹ mulẹ.

Ọna wo ni Philip, ògbólógbòó apààyàn gbà pa àwọn tó ti pa?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n ṣalaye ara rẹ fun awọn ọlọpaa lọjọ Ẹti to kọja ti ọwọ ba a, Philip to mu wọn lọ sibi to pa awọn to pa si, ṣalaye pe ẹnikan to n jẹ Danjuma lo tan oun wọ ẹgbẹ apaayan.

O ni oun naa maa n tan awọn obinrin toun ba fẹẹ pa wọgbo, oun yoo so wọn mọlẹ, ba omiran lo pọ, fun wọn lọrun pa, lẹyin naa loun yoo ji foonu wọn.

O di dandan kawọn obi maa wa ọmọ wọn to sọnu, afurasi yii sọ pe lẹyin naa loun yoo pe awọn obi ọmọ toun ti pa naa, oun yoo si beere owo itusilẹ lọwọ wọn.

Atẹjade ọlọpaa lorii bi Ogunnaike ati ẹnikẹji rẹ to ti sa lọ bayii ṣe pa Mary Ogunyẹmi,ka pe:

‘’ Lọjọ kẹta, oṣu keje ọdun 2024, ni nnkan bii aago mẹwaa owurọ, ọmọbinrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Mary Ogunyemi, fẹẹ lọọ ba iya rẹ, Eshter Ogunyemi, ra eso ni Adatan, lati Asero Estate, Philip to n gbe pẹlu ẹnikan nilee wọn si tẹle e.

‘’Philip tan tan Mary wọ inu igbo kan to wa nitosi Asero Estate, o si pe ẹnikeji rẹ ti wọn jọ gbimọ pọ, lati ran an lọwọ ninu ijinigbe naa.

“ Wọn fi okun de Mary, wọn si mu foonu Iphone S rẹ, Philip ati ẹnikeji rẹ naa si jọ fun un lọrun pa. Awọn ọdaran mejeeji yii pada pe iya Esther, wọn si beere ẹgbẹrun mẹtadinlogun (17,000) gẹgẹ bii owo itusilẹ Mary.

‘’ Awọn mejeeji fi oku Mary silẹ sinu igbo, wọn sa lọ si Badagry nipinlẹ Eko, wọn si ta foonu ọmọ naa ti wọn ji ni ẹgbẹrun mẹjọ naira.

‘’Philip fipá bá ọmọ ọ̀gá rẹ̀ lò pọ̀, ó pa á tán, ó tún gbowó ìtúsílẹ̀’’

Ileeṣẹ ọlọpaa Ogun tun fidi ẹ mulẹ, pe Philip Ogunnaike pa ọmọ ọga rẹ,Habibat Akinsanya, ni ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yii.

Agbegbe Mile 6, l’Abeokuta ni iṣẹlẹ naa ti waye, nnkan bii aago marun-un irọlẹ ni awọn ọlọpaa sọ pe o ṣẹlẹ.

Alukoro ọlọpaa Ogun sọ pe Philip ji Habibat gbe, o fi okun de e, o fipa ba a lo pọ, o si fun un lọrun pa mọnu oko baba ọmọ naa ti i ṣe ọga tiẹ.

“Baba ọmọ naa gba ipe lorii foonu ọmọ rẹ, pe wọn ti ji Habibat Akinsanya gbe, o si gbọdọ sanwo itusilẹ miliọnu kan naira.

‘’Baba Habiba san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira kia si akanti Moniepoint ti wọn ni ko san an si, ṣugbọn ko pẹ sigba naa ti wọn fi ri oku ọmọ ọdun mejidinlogun yii ninu oko baba rẹ.Wọn ba ẹrọ POS kan lẹgbẹẹ rẹ pẹlu.

Ogunnaike funra rẹ jẹwọ pe Baba oloogbe gba oun si oko rẹ lati maa ṣiṣẹ, oun si ri ọmọ naa to n kọja lọ loun ṣe tan an wọnu oko’’

Ni bayii, awọn ọlọpaa ti sọ pe Ogunnaike ko ni i bọ́ lọtẹ yii, bẹẹ ni awon yooku rẹ tro sa lọ yoo di mimu laipẹ pẹlu.