'Ìjọba kò nìí san owó ìrànwọ́ lórí Hajj 2025 - Ẹ wo iye tó ṣeéṣe kí ẹ san'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n risi irinajo lọ si ilẹ mimọ Hajj lorilẹede Naijiria ti kede sita pe ijọba ko nii san owo iranlọwọ lori irinajo Hajj lọdun 2025.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ naa, Fatima Usara fi lede fawọn akọroyinlo ti sọ pe ijọba ko nii le maa ran awọn arinrinajo lọwọ mọ nitori bi paṣiparọ Dọla si Naira ṣe ti lọ soke.
Ni ọdun to kọja, akọsilẹ fihan pe ko din ni aadọrun un miliọnu Naira ti ijọba fi kun owo irinajo naa lọfẹẹ.
Kini eyi tumọ si?
Alhaji Nasidi Yahaya Sulaiman to jẹ onimọ nipa irinajo Hajj ati Umrah, sọ pe nnkan ti ikede naa tumọ si ni pe owo irinajo Hajj lọdun 2025 yoo wọn ju ti atẹyinwa lọ.
"Eyi nii ṣe pẹlu iye ti dọla ba jẹ lasiko naa. Amọ nnkan to daju ni pe, to ba ṣi wa ni iye to wa bayii, N1,600/$1, awọn arinrinajo yoo san owo to to milọnu mẹwaa Naira ni ọdun 2025.
"Ti Dọla ba to N2000, a jẹ pe irinajo Hajj yoo ju miliọnu mẹwaa Naira lọ."
Bẹẹ ba gbagbe, ijọba apapọ dide lati pese owo iranwọ fun ajọ naa lati se iranlọwọ fun awọn arin irinajo lọdun 2024.
Alhaji Nasidi ṣalaye pe ohun to tun daju bayii ni pe iye awọn arinrinajo yoo dinku.
"To ba jẹ pe 100,000 eeyan lo ma n lọ tẹlẹ, 50,000 ni yoo l ni 2025."
Lọwọlọwọ, ajọ to n mojuto irinajo Hajj, NAHCON, ko tii gbe iye owo ti awọn eeyan yoo san fun ọdun to n bọ jade.
Amọ awọn ajọ ni ipinlẹ ti bẹrẹ si kede pe ki awọn eeyan maa san owo silẹ, ti awn mii si n beere to miliọnu mẹjọ aabọ Naira.















