'Bàbá mi, MKO Abiola ṣe wíìlì sílẹ̀, àmọ́ ìyà n jẹ àwa kan débi pé a kò rówó ra bàtà'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Abdulmumuni Abiola to jẹ ọkan lara awọn ọmọkunrin ilumọọka oniṣowo to ti di oloogbe, Moshood Kasimaawo Olawale Abiola ti sọ pe owo to le ni N1.4bn ni oloogbe naa fi silẹ fawọn iyawo rẹ mẹrin akọkọ.
Abdulmumuni fidi ọrọ yii mulẹ lori eto kan ti wọn n pe ni ‘’Mic On Podcast’’ eyi ti oṣiṣẹ ileeṣẹ tẹlifisan Channels, Seun Okinbaloye n ṣakoso rẹ.
Lọjọ Abamẹta opin ọsẹ to kọja ni fidio eto naa jade sita tawọn eeyan si ni anfaani lati wo ifọrọwerọ naa.

Oríṣun àwòrán, Mic On Podcast/X
Iwe ogun ti Abiola fi silẹ naa ṣafihan bi o ṣe fẹ kawọn iyawo rẹ mẹrin akọkọ naa pin owo yii.
Abdulmumuni ni o wa ninu akọsilẹ iwe ogun ọhun wi pe ki Simbiat Abiola to jẹ iyawo akọkọ mu £300,000, nigba ti iyawo keji Kudirat Abiola yoo mu £150,000.
£100,000 ni Abiola pin kan Moriamo to jẹ iyawo rẹ kẹta nigba ti Idiat naa yoo mu £100,000 gẹgẹ bi Abdulmumuni ti ṣalaye.
Amọ, Abdulmumuni fẹsun kan ẹgbọn rẹ agba, Kola Abiola, to jẹ ọkan lara ọmọ Simbiat lori eto naa wi pe o kọ lati fun oun ati awọn ọmọ iya oun ni ipin to kan wọn ninu ogun ti baba wọn fi silẹ.
Abdulmumuni sọ pe ẹbi Abiola ti ṣe oriṣiriṣi ayẹwọ DNA fawọn ọmọ oloogbe naa lati mọ awọn to jẹ ojulowo ọmọ Abiola gan an.
Abiola sọ ninu iwe ipin ogun to fi silẹ pe ki wọn fun mama mi Kudirat ni £150,000 - Abdulmumuni
‘’Ti ẹ ba wo iwe ipin ogun ti Abiola ṣe ki o to o ku, o ti pin owo yii lẹsẹẹsẹ pẹlu awọn iyawo to ni.
Mama temi Kudirat Abiola ni iyawo keji, £150,000 si ni Abiola kọ sinu iwe naa pe o tọ si mama mi,’’ Abdulmumuni lo sọ bẹẹ.
O fikun ọrọ rẹ pe nkan ko fararọ fun oun atawọn ọmọ iya oun lẹyin ti mama ati baba awọn ku.
O ni iru owo yii ko ba ṣe iranwọ foun ati awọn to jẹ ọmọ iya kan naa pẹlu oun ti awọn ba le ri gba.
Abdulmumuni ṣalaye pe lati igba toun ti wa ni ọmọ ọdun mẹjọ lorilẹede UK loun atawọn ọmọ iya oun ti n tiraka lati jẹ eeyan laye.
O ni awọn ko rowo lati ra bata gidi lọ si ile ẹkọ nibi ti nnkan le de fawọn lẹyin iku Kudirat ati Abiola.
Abdulmumumi ṣalaye pe ẹgbọn oun obinrin, Kafilah ni lati maa dirun ta lorilẹede UK kawọn to le ri ounjẹ jẹ nigba mii.
Abiola lo jawe olubori ninu ibo aarẹ orilẹede Naijiria ọdun 1993, amọ, olori orilẹede Naijiria nigba naa, Ọgagun Ibrahim Babangida wọgile esi ibo naa eyi to da rogbodiyan silẹ.
Lẹyin o rẹyin, Abiola pada ku si ahamọ lọdun 1998.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
BBC ko le fidi awọn ẹsun yii mulẹ.















