Gómìnà Eno ṣàlàyé ìdí tó fi yan ọmọbìnrin rẹ̀ sípò aya gómìnà ìpínlẹ̀ Akwa Ibom

Aworan Gomina Umo Eno ati Ọmọ rẹ obinrin, arabinrin Helen Eno Obereki

Oríṣun àwòrán, Instagram/pastorumoeno

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ipinlẹ Akwa Ibom, Pasitọ Umo Eno, ti ṣalaye idi to fi kede ọmọbinrin rẹ, Helen Eno Obareki gẹgẹ bii ẹni ti yoo rọpo iyawo rẹ, Arabinrin Patience Eno, to di oloogbe laipẹ yii ni ọfiisi aya gomina ipinlẹ naa.

Gomina ni ipo ti iyawo oun fi silẹ jẹ ipo to lagbara ti ijọba ko si gbọdọ fi silẹ rara.

Gomina Eno sọ eyi di mimọ nigba to n ba awọn araalu sọrọ lẹyin to pada si ọfiisi rẹ lẹyin eto isinku iyawo rẹ.

O si tun jẹ ko di mimọ pe ijọba oun ko ni ja awọn araalu kulẹ, bo tilẹ jẹ wi pe oun si n ṣọfọ iku iyawo oun.

Gomina wa fa ọmọbinrin rẹ le aya aarẹ orilẹede Naijiria, Sẹnẹtọ Oluremi Tinubu lọwọ lasiko to se abẹwo ibanikẹdun si i niluu Uyo.

Lasiko abẹwo naa ni gomima rọ aya aarẹ lati jẹ atọna fun ọmọmọbinrin rẹ ti o ṣẹṣẹ yan sipo.

“Ko ki n se iṣẹ kekere lo wa niwaju wa sugbọn lati le jẹ ki iṣẹ maa lọ ni ọfiisi aya gomina ni mo fi yan ọmọbinrin mi lati rọpo iya rẹ to doloogbe.

“Oun ni yoo tẹsiwaju lati maa se iṣẹ ọfiisi aya gomina, ti yoo si ma sisẹ pọ pẹlu gbogbo awọn obinrin, igbakeji Gomina, kọmiṣọna fun ọrọ awọn obinrin ati bẹẹ bẹẹ lọ,'' Gomina Eno lo sọ bẹẹ.

Ninu ọrọ rẹ, aya aarẹ orilẹede Naijiria, Sẹnẹtọ Oluremi ba mọlẹbi Eno kedun lori ipapoda iyawo gomina ipinlẹ naa, ẹni to ṣapejuwe gẹgẹ igi nla fun ajọ Renewed Hope Initiative.

O wa fi da awọn eeyan ipinlẹ Akwa Ibom loju pe ọfiisi iyawo aarẹ setan lati sisẹ pẹlu ọfiisi aya aarẹ ipinlẹ naa lati mu aye rọrun fun awọn eeyan ipinlẹ naa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Instagram/pastorumoeno

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹsan an ni iroyin tẹ wa lọwọ nipa ipapoda iyawo gomina ipinlẹ Akwa Ibom, Arabinrin Patience Eno.

Kọmiṣọna fun eto iroyin ni ipinlẹ naa, Ini Ememobong, lo kede iku Arabinrin Patience ninu atẹjade kan to fi sita laarọ oni ọjọ Ẹti.

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Ememobong ṣe sọ ninu atẹjade naa, aya gomina Akwa Ibom ku nile iwosan kan l’Ọjọru ọjọ kẹrindinlogbọn oṣu Kẹsan an nibi tawọn ẹbi rẹ ti wa pẹlu rẹ.